Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 4 nínú 15

Àdúrà

Ọlọ́run, fi àwọn ohun tí mo máa ń sá lọ fún fún ààbò àti ìtumọ̀ nínú ìgbésí ayé yìí hàn mí. Ran mi lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́ nínú wọn kí n sì fọkàn tán ọ.


Kíkà:

Fojú inú wò ó pé ìwọ nìkan lo la ọkọ̀ ojú omi tó rì já. O máa ń gùn lórí omi fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, o sì máa ń dì mọ́ igi kan tó o rí nínú ọkọ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tó dà bíi pé ìrètí kò sí mọ́, ọkọ̀ ojú omi kan yọ lójú ọ̀run. Láìpẹ́, ọkọ̀ náà á wá sún mọ́ ẹ, ẹnì kan á sì gbé okùn kan lé ẹ lọ́wọ́. Wọ́n sọ fún ẹ pé kó o fi igi náà sílẹ̀ kó o sì di okùn náà mú. Ìpinnu tó rọrùn lèyí, àbí? O ti wà nínú ipò kan tó le koko, o ò sì lè dá bọ́ nínú rẹ̀, ẹnì kan sì ti dé tó fẹ́ láti gbà ẹ́ là, tó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kó o jẹ́ kí igi náà lọ, kó o sì wá ọ̀nà láti mú ọ̀nà ààbò náà. Gbogbo ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kó o fọkàn tán an.


Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé kó o tó mú okùn náà, o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa ìpinnu rẹ, tó o sì ń ronú nípa bí igi yìí ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó o ti ní láwọn ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn lórí òkun. Ó ti wà níbẹ̀ nígbà tó o nílò rẹ̀, o sì ti wá gbára lé e láti lè máa wà láàyè. Ó máa ń ṣòro gan-an láti jẹ́ kí nǹkan míì gbà wá lọ́kàn. Nítorí náà, o kígbe padà sí ọkọ̀ náà pé, "Rárá o. Mi ò ní fi Igi náà sílẹ̀!


Ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu nìyẹn! Àmọ́ yálà a mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò mọ̀, a sábà máa ń ṣe é nígbà gbogbo nínú ìgbésí ayé wa nípa tẹ̀mí. Nígbà tí Jésù ké sí wa láti tẹ̀ lé e, ká sì gbé ìgbésí ayé tuntun gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọba rẹ̀, ńṣe ló ń ké sí wa pé ká gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa lé ẹlòmíì. Ó pè wá pé ká fi àwọn nǹkan tá a ti fọkàn tán tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ fún ààbò wa àti ìjẹ́pàtàkì wa, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí orísun wa tuntun. Àti pé, nígbà míì, ó lè dà bíi pé à ń kú lọ, bíi pé à ń pàdánù ìgbésí ayé wa. Ìbẹ̀rù lè máa bà ẹ́, ó tiẹ̀ lè dùn ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.


Yàtọ̀ sí ìtàn ẹni tó là á já nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ rì, ìpinnu wa láti jáwọ́ nínú rẹ̀ ká sì fọkàn tán an kì í ṣe ìpinnu kan ṣoṣo. Kódà lẹ́yìn tá a bá ti pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Jésù tá a sì tẹ̀ lé e, a ṣì máa ń rọ̀ mọ́ àwọn nǹkan kan nínú ìgbésí ayé wa àtijọ́. A óò rí i pé à ń pa dà sí àwọn ibi tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n ti ń pèsè ààbò àti ìjẹ́pàtàkì. Àti pé ní gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti pinnu láti tún pa dà sídìí ìgbésí ayé tí Jésù ń fún wa.


Tó o bá tún ní irú ìṣòro yìí, rántí ìlérí tí Jésù ṣe nínú ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí. Ó jẹ́ nípa fífi ìgbésí ayé wa sọnù, nípa fífi ìgbésí ayé wa sílẹ̀, la fi ń rí i, ní ọ̀nà tó jinlẹ̀ jù lọ àti ní ọ̀nà tó kún rẹ́rẹ́ jù lọ.


oro

Jésù ń ké sí wa pé ká gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa kúrò nínú àwọn ohun àtijọ́ tá a mọ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tá a rọ̀ mọ́ fún ìrètí àti ààbò, ká sì gbé e ka ohun kan tó sàn ju ìyẹn lọ: ìyẹn Jésù fúnra rẹ̀. Àwọn nǹkan wo ló ṣòro jù fún ẹ láti fi sílẹ̀ kó o sì fọkàn tán an? Máa fi àkókò díẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn, kó o sì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kó o mọ àwọn ibi tó o ṣì ń sapá láti gbẹ́kẹ̀ lé e nínú ọkàn rẹ àti nínú ìgbésí ayé rẹ.


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org