A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ RékọjáÀpẹrẹ

Greatly Loved

Ọjọ́ 3 nínú 5

Nínu gbogbo orúkọ tí Ọlọ́run fún wa, Ọmọ Ọlọ́run sì jẹ́ orúkọ tí ó nira jùlọ fún mi láti ni òye rẹ ní kikun.

Bóyá ó jẹ́ pé ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí ọmọde dà bí ikanju láti dàgbà, ati mi kò ní ẹ̀kọ́ tó pé nípa bí ó ṣe yẹ kí a gbe bí ọmọde.

Njẹ di bí ọmọ túmọ̀ sí pé o ni ààbò àti ìtọju láì ní ìbànújẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la? Lati ní ìfẹ̀ sí nkan àti láti gba ewu? Lati sinmi, láti ní ayọ, àti láì ní ìwùwo ayé?

Iyẹn kì í ṣe ìgbà ọmọde mi.

Bàbá mi gbógun ti afẹsodi, ó jà nínú ẹgbẹ́ kan, ó sì ń gbé pẹ̀lú arùn Hepatitis C. Ẹnikan sọ fún un nípa Jesu, ó sì yí ayé rẹ̀ padà (yìn Ọlọ́run!). Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn òpó San Francisco sí àwọn ọ̀rẹ́ wa tí ń gbé níta ilé àti tí ń jà pẹ̀lú ayé afẹsodi. Inú mi dùn sí àwọn àdúgbò, tí wọ́n tọ́ mi dàgbà, ó sì yà mí lẹ́nu pẹ̀lú ohun tí a rí tí Ọlọ́run ń ṣe, ṣùgbọ́n ó tún wá pẹ̀lú ìgbà ọmọde tó nira. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọde, mo rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń pa ní iwájú mi, wọ́n ṣe àwọn òbí mi méjèèjì léṣe, àti oríṣiríṣi oògùn olóró tí wọ́n ń tà tí wọ́n sì ń lò. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, bàbá mi ní àrùn jẹjẹrẹ ó sì kú.

Mo kọ́ ẹ̀kọ́ ní kíákíá láti gbé awon ise ti tó wúwo, bá ìbànújẹ ṣiṣẹ, je eni ti o le, àti láti ṣiṣẹ́ takuntakun. Awọn anfani ati alailanfani wa ninu ohun ti o ṣẹlẹ. Mo lo ọdún ìdàgbàsókè mi pẹ̀lú ìwọ̀n ìdààmú láti jẹ́ ẹni tí ń ṣiṣẹ́ dáadáa ati lati je olùdarí, lai ní ìsinmi, nínú ìbànújẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, láì ní ìmọ̀lára ọmọde kankan nínú ìgbé ayé mi. Mo fà ìbànújẹ́ tó jinlẹ̀ sí àwọn ènìyàn kan ní ìgbà yìí.

Ní awon ọdún tó kọja, mo ti wa lórí ìrìn àjò lati tun mo ohun tí eyi orúkọ kan ṣoṣo túmọ̀ sí.

Fún ẹni tó ti gbe pẹ̀lú ẹru ayé lórí Èjìká rẹ... O ju èyí tí wọ́n ti sọ fún ọ lọ. Ọlọ́run pè é ní Ọmọ Rẹ̀ (Gálátíà 3:26).

Nígbà tí a bá fi ayé wa fún Jesu, a gba láti tún kọ́ ẹ̀kọ́ ohun tó túmọ̀ sí jíjẹ́ ọmọde. A lè fi àwọn ẹrù tí a kò yẹ kí a gbe nikan Fún un. Ó dájú pé a wa ní ààbò ju bi a ṣe rò lọ – láti gbàgbọ́, lati tẹsiwaju pẹlu ohun tí kò dájú, lati tẹle ọna igbagbọ, láti sinmi, láti ní ìdùnnú, àti láti ṣe ayẹyẹ bí ọmọde tí ó wa ní ààbò àti tí a fẹ́ràn.

Ọmọ Ọlọ́run. Èyí ni orúkọ rẹ.

Fun ẹni ti o ro pe iwọ ohun o le ri itusilẹ kúrò nínú ìtìjú ẹni tí o ti jẹ́ tàbí ohun tí o ti ṣe… o ìwọ jẹ́ ju ohun tí wọn ti sọ fún ọ lọ. Jésù pè ọ ni Ọfẹ, Ní tòótọ́ (Johannu 8:36).

Nígbà tí a bá fi ayé wa fún Jésù, Ẹ̀mí kan náà tí ó jí Jésù dìde kúrò nínú òkú ń gbé inú wa báyìí. A ní irú ìwà tuntun, ìmúrasílẹ̀ tuntun, àti agbára tuntun tí ń pọ sí nínú wa.

Bí Ọlọ́run kò bá tó láti jí wa dìde kúrò nínú òkú, bí kò bá tó láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí kò bá tó láti rà wá padà kúrò ní gbogbo ibi tí a ti wà, nígbà náà kò lè tó láti jí Kristi dìde. Nítorí náà, a ti di alààyè, tàbí Jésù kò tí í jí.

Ṣùgbọ́n nitori pe kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ - ibi ìkú náà ti ṣófo ati kò sì sí egungun Olùgbàlà kankan tí ń wà nínú ibi ìkú. - a mọ̀ pé iṣẹ́gun ti wa lori ikú fún ìgbà pípẹ́.

Iwọ kì í ṣe ẹlẹ́wọn pelu Ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ rẹ

Ìtùsílẹ̀, Ní tòótọ́. Eyi ni orukọ rẹ.

Ọ̀rẹ́, o lè máa gbé ẹrù tí o ye ki o gbé mọ́. O lè máa gbé nínú ẹ̀wọ̀n tí kò yẹ kí o gbe mọ́.

Fi wọ́n sílẹ̀ fún Ọlọ́run, kí o sì gbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọlọ́run òmìnira tí o jẹ́ gan-an.

Day 2Day 4

Nípa Ìpèsè yìí

Greatly Loved

Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Hosanna Wong fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://hosannawong.com/greatlyloved