Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò KérésìmesìÀpẹrẹ
Ìrètí
Gẹ́gẹ́ bi Krìstẹ́nì, à ń ṣe àjọyọ̀ Kérésìmesì bíi ọ̀nà tí à ń gbà rántí ìrètí tí a ní nínú JésùKí wáá ni ìdí rẹ̀ tí ó fí rọrùn láti wà ní ipò àìní ìrètí ní àkókò ọdún yí? Bóyá nítorí pé a kò ní ìmọ̀ ohun tí ìrètí jẹ́ àti ibi tí ó tí wá
Jeremáyà 29:11 jẹ́ ẹsẹ Bíbélì tí ó gbajúmọ̀ nípa ìrètí. Ó sọ wípé, "'Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,' ni Olúwa wí, 'àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú."'
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí kàn ṣe ohun tí a lè máa gbé kiri bíi àkọ́lé lásán. Nwọn jẹ ìlérí Ọlọ́run fún wa láti rọ̀ mọ nígbà tí a bá wà ní ipò àìní ìrètí. Bíótilẹ̀jẹ́pé a pilẹ̀ kọ àwọn ọrọ wọ̀nyí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ní ìgbèkùn Bábílónì, Ọlọ́run wà bákannáà lónìí bí ó tí wá ní ìgbà náà
Ni òdodo, tí a bá wà wọn, a ó ríi pé àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wa jẹyọ k'olẹ̀ Májẹ̀mu Láíláí. L'éraléra, nípa àwọn ìtàn àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ọlọ́run ṣe àfihàn Ẹni tí ó jẹ́ pẹ̀lú ìjẹ́rí pé Òun ṣe è gbẹ́kẹ̀le
Ọkàn nínú àwọn ìlérí àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún wa ní a rí ní Jẹ́nẹ́sísì nígbàtí Ọlọ́run sọ wípé Òun yíò bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ Ábráhámù. Nǹkan tí Ọlọ́run ń sọ ni pé Olùgbàlà yíò jẹ́ irú-ọmọ Ábráhámù àti pé yíò gba gbogbo ènìyàn là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn-kì í ṣe àwọn Jùú nìkan, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbágbọ́ nínú Rẹ̀. Lẹ́hìn náà nínú Májẹ̀mú Títún, a rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run jẹ́ olóòtọ́ sì ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ìwé Mátíù fí hàn wá bí ìtàn ìran Jésù ṣe tọ pinpin orísun wọn padà s'ẹhin dé ọ̀dọ̀ Ábráhámù, àti wípé ìwé Jòhánù sọ fún wa pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Jésù yíò ni ìyè àìnípẹ̀kun. Ọlọ̀run wa jẹ́ ẹniti ó ń mú ìlérí ṣẹ́. Òun ni ìrètí ààyè wa
ìrètí kìí wá láti ara ohun ti ara tí a fi ojú rí tàbí ìlérí asán tí ayé yí. Ìrètí òtítọ́ wá láti inú mímọ̀ pé a ó lo ayérayé pẹ̀lú JésùTí a bá ṣe àkàwé rẹ̀ pẹ̀lú ayérayé ni Ọ̀run, ipò wa ní ayé yìí rí bíńtín àti ohun tí ń kọjá lọ ní ìṣẹ́jú aáyá. Ní ìwọ̀n ìgbà tí èyí kò túmọ̀ sí wípé a kò ní ní ìmọ̀lára ìrora, ó túmọ̀ sì wípé a lè yàn láti ní àfojúsùn tí ó tayọ ìrora tí à ń là kọjá lọ́wọ́ lọ́wọ́ sí ọjọ́ iwájú wa ti yíó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ
Ohun yòówù kó jẹ́ tí ó bá ń lá kọjá ní àkókò ìsinmi yí, gbé ojú s'ókè sí àwọn ìlérí Ọlọ́run fún ìrètí. Òun kò ní fí ọ silẹ, kò sì níí já ọ kulẹ̀. Yíò dárí jì ọ nígbà gbogbo àti wípé yíò ṣé atọ̀nà rẹ nígbà gbogbo. Òun ní agbára rẹ, àpáta rẹ, àti ààbò rẹ pẹ̀lú. Nígbà tí ó bá lérò wípé o kò sa ipá tó, o kò ní tó, tàbí kún ojú òsùwọ̀n, rántí wípé gbogbo ìlàkàkà rẹ wà fún àkókò díẹ̀ àti wípé Ọlọ́run ní ohun pupọ́ fún ọ. Ó fẹ́ràn rẹ dénú Ó sì fẹ́ ló àsìkò pẹ̀lú rẹ.Rántí wípé Ó tí ṣe ìlérí ọjọ́ iwájú fún ọ, ó sì kọjá ohun tí ó lè f'òye gbé lọ
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.
More