A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ RékọjáÀpẹrẹ

Greatly Loved

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ǹjẹ́ ó ti ṣe bíi pé wọn ò rí ẹ, pé wọn ò fé ẹ, pé ò já mọ́ nǹkan kan, tàbí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ? Tí o bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ kò sí ṣe aṣiwèrè, àti pé ìwọ nìkan kọ̀ lo wà nínú ìṣòro yìí. Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀tá ọkàn wa ti ń bá wa jà, nítorí ó mọ irú ẹni tí a jẹ́ gan-an.

Kò fẹ́ kí a mọ̀ pé a jẹ́ ẹni tíA fẹ́ràn lọ́pọ̀ lọpọ̀. Àyànfẹ́. Tí a fẹ́. Ó yẹ kí a ja fúnÓ mọ̀ pé tí a bá ṣàwá rí ẹni tí a jẹ́, a o bẹ̀rẹ̀ láti gbé ni ìgboyà. Yóò yí ìwòye wa àti ìdúró wa padà, bí àwọn ọmọ Ọlọ́run bá sì ń gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n pinnu láti ṣe, èyí á jẹ́ ewu tó ga jù lọ fún ètò rẹ̀.

Ó ṣé ṣe kí wọ́n ti sọ pé o tò, o ṣe tó, tàbí o ṣe pàtàkì bí àwọn ẹlòmíràn. Ó kò lé ni òmìnira láti àwọn ìrora tí o tí ní tẹ́lẹ̀, tàbí pé ìwọ yóò wà nínú ìdádúró títí láé láì ní àṣeyọrí.

Mo tí la gbogbo nǹkan wọ̀nyí náà rí. Mo fẹ́ sọ ohun tí mo fẹ́ kí ẹnìkan tí sọ fún mi ní ọdún sẹ́yìn fún ọ: o ju ohun tí wọ́n sọ fún ọ lọ.

Kò sí ẹni tó lágbára láti ṣàpèjúwe rẹ bí kò ṣe Ẹni tí ó dá ọ.

Ọlọ́run sì lo àkókò púpọ nínú Bíbélì láti sọ fún wà irú ẹni tí a jẹ́.

Ní gbogbo ọjọ́ eto ọlọjọ́ márùn-ún yìí, a ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run pé wà ṣi.

Bí a ṣe ń fí ojú Ẹlẹ́dàá wo ara wa, a óò tú rí irú ẹni tí a jẹ́ dáadáa àti irú ẹni tí a jẹ́ nígbà gbogbo.

Fún ẹni tí ó rò wípé òun jẹ́ ẹni ìríra, tí ọkàn rẹ bàjẹ́ gan, tí ó sì dàbí pé àwọn nǹkan tí o ti kọjá ko le ni ìràpadà… o ju ohun tí wọ́n sọ fún ọ lọ. Ó jẹ́ ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ dáradára.

Romu 5:8 sọ pé “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wà hàn nínú èyí pé: nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.”

A fẹ́ wa gan débi pé nígbà tí a ń lòdì sí Ọlọ́run, Ọlọ́run wà fún wa. Kí a tó yan Ọlọ́run, Ó tí yan wa. Nígbà tí a ń sá fún, Ó ń sáré tẹ̀ lé wa lẹ́yìn. Nígbà tí a ń ṣiyèméjì. Ní àkókò tí a tí ń dá a dúró tàbí tí a ń mú un ní ìlà apá. Ìfẹ́ tí ó ní sí wa jẹ́ ìfẹ́ tó kọjá ààlà, ìfẹ́ tó máa ń fara dà á, àti ìfẹ́ tí kò ní dópin débi pé ó rán Jésù ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo wá sáyé láti ku fún wa.

Kò sí ohun tí o tí ṣe tí o jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní sí ẹ dín ku. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ nígbà náà. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ báyìí. Kò tí jáwọ nínú nínífẹ̀ẹ́ rẹ. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ sí.

Ó wa fún ọ ní báyìí ní àkókò yìí. Ò máa wù láti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ.

Ẹni a nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. Orúkọ rẹ ní yẹn.

Ọ̀rẹ́, bí a ṣe ń wá ọ̀nà láti tú àṣírí irọ́ ọ̀tá àti láti tú òtítọ́ Ọlọ́run sílẹ̀, àwọn ìbéèrè díẹ̀ nìyí láti béèrè:

  • Ohùn ta ní ó dún jù lọ ní ìgbésí ayé mi?
  • Èrò ta ni mo kà sí pàtàkì jù lọ?
  • Ta ló sọ ohun tí kò dáa nípa mi rí tó sì nípa lórí ojú tí mo fi ń wo ara mi?
  • Àṣẹ wo ni wọ́n ní láti sọ ẹni tí mo jẹ́?

Èyí ní díẹ̀ nínú àwọn òtítọ tí a o ṣàyẹ̀wò wọn:

  • A kò ní ẹni tí a jẹ́ nípasẹ̀ àwọn èèyàn mìíràn tí wọn kò mọ ẹni tí a jẹ́.
  • Ohùn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ ohùn tí o dún jù lọ nínú ìgbésí ayé wa.
  • Ojú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan ló yẹ kó jẹ́ ojú ọ̀nà tá a gbà ń wo ara wa.

Má ṣe jẹ́ kí ọ̀ta náà borí ẹ̀dá tàbí ẹ̀mí yín. Lónìí, ẹ fi àwọn orúkọ àtayébáyé yín sílẹ̀, èyí tí ó ti fi yín hàn fún àkókó gígùn. Yàn láti máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ ṣe ìkọ́ni.

Nígbà tí ó bá mọ irú ẹni tí ó jẹ́, ó máa yí bó o ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ pada.


Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Greatly Loved

Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Hosanna Wong fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://hosannawong.com/greatlyloved