Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò KérésìmesìÀpẹrẹ

Living Changed: At Christmas

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìfojúsọ́nà

Àkókò ìsinmi kún fún ìyanu àti ayọ̀. Ó ní oun púpọ̀ láti fojú sọ́nà sí pẹ̀lú àwọn ìfihàn iná Kérésìmesì, àwọn pàsí pààrọ̀ ẹ̀bùn, àwọn àpéjọ ìdílé ńlá, àti àwọn oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ tí a jẹ ní àkókò ọdún yìí. Ìfojúsọ́nà àti ìdùnnú kún afẹ́fẹ́ bí a ṣe ń múra sílẹ̀ láti ṣe ayẹyẹ ìbí Jésù.

Irú ìfojúsọ́nà kan náà wà láàrín àwọn Júù nígbà tí a bí Jésù. Wọ́n tí fi ojú sọ́nà fún bíbọ̀ Olùgbàlà. Ẹni tí yóò wá gbà wọn là. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọrun ọdún sẹhin, ní Ọlọ́run ti ń sọ fún wọn nípa ètò Rẹ̀ láti gbà wọ́n silẹ, gbogbo rẹ̀ yóò sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbí láti ipasẹ̀ wúńdíá kan.

Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù, Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀ pé: “Nítorí náà, Olúwa tìkára rẹ̀ yóò fún ọ ní àmì kan: Wúńdíá náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọdékùnrin kan, a ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Immanueli"

Ó kú díẹ̀ kí a bí Jésù, àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà tún wà láti ẹnu wòlíì. Áńgẹ́lì kan sọ fún Jósẹ́fù, bàbá Jésù nípa tí ayé lójú àlá pé:

Òun yóò sì bí ọmọdékùnrin kan, ìwọ yóò sì sọ orúkọ rẹ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ láti mú ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì náà ṣẹ:“Wúńdíá náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọdékùnrin kan, wọn yóò sì pè é ní Immanuẹli” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run pẹ̀lú wa”).

Eléyìí jẹ́ àpẹẹrẹ kan nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà sì ìmúṣẹ pẹ̀lú ìbí Jésù. Lẹ́yìn náà, jákèjádò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, ó tún bá àwọn ènìyàn Rẹ̀ ṣèlérí púpọ̀ sí i nípa ohun tó ń bọ̀. Ó ní Òun yóò jíǹde kúrò nínú òkú yóò sí borí ẹ̀ṣẹ̀. Ó sọ pé Òun yóò rán Ẹ̀mí Mímọ́ bí olùrànlọ́wọ́ láti ṣe amọnà wọn. Ó ní Òun yóò lọ pèsè ààyè sílẹ̀ fún wọn àti pé Òun yóò padà wá mú wọn ní ọjọ́ kàn. Nítorí pé Ọlọ́run mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ láti rán Olùgbàlà wa, àwọn ènìyàn náà tún gba àwọn ìlérí wọ̀nyí gbọ́.

Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ìlérí wọ̀nyí tí ó yẹ̀. Ọ̀kọ̀ọkàn nínú gbogbo wọn kò kùnà títí òní olónìí! Bí a ṣe lè wo ìbí Jésù nìyẹn, ká sì mọ ìmúṣẹ ìrètí àti ìrètí tó ń bọ̀. Gẹ́gẹ́bí àwọn Júù ṣe dúró de bíbọ̀ Olùgbàlà, àwa náà ń dúró de ìlérí ìpàdabò rẹ̀.

Bí o ṣé ń lò àkókò ìsinmi yíì, ní ìgbàgbó pé àwọn ìlérí Ọlọ́run jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé àti òtító rẹ. Kìí ṣẹ fún àwọn mìíràn, ṣùgbọ́n pàtàkì julọ fún ọ. Nígbàtí o bá ń tiraka, yàn láti fojú sún ẹni tí Ó jẹ́ àti gbogbo ohun tí Ó ṣe fún ọ. Pẹ̀lú ìrísí ayérayé, ó ṣeé ṣe láti gbé nínú ìsinmi yìí pẹ̀lú ìrètí ní àwọn ipò àìní ìrètí, ìgbàgbọ́ nínú àwọn àkókò ìgbìyànjú, ayọ̀ laibikita àwọn ipò wa, àti àlàáfíà ní àárín rúdurùdu.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: At Christmas

Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.

More

A fé dúpé l'ọ́wọ́ Changed Women Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí'wájú síii, ẹ ṣe ìbẹ̀wò https://www.changedokc.com