Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò KérésìmesìÀpẹrẹ
Ayọ̀
Àwọn orin Kérésìmesì yóò jẹ́ kí a gbàgbọ́ wí pé èyí ni àkókò l'àti yọ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wa la ní ohùn kan l'áti yọ̀ lé l'órí, kò sì sí ẹni tí ó lè ní ayọ̀ ní ìgbà gbogbo. A dúpé wí pé bí ó ti lè jẹ́ wí pé ìdùnnú dá l'ori ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa, a lè ní ayọ̀ ní ìgbà gbogbo.
A lè pààrọ̀ àwọn òrò méjèèjì wọ̀nyí nínú àṣà wa - ìdùnnú àti ayọ̀, ṣùgbọ́n wọn kìí ṣe ìkan náà. Inú wa lè dùn ní ìgbà tí ojú ọjọ́ bá dára, tí àwọn ọmọ wa ṣè ìgbọ́ràn, tí a bá gba ìsinmi, tàbí tí a ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun kan. Ìmọ̀lára tí kò jìnlẹ̀ yìí ni ìdùnnú. Ayọ̀ jẹ́ nkan tí ó jìnlẹ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ. Kò dá l'órí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Kò ní ǹkankan l'àti ṣe pẹ̀lú àwọn ohun ti ayé yìí. Ó dá l'órí Kristi nìkan. Ayọ̀ wà nínú ìgbàlà wa àti nínú ẹbọ tí ó jẹ́ kí ayérayé wa dájú.
Ní àwọn àkókò ìkẹyìn ṣáájú ikú Jésù, ọ̀kan l'ára àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́ àgbélébùú náà béèrè wí pé kí ni ìdí tí Jésù kò fi gba ara Rẹ̀ là bí Òun bá jẹ́ Mèsáyà náà ní òtítọ́. Ibeere ti o tọ́ ni èyí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti rí ibi tí wọ́n ti ń kan ènìyàn mọ́ àgbélèbúu Róòmù, àti ní pàtàkì ẹni tí ó ń ní ìrora nlá kan náà yóò béèrè ìbéèrè kan náà. Kíni ìdí tí o yàn l'áti fi ara da èyí tí o kò bá ní l'áti fi ara dà á?
Nínú ìwé sí àwọn Hébérù, Pọ́ọ̀lù Àpọ́stélì sọ wí pé Jésù fi ara da àgbélèbú “nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú Rẹ̀.” Rárá o, ikú oró ní ìtorí ẹ̀ṣẹ̀ wa kìí ṣe ohun tí ó dùn mọ́ Jésù. Ó ní ìdààmú ọpọlọ, ìmọ̀lára, àti ti ara. Kò lọ sí àgbélèbú pẹ̀lú ìdùùnú, sùgbọ́n pẹ̀lú ayọ̀. Jésù mọ̀ wí pé ohun tí ó ń dúró de Óun ni ayérayé pẹ̀lú Baba àti ìdàpọ pẹ̀lú wa. Ó ní ayọ̀ ní ìtorí wí pé ikú àti àjíǹde Rẹ̀ yóò bo orí ìwà ọ̀dàlẹ̀, ìrora ọkàn, ìrora, àti ikú ayé yìí.
A ní ayọ̀ fún ìdi kan náà pàtó. Pàápàá ní àwọn àkókò tí ó nira jù lọ, a ní ayọ̀ ní ìtorí a mọ́ wí pé a ní ìrètí ayérayé àti ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi hàn wá, níní ayọ̀ kò túmọ̀ sí wí pé a kì yóò ní ìrora láé. Ní ìtorí náà ní ìgbà míràn ní ayé yìí, ayọ̀ àti ìrora yóò wáyé papọ̀. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Kristi, a lè wò kọjá ìrora náà sí ohun tí a ti ṣe ìlérí fún wa kí a sì mọ̀ wí pé Ọlọ́run ní púpọ̀ síi fún wa. Ní ọjọ́ kan, a yóò tùn da ara pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ ní ibi tí kò ní sí ìbànújẹ́, ẹkún, tàbí ìrora mọ́.
Bóyá ní ákókò ìsinmi yìí àwọn àna rẹ ń ṣe l'òdì sí ọ l'áì dákẹ́, o wà ní àárín ìnira owò, tàbí ò ń tiraka pẹ̀lú àyẹ̀wò tí ó ń bà ọ́ l'ẹ́rù. Bóyá o kán ríi wí pé ó nira l'áti ní ìdùnnú. Ohunkóhun tí ò ń là kojá ní ákókò Kérésìmesì yíì, mọ̀ wí pé Ọlọ́run ní òye rẹ̀. Ó rí ọ, Ó fẹ́ràn rẹ, kì yóò sì fi ọ́ s'ílẹ̀ nínú ogbẹ́ rẹ. Ní áàrín ìbànújẹ́ rẹ síbẹ̀síbẹ̀, o ṣì ní ayọ̀ ní ìtorí wí pé a ti ṣe ìlérí ayérayé rẹ, òtítọ́ sì ni àwọn ìlérí Rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.
More