Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 15 nínú 15

ÀDÚRÀ:

Ọlọ́run, mo fẹ́ní ìgbàgbọ tí kò í'sẹ̀. Kọ́ mi kí n lè fi gbogbo ọkàn mi gbẹ́kẹ̀lé Ọ.


Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ:

Ó ṣeéṣe kí o mọ ibi tí ìtàn yí parí sí. Pétérù w'òkè ó rí atẹ́gùn àti ìjì ẹ̀rù sí bàa. Ó pàdánù ìfọkànsí rẹ̀ sí Jésù, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní rì sínú omi, Jésù sì wá láti gbà á là. Ìkùnà Pétérù nínú ìtàn yí ló ma ń sábà jẹ́ kókó fún wa, ṣùgbọ́n njẹ́ o fiyèsí ìgbàgbọ́ bàntàbanta nínú Jésù tí Pétérù mú lò láti gbé ẹsẹ̀ sórí ìjì omi yìí rárá? Ìgbàgbọ́ tó bùyààrì ni! Ìgbàgbọ́ tó tayọ tí ẹnikẹ́ni nínú ọkọ̀ ojú omi lọ́jọ́ náà. Ìgbàgbọ́ Pétérù nínú agbára Jésù jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ pé òun nìkan ni ọkùnrin tó tún rìn lórí omi. Ódára, òun nìkan ní ọkùnrin tí kìí sìí ṣe Ọlọ́run, pẹ̀lú. 


A ma ń sáábà bẹ̀rù àti kùnà tó bẹ́ẹ̀ tí a kìí fi gbé ìgbésẹ̀ ká sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti ṣe ohun àrà. Bíi áwọn ọmọ-ẹ̀hìn yókù nínú ọkọ̀, a ri ẹsẹ̀ wa mọ́lẹ̀ ṣinṣin nínú ọkọ̀ a ún wo ẹlòmíràn kí ó gb'ésè sórí ìgbì omi. Ó ṣeéṣe kí á ti ẹ̀ dun nú nígbàtí wọ́n bá kọ sẹ̀ a ó sì ma dá ara wa l'àre ìpinnu wa láti paramọ́ lọ́wọ́ ibi nípa dí dúró sójú kan. 


Bóyá a ti ẹ̀ ti ń ṣe báyìí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa a kò sì tíì ní ìjákulẹ̀ tí ó lè dojú tì wá ní ìgboro ní ọ̀nà kan kan rí, lọ́nà kannáà ẹ̀wẹ̀, a ò tíì ṣe àṣeyọrí kankan tó ní ìtumọ̀ gidi. Ó má ṣe o! Olùṣọ́-àgùntàn àti òǹkọ̀wé A.W. Tozer sọpé, “Ọlọ́run ń wá irúfẹ́ ènìyàn tí Yóò tipa wọn ṣe ohun tí a pè ní kòṣeéṣe. Ó ṣeni láàánú pé ìpalẹ̀mọ́ wa fún ohun tí a lè dá ṣe fúnra wa lásán ni.”


Báwo ni yóò ti rí tí àwa náà bá leè gba Ọlọ́run gbọ́ láì bìkítà ohun kan bíi Pétérù nígbàtí ó fò jáde kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi? Nítòótọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní rì, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ sínú ohun tó jọ pé kò ṣeéṣe. Nígbẹ̀yìn gbéyín, Jésù Kò wòran kí órí. 


Nínú ìkùnà paàpàá Pétérù àti Jésù jọ pín irúfẹ́ àkókò tí kò lè wáyé mọ́ láí. Tí o bá wá ní ànfàní láti bi Pétérù nípa àkókò yìí, ó ṣeéṣe kí o sọ fún ọ pé òun kò k'àbámọ̀ wípé òun gb'ésè kúrò nínú oko ojú omi.


ÀṢÀRÒ:

Ǹjẹ́ o leè ro bí yíò ti rí tí ó bá lè gbẹ́kẹ̀lé Jésù dé ibi tí o kò bìkítà ohun tí ó lè dé? Ṣé yíó bà ọ lẹ́rù àbí ó ńpa ọ l'áyọ, tàbí méjéèjì? 


Lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àyò, ibi ìrọ̀rùn fún ọ. Bóyá àga ìrọ̀gbọ̀kú tó dẹrùn pẹ̀lú aṣọ ìbora, tàbí ibìkan ní òde láàrin ìṣẹ̀dá dá. Kété tí o ti fi ara bale, bẹ̀rẹ̀ síí mí kanlẹ̀, ní pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́, kí o dúró jẹ́ níwájú Ọlọ́run. 


Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ún fà ọ sẹ́yìn láti jọ̀wọ́ ara rẹ fún bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ rìn nínú ayé rẹ? Fi àkọ́kọ́ dí ẹ̀ sílẹ̀ kí o sì bèèrè kí Ó fi hàn ọ ohun tí ó wà lọ́nà—nígbàná gbe kalẹ̀ níwájú Rẹ̀. Bẹ Ọlọ́run kí Ó ṣiṣẹ́ nínú ayé rẹ, bi Ó bá ti fẹ́, láti ràn ọ́ lówó kí o lè gbẹ́kẹ̀le laibikita ibi tó lè já sí. 




Láti ṣàwárí ẹ̀kọ́ míràn síi láti North Point Community Church, yàrá tẹ here .  

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org