Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò KérésìmesìÀpẹrẹ
Ìgbàgbọ́
Kò ṣòro fún pọ̀pọ̀-ṣìnṣìn ọdún Kérésìmesì láti gba àkókò wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí a gbàgbé ohun tí a ń ṣe àjọyọ̀ rẹ̀ gan. Bí ó ti wù wá tó láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tó yí wa ká, nígbà míràn a máa nira láti já ara wa gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn ìpèníjà tó kojú wa lákòókò náà. Dípò àníyàn, ìbínú àti ẹ̀dùn ọkàn tí a kó pamọ́ sí àyà wa, ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ lákòókò ìsinmi yìí.
Nínú lẹta rẹ̀ sí àwọn ará Éfésù, Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe àlàyé bí ìgbàgbọ́ wa ti lè mú ìrísí wa dúró nígbà tí ó rọ̀ wá láti gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀ lójojúmọ́. Ó wá ka àwọn ẹ̀yà ìhámọ́ra yìí síta ní ẹyọ kàànkan: àmùrè òtítọ́, ìgbàyà òdodo, bàtà ti ìhìn rere àlàáfíà, asà ìgbàgbọ́, fìlà ìgbàlà onírin, àti idà ti Ẹ̀mí, èyí tí íṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀yà kàànkan nínú ìhámọ́ra yìí wà láti rán wa létí agbára àti ìpamọ́ tí a ní nínú Kristi.
Ǹkan ìyanu ibẹ̀ wá ni wípé, ẹ̀yà ìhámọ́ra kan tí Pọ́ọ̀lù túbọ̀ ṣe àlàyé nípa rẹ̀ ni asà ìgbàgbọ́. Ó sọ wípé ó ní agbára láti “máa paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi nì.” Kàn fara balẹ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi ojú inú wo ǹkan tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ọfà iná ń fò wá sí ibi tí o wà, lọ́gán o fi asà rẹ dá wọn dúró. Ìgbàgbọ́ wa jẹ́ ohun ìjà tó lágbára láti dojú ìjà kọ gbogbo ète ọ̀tá wa!
Nígbà mìíràn, a lè ní ìdàrúdàppọ̀ ọkàn nípa ẹni tí ọ̀tá náà jẹ́. A lè fẹ̀sùn kan àwọn tí ń ra ọjà ọdún bíi tiwa tó hùwà tí kò tọ́ sí wa, ọ̀gá tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ wa ní ọjọ́ díẹ̀ sí Kérésìmesì, tàbí ẹbí tí máa ń fí gbogbo ọjọ́ ayé yìí bu ẹnu àtẹ́ lù wá. Àmọ́ àwọn tó yí wa ká kìí ṣe ọ̀tá wá. Ọ̀tá ojúlówó tí a ní ni Èṣù ẹni tí ń dọdẹ káàkiri bíi kìnìún tí ń wá ọ̀nà tí yóò gbà jí ayọ̀ wa, paná ìrètí wa, tàbí tẹ àlàáfíà wa lójú mọ́lẹ̀. Òtítọ́ tí ń bani lẹ́rù ni èyí tí a kò gbudọ fi ṣeré, ṣùgbọ́n tí a kò nílò láti fòyà fún. Ọlọ́run wa tóbi ju ohunkóhun tó lè dojú ìjà kọ wá.
Pẹ̀lú bí ìhámọ́ra yìí ti jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ìdáàbòbò wa, a sì ní láti máa ṣe àmúlò rẹ̀ ní ìgbà dé ìgbà. O lè rọrùn bíi àdúrà olójojúmọ́ bí èyí:
“Ọlọ́run, mo mọ̀ wípé inú ìjàkadì ti ẹ̀mí ni mo wà mo sì jẹ́rìí Rẹ fún ìdáàbòbò. Mo wọ àmùrè òtítọ́; ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ àti láti máa sọ òtítọ́ nìkan. Mo gbé ìgbàyà òdodo wọ; dáàbò bo ọkàn mi kí o sì ràn mí lọ́wọ́ láti ṣí ọkàn payá sí ìtọ́ni Rẹ. Mo wọ bàtà Ìhìn Rere àlàáfíà; ràn mí lọ́wọ́ láti máa jíhìn Rẹ fún àwọn ẹlòmíràn àti láti mú àlàáfíà lọ sí ibikíbi tí mo bá wà. Mo gbé asà ìgbàgbọ́ wọ̀; ràn mí lọ́wọ́ láti gbójú lé Ọ kí o sì pa mí mọ́ kúrò nínú ìkọlù ọ̀tá. Mo wọ fìlà onírin ti ìgbàlà; pa ọkàn mi mọ́ kí o sì ràn mí lọ́wọ́ láti máa ronú nípa ǹkan dáradára nìkan. Mo mú idà ti Ẹ̀mí; mú Ìwé Mímọ́ wá sí ìrántí mi àti láti ṣe àmúlò rẹ̀ fún ìdáàbòbò mi àti ti àwọn ẹlòmíràn. Àmín!”
Ní àkókò Kérésìmesì yí, ẹ jẹ́ kí a dúró gírí láti kojú gbogbo ìkọlù ọ̀tá. Rántí wípé ìjà yìí kìíṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó yí ọ ká. Dúró ní àárín gbùngbùn òtítọ́ wípé Ọlọ́run fẹ́ ọ dénú dénú kí o ba lè ta àbùkù kàànkan tó bá kángun sí ẹ dànù. Ṣe ohun gbogbo ní ìkápá rẹ láti fẹ́ràn àwọn ènìyàn tó yí ọ ká, pàápàá àwọn tí ìwà wọn kù díẹ̀ káàtó, nítorí o kò mọ ìrora ìkọ̀kọ̀ tí ẹni náà ń là kọjá. Wíwọ gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run lójojúmọ́ máa ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ǹkan tí a ti kà sílẹ̀ yí.
Kí o tó lọ sí ọjà, wọ ìhámọ́ra. Kí o tó ṣe ìtàkúrọ̀sọ tó ní bá, wọ ìhámọ́ra. Kí o tó lọ fún ìpàdé ẹbí, wọ ìhámọ́ra. Kí ìrẹ̀wẹ̀sì tó rápálá wọlé, kí sùúrù rẹ tó pin, àti kí o tó fèsì pẹ̀lú ìbínú, wọ ìhámọ́ra. A lè fi ní ìdánilójú kíkún nínú ìhámọ́ra Rẹ̀ àti agbára ìgbàgbọ́ wa. Nígbà tí a bá jẹ́ olóòótọ́ tí ń wo ojú Ọlọ́run fún ipá, yóò jẹ́ olóòótọ́ nípa ṣíṣe ìdáàbòbò wa.
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.
More