Ìwòye Bíbélì Lóríi Ìyípadà ÀwùjọÀpẹrẹ

A Biblical View On Social Change

Ọjọ́ 3 nínú 5

Fífi Ara Wa Sílẹ̀

Nínú ẹsẹ̀ Bíbélì tí a kà lónìí (Máàkù 6:35-36), ipò tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wà jọ èyí tí ọ̀pọ̀ lára wa wa bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú Jésù lónìí.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti rẹ̀wẹ̀sì nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù àti láti máa sin àwọn èèyàn, wọ́n sì fẹ́ sinmi. Kò pẹ́ tí wọ́n n sinmi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ya lù wọ́n, tàwọn ti ọ̀pọ̀ ìbéèrè wọn.

Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kò jọ pé àwọn ènìyàn náà fẹ́ kúrò níbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n jẹ́ ilẹ̀ ahoro kò sì sí oúnjẹ níbẹ̀. Ohun tí wọ́n fẹ́ láti ṣe ni pé kí wọ́n bi Jésù kí Ó rán àwọn ènìyàn náà lọ, kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe.

Lọ́pọ̀ ìgbà, àwa náà máa ń fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tí àìní wọn kọjá agbára wa. A sábà máa ń ronú nípa ìṣòro dípò ohun tó ṣeéṣẹ. Bákan náà, bíi ọmọ ẹ̀yìn, a máa ń ti gbogbo ìṣòro pátápátá sí Jésù lọ́run kó lè yanjú rẹ̀, dípò kí á béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ pé báwo la ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ọ̀pọ̀ àdúrà wa ló dà bí ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn—Jésù, jọ̀wọ́ gba ojúṣe yìí kúrò lọ́wọ́ wa!

Ṣe Àṣàrò:

Láìsí ìṣe olóòtítọ́ Ọlọ́run, a ò bá máa tiraka láti gbọ́ bùkátà ara wa láìní ìrètí àyípadà nínú ìgbé áyé. Ṣùgbọ́n a ti gbìn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú ọkàn àwọn tó gbà á gbọ́, Ó sì ti fún wa ní ìkúndùn á ti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti lè rí agbára Rẹ̀ tó ń yíni padà.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò fi bẹ́ẹ̀ ní ohun àmúlò, síbẹ̀ Jésù sọ ohun tí wọ́n ní di púpọ̀ láti bọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá. Kíni àwọn ohun àmúlò tí ó ní tí Ọlọ́run lè mú pọ̀ sí i kó sì lò fún ìbùkún àwùjọ rẹ? Kì í wulẹ̀ ṣe ohun àmúlò tara nìkan ni, àmọ́ ó tún lè jẹ́ ọgbọ́n tàbí àkókò.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

A Biblical View On Social Change

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Krìstẹ́nì ni bíbá àìní yálà nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí jẹ lógún. Kíni ó yẹ kí jẹ́ ọ̀kúndùn jùlọ fún wa bíi Krìstẹ́nì? Kíni a leè kọ́ láti inú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yí?

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Tearfund fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://www.tearfund.org/yv