A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ RékọjáÀpẹrẹ

Greatly Loved

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi gba irọ́ náà gbọ́ wípé mi ò tó, ìpìlẹ̀ mi kò tó, ìdílé mi ò tó, ìtàn mi gan-an kò sì tó. Ó rí bíi pé mo yàtọ̀ síra, kò sì sí ẹ́ni tó lóye ẹni tí mo jẹ́ gáan. Nítorí náà, mo lo ọ̀pọ̀ ọdún ní ìgbìyànjú àti yíra mi padà sínú ẹyà ohun tí mo rò wípé ó tọ́.

Njẹ o ti fí igbàkanri nimọ̀lara wípe o ni láti rẹ ará rẹ sílẹ, ẹni ti o jẹ, ìbí tí o tí jade wá, ṣe ìrẹlẹ àpèjúwe rẹ, tabi yi ẹni ti o jẹ ní tòótọ pada ki o le rí itẹwọgbà àti imuṣiṣẹ ní àwọn ààyè ti Ọlọ́run fi ọ sí bí?

O jọ wipe ohún yíi ní ọta n ìrètí wípé kí a ṣe.

Nígbàtí a bá dáhùn si àwọn orúkọ ti kò tọ, a gbe ìgbé ayé ìtàn tí ko tọ. Àwọn ìtàn ẹtan ti a gbàgbọ́ nípa ará wa le de wa ni ìde sí ilana ìgbé ayé tí ko tọ.

Òtítọ ni wípé ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ gáan, itan-akọọ́lẹ, àti àwọn àlàyé rẹ gẹgẹ ni Ọlọ́run fẹ́ lo fún àkókò yíì gẹ́lẹ́.

Bẹ́ẹni, Ọtá náà fẹ láti fi yé ọ wípé àwọn àpèjúwe rẹ kò ni ìyí. O jẹ́ ewu tí ko le gbà láyè fun ọ láti ṣàwarí irú ẹdá tí o jẹ àti kí o gbé ìgbé ayé na.

Àkókò tó láti kọ̀ dàalẹ àwọn itàn-akọọ́lẹ èké àti láti gbé ilé-ayé gégébí ẹni tí a jẹ gàan.

Fún ẹni tí o lérò wípé òun o ní ìyí tàbí òun kéré jù…o pọ̀ ju ohún tí à sọ fún ọ lọ. Ọlọ́run pè ọ́ ní iṣẹ́ àṣétán-iyì Rẹ̀ (Éfésù 2:10).

Àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ Alágbẹ̀dẹ ọ̀run àti ayé. Nígbàtí àwọn ayàwòrán bá ṣẹda nkán kan, wọn má n mọ̀ọmọ nípa tí àlàyé rẹ kékèké. Àwọn olùyàworán yan igifẹlẹ kan pàtó láti tẹ sí ojú òfo páálí. Àwọn eléwì yan ètò kan pàtó láti ṣe ara ìtàn. Àwọn onijo pinnu ìgbésẹ ti o dára jùlọ fún àkókò kán nínu orin. Àwọn olùyàworán àti àwọn òṣeré fíìmù nṣàwarí àlàfo ti o dára jùlọ, iná, àti àwọn àwoara láti ṣe àgbéjáde ìtàn kíkún ti wọ́n pinnu láti sọ.

Àwọn ayàwòrán máa ń ṣe àyẹ̀wò kínníkínní - mo gbóya sọ wípé, yányàn - àti lo àkókò wọ́n láti ṣẹ̀dà iṣẹ́ kàn tí wọ́n lè fi yangàn. Èyí tó ju ìyẹn lọ ni ìpinnu Ọlọ́run nígbàti Ó dá wa. Ó yan irú fẹlẹ kan, abẹ̀lẹ̀ kan, ìlù rikiki kan, àlàfo kan, àti ojú-ora láti fi ìgbésí ayé rẹ sípò tó dára fún ire rẹ àti ògo Rẹ̀.

Ìwọ jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí a ṣe pẹlú àfiyèsi láti jẹ́ iṣẹ́ rere ti Ọlọ́run. Iwọ kìí ṣe iṣẹ́ àmì tí a kàn kọlu. Iwọ́ jẹ iṣẹ ọwọ tí o dára. O jẹ òhun iyangan. O jẹ ìpilẹ̀ṣẹ̀, àṣa-ṣé nípasẹ Ẹlẹdàá ohùn gbogbo.

Àṣétán-iyì Ọlọ́run. Ìyẹn ni orúkọ rẹ.

Fún ẹni ti o bá tiju ara rẹ̀ nitori ohun tí a ti sọ nípa rẹ, ohun tí o tí fi ṣe, tàbí ohun tí a ṣe síi…iwọ ju ohun tí a ti sọ sí ọ lọ. A pè ọ ní Tẹmpili níbi tí Ẹ̀mí Mímọ́ ń gbé ( 1 Kọ́ríńtì 6:19)

Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè gba ohun tí a kọ́, ọ́rẹ́ Ọlọ́run, íyi atinuda rẹ. Bíótilẹ wù ẹniti o báà ti rẹ ọ jẹ, tí o lo agbára wọ́n láti ṣe ìpalára fún ọ, àti pe ohunkóhun ti o lérò wípé o pàdánù nitori àwọn ayanfẹ rẹ, nigbati o ba fi ayé rẹ fun Kristi, Ọrọ Ọlọ́run pe ará rẹ ni ìbí ti Ẹmi Mímọ̀ n gbé. Ara rẹ dára. O níye lórí. Ìgbàgbogbo ni o ti níye lórí. Àwọn ènìyàn kò ní agbára láti díyele iyì rẹ́ gan-an, èyí tíó túmọ̀ sí wípé wọn kò lè gbà á lọ́wọ́ rẹ.

A kò ṣe àsọye rẹ nípasẹ ohun tí o ṣe tàbí ohun tí a ṣe si ọ.

Tẹmpili Ọlọ́run. Ìyẹn ni orúkọ rẹ.

Máṣe jẹ́ ki Ọta wá tọwọ́bọ ohun ti Ọlọ́run ṣe dára dára, fun ohun réré, ati lati mu ogo wá fun Un.

Lóni, pe Ọlọ́run si àwọn ààyè ìtàn rẹ ti o tútù ki o si béèrè l'ọwọ Rẹ láti mu ọ lára da. Gbàdúrà wípé ki O fún ọ ni ojú Rẹ̀ láti ri ìgbésí ayé rẹ àti ìtàn rẹ.

Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

Greatly Loved

Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Hosanna Wong fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://hosannawong.com/greatlyloved