A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ RékọjáÀpẹrẹ
Ṣé mo lè ṣí ara mi payá fún ọ?
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àkókò tó máa ń dunni jù lọ láyé mi.
Wọ́n ti tàn mí jẹ, wọ́n sì tún jàmílólè. Ojú tì mí. Àwọn tí mo rò pé wọ́n á dúró kò dúró. Àwọn èèyàn tí mo rò pé wọ́n máa gbè mí níjà kò ṣe bẹ́ẹ̀. Mo nímọ̀lára pé a ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí a kò sì fẹ́ mi. A ti fi gbogbo owó àpamọ́ wa sínú iṣẹ́ kan tá a rò pé Ọlọ́run ti pè wá sí, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí tí ó bani nínú jẹ́, ó forí ṣánpọn. A pàdánù gbogbo owó àpamọ́ wa, a sì wà ní ọwọ́ òfo, pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀, àti àìdánilójú nípa ibi tí a ó ti bẹ̀rẹ̀. Ìtìjú bá mi, mo sì dàbí ẹni tí a ṣẹ́gun.
Àwọn ọgbẹ́ atijọ́ tí mo ti ní rí bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Mo rì sínú ọ̀gbun ìṣẹ́gun. Mo ti gbàgbé ẹni tí mo jẹ́.
Mo ní àṣàyàn kan láti ṣe. Ìwọ náà ní irú ẹ̀.
Ṣé a óò yàn láti jẹ́ kí èrò àwọn ẹlòmíràn àti ìrora àwọn ìlàkọjá wa ṣe ìtumọ̀ wa kí wọ́n sì máa darí wa?
Àbí a óò yan láti jà fún èrò inú wa, ọ̀nà ìrònú wa, àti ẹ̀mí wa?
Nígbà tó yá, mo yàn láti jà fún ayé mi nípa jíjagun láti lo àkókò gidi pẹ̀lú Ọlọ́run.
Kì í ṣe àkókò ojú-ọjọ́.
Kí n lè kúrò nínú ìparun yìí, mo ní láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, kí n fi ara mi fún un, kí n sì jagun tọkàntọkàn láti mú kí ohùn Ọlọ́run jẹ́ ohùn tó lágbára jù lọ nígbèésí ayé mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá àkókò púpọ̀ sí i láti wà pẹ̀lú Rẹ̀, mo sì ń gbàdúrà ní pàtó, mo sì ń fi sùúrù ka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ láti mọ ohun tí Ó sọ nípa mi.
Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rí ara mi nípasẹ̀ ojú ìwòye rẹ̀, ọkàn mi tó ti rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọjí.
Mi ò mọ irú irọ́ tí wọ́n pa fún ọ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní àwọn orúkọ mìíràn fún ọ.
Fún ẹni tí ó bá nímọ̀lára ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ìdánìkanwà... o ju ohun tí a ti sọ fún ọ lọ. Jésù pè ọ́ ní ọ̀rẹ́ Rẹ̀ (John 15:15).
Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì fẹ́ràn rẹ. Ó ń ṣètìlẹ́yìn fún ọ. Ó wà ní ìhà rẹ. Ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ nígbà gbogbo.
Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Èyí ni orúkọ rẹ.
Ní ígbà tí o bá rí i pé orúkọ àtijọ́, èrò àtijọ́, àti èrò àwọn ènìyàn nìpa rẹ ní àtijọ́ ti fẹ́ê ya bóorán mọ́ ọ lọ́wọ́... mọ̀ pé o ju ohun tí wọ́n ń pè ọ́ lọ. A pè ọ́ ní Ẹ̀dá Tuntun (2 Corinthians 5:17).
Nígbà tí a bá pinnu láti tẹ̀lé Jésù ní tòótó, kí a sì tẹ̀lé àwọn ọ̀nà Rẹ̀, ìgbésí ayé ọ̀tun bẹ̀rẹ̀. A kì í ṣe àwọn orúkọ àtijọ́ wa mọ́. A kì í ṣe àwọn ọ̀nà ìrònú wa àtijọ́ mọ́. A kì í ṣe àwọn àṣìṣe wa àtijọ́ mọ́. Títẹ̀lé Jésù jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó fi ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó fúyẹ́ àti tí ó lómìnira hàn wá.
Ẹ̀dá Tuntun. Èyí ni orúkọ rẹ.
Ní àkókò ìrora náà, mo kọ ewì kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ “I Have a New Name,” tí ó ń kéde orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè wá. Ó jẹ́ àfìhàn ní ṣókí àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ. Mo gbàdúrà pé kí ó fún ọ ní ìṣírí.
Mo gbàá ní àdúrà kí a lè mọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a jẹ́ ní tòótọ́.
Àkókò ti tó láti dìde kúrò ní ipò ìparun, kí a sì jagun láti lo àkókò gidi pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ìwọ yóò ṣàwárí ẹni tí o jẹ́ ní tòótọ́ nígbà tí o bá lo àkókò gidi pẹ̀lú Ẹni tí ó mọ̀ ọ́ jùlọ.
(Ewì mi, "I Have A New Name," Wo gbogbo fọ́ọ́rán fídíò rẹ̀ ní ìsàlẹ̀.)
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.
More