Ìjọba DéÀpẹrẹ
ÀDÚRÀ:
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé o gbà mí láàyè láti pè ọ́ ní Bàbá l'Ọ̀run. O ṣeun nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ mi o sì fẹ́ kí n súnmọ́ ọ.
È̩KỌ́ KÍKÀ:
Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù bèèrè pé kí ó kọ́ àwọn bí a ti ń gbàdúrà. ó fún wọn ní àpẹẹrẹ yìí. A lè lo àdúrà yí gẹ́gẹ́ bí atọ́nà fún ìgbésí ayé àdúrà tiwa náà. Ọ̀kan nínú àwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wa nípasẹ̀ àdúrà yí wà nínú ọ̀rọ̀ méjì àkọ́kọ́: "Bàbá Wa.”
Nípa pípè é ní "Bàbá", Jésù ń ṣe àfinhàn irú ìbáṣepọ̀ tí a lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Eléyìí jẹ́ ohun tó ṣàjèjì sí àwọn Júù ọrúndún kìíní t'ó ń tẹ̀lé e. K'ò wọ́pọ̀ kí ènìyàn tọ Ọlọ́run alágbára lọ pẹ̀lú èdè tí à ńlò fún àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ wa tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Bóyá eléyì ganan ni àfojúsùn Jésù.
Tí a bá ronú pé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀gá wa t'ó wà lọ́run tàbí àpẹẹrẹ ẹni t'ó wà lọ́run, tàbí ọ̀rẹ́ wa t'ó wà lọ́run, ọ̀nà ọ̀tọ̀ gedegbe ni ìgbé ayé àdúrà wa yó gbà lọ. Àwọn àpọ́nle yìí a máa mú ìrètí àti ìdáraró wá sínú ìbáṣepọ̀ náà.
F'ojú inú wo òṣìṣẹ́ kan t'ó wọ inú ọọ́fìsì ọ̀gá rẹ̀ lọ láti lọ bèèrè fún ohun kan. Ìbáṣepọ̀ yí yó wà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìtẹríba. Báyìí, wá f'ojú inú wo ọmọ bíbí ọ̀gá yì ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún márùnún t'ó ń wọlé bọ̀ láti bèèrè súùtì. Bí yó ṣe bá a sọ̀rọ̀ yó yàtọ̀, ó tilẹ̀ lè fò lé e lẹ́sẹ̀ bí ó ti ń bèèrè ohun tí ó fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà. Kí ló jẹ́ kí ìṣesí ti ẹnìkan yàtọ̀ sí ti ẹnìkejì? Ìbáṣepọ̀ ló yàtọ̀. Irú ìbáṣepọ̀ tí o bá ní ni yó sọ bí oó ṣe wọlé àti bí yó ṣe gbà ọ́ mọ́ra sí.
Ìdí nìyí tí ọ̀rọ̀ Jésù fi jẹ́ ìjìnlẹ̀. Nígbà t'ó ní k'á gbàdúrà pé "Bàbá Wa," ó ń sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé nípa irú ìbáṣepọ̀ tí a lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Nípasẹ̀ Jésù, a ti gbà wá bí ọmọ sínú ẹbí Ọlọ́run, a sì leè fi ìgboyà wọlé bí a ti ń pè wá sínú ìbáṣepọ̀ tí a le ṣ'àpèjúwe pé ó jẹ́ tímọ́tímọ́.
(Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ànfààní láti dàgbà pẹ̀lú bàbá tó ní ìfẹ́ tó sì fi àìní àtí ìmọ̀lára wọn síwájú ohun gbogbo. Fún àwọ́n mìíràn, ó nira láti má fi ojú irú ìrírí tí wọn ní pẹ̀lú ẹni tí ó jẹ́ "bàbá" fún wọn wo ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. A lè nílò láti fi àsìkò tó pọ̀ sílẹ̀ kí ọgbẹ́ yìí san ná kí o tó pe Ọlọ́run ní orúkọ yìí. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ọgbẹ́ yìí mú ọkàn rẹ kúrò nínú nnkan pàtó tí Jésù ń sọ nípa lílo "Bàbá" - wípé o lè tọ Ọlọ́run lọ pẹ̀lú ìgbóyà nínú ìbáṣepọ̀ tí ó fààyè gba àkóyawọ́ àti sísúnmọ́ ẹni tímọ́tímọ́. Ìdiwọ̀n àti ọgbẹ́ ti àwọn bàbá ti ayé kò dá Ọlọ́run dúró. Ó fẹ́ràn rẹ gẹ́gẹ́ bí Bàbá tí ó pé.)
ÀṢÀRÒ:
Ìbáṣepọ̀ pẹlú Ọlọ́run jẹ́ èyí tó dálé rírí ààyè, ìbáramu, àti ìgbẹ́kẹ̀lé. Fi ìyẹ́n pamọ́ sí ọ̀wọ òsì rẹ. Nnkan aláìlẹ́gbẹ́ ni pé nípasẹ̀ Jésù ó ṣeéṣe láti ní irú ìbáṣepọ̀ yí pẹ̀lú Ọlọ́run!
Ya ìṣẹ́jú díẹ̀ sọ́tọ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Bí o ti ń kọ ọ́, bèèrè pé kí È̩mí Mímọ́ fi hàn ọ́ bí ó ti wu Ọlọ́run tó láti ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ rẹ̀.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí báwo ni ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe rí? N jẹ́ ibì kankan wà nínú ayé tàbí ọkàn rẹ tí o ti ń tẹ̀tì láti gbẹ́kẹ̀lé e? Báwo ni yoó ṣe rí láti súnmọ́ Bàbá pẹ̀lú ìgboyà kíkún pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ àti pé ó fẹ kí o súnmọ́ òun?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.
More