Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 14 nínú 15

ÀDÚRÀ:

Ọlọ́run, O dá mi fún ìdí kan. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbé-ayé mi pẹ̀lú èrèdí yìí ní ọkàn mi. Ṣí mi lójú sí àwọn ọ̀nà tí màá fi fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn dáadáa tí màá sì fí tì wọ́n ṣ'ọ́dọ̀ Rẹ.




Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ:

Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ dá wa ni—fún ìdí kan. Bóyá o gbàgbọ́ tàbí o kò gbàgbọ́, Ó ti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ tí wà á gbà láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn tí wà á sì ṣe àjọpín ìfẹ́ yìí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Bóyá ó nkọ ọ́ l'óminú, Ó mọ ibi tí o tí ń ṣiṣẹ́!)


Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù ma ń gbé ìgbé-ayé kóńkó jabele, pàápàá jùlọ nínú iṣẹ́ àti ìrìn-àjò ìgbàgbọ́ wọn. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ jẹ ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run fẹ́ fi mú ìgbàgbọ́ rẹ dàgbà ńkọ́?


Ǹjẹ́ ọ mọ̀ pé ènìyàn kan lè lo bíi wákàtí 90,000—tó tó ìdá kan nínú mẹ́ta àkókò ìgbé-ayé àgbà wọn—l'ẹ́nu iṣẹ́? Bí ìgbàgbọ́ wa kò bá bá iṣẹ́ wa wí, a jẹ́ pé kò sí ohun tí a lè sọ nípa ohun tí a fi ọ̀pọ̀ nínú àkókò wa ṣe. Ọlọ́run bìkítà gidi nípa iṣẹ́ wa àti bí àwa gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́hìn Jésù ṣe ń ṣiṣẹ́ wa.


Àwọn ìjọ kò ṣe dáadáa nípa ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ làti ṣe àwárí ìtumọ̀ àti èrèdí iṣẹ́ wọn. Kódà, àwọn ìwáásù kan a máa jẹ́ kí ènìyàn l'érò pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí ènìyàn lè gbà sìn Ọlọ́run ní làti fi iṣẹ́ sílẹ̀ kí ó sì wáá ṣ'iṣẹ́ nínú ilé ìjọ̀sìn. Irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ l'èyìí.


Atúnjọṣe Martin Luther kọ̀wé pé, “Aṣebàtà tó jẹ́ Krìstíẹ̀ní kìí ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nípa fífi àgbélèbú kékèèké sí bàtà ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe bàtà tó jíire, nítorípé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ọnà gidi.”


Dorothy Sayers, ajàfẹ́tọ̀ọ́ àti òǹkọ̀wé, sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ó kọ pé, “Ohun tí ìjọ ma ńṣe fún gbẹ́nàgbẹ́nà tó dáńtọ́ ni kí wọn gbàá níyànjú kí ó má mu ọtí, kí ó má sì ṣe jàgídíjàgan l'ákókò afẹ́ rẹ̀, kí ó sì wá sí ilé ìjọsìn ní ọjọ́ ìsinmi. Àmọ́, ohun tó yẹ kí ìjọ ṣọ fún un ni pé: ohun àkọ́kọ́ tí ẹ̀sìn rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ni pé kí ó ṣe tàbìlì tó dára.”


Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo iṣẹ́ ni ó ń ṣe àlékún ire àwọn elòmíràn. Nípa báyìí, iṣẹ́ wa ni ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ńgbà fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ Rẹ̀ hàn sí ẹ̀dá Rẹ̀. Láti fi iṣẹ́ rẹ sin Ọlọ́run, o kò níílò làti fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ kí o sì lọ s'iṣẹ́ nínú ilé-ìjọsìn—o lè sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àfojúsùn tuntun. Bóyá o níílò làti wo iṣẹ́ rẹ̀ l'ọ́nà tí ó ńgbà mú ipa rere tó dàra jù bá àwọn elòmíràn. Bóyá o ní láti ṣe ìpinnu tuntun làti máa ṣe iṣẹ́ tí ó kún ojú òsùwọ̀n pẹ̀lú òtítọ́ inú. Tàbí o ní láti mọ̀ pé Ọlọ́run fi ọ́ sí ibi tì o wà fún ìdí kan àti pé "Ó ti pèsè iṣẹ́ rere fún ọ" làti ṣe ní ibí tí o tí ń lo 40 wákàtí l'ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.


ÀṢÀRÒ:

Àwọn ìbéèrè díẹ̀ nìyìí làti bèèrè bí o ti ń ṣe àṣàrò lórí bí ayé àti iṣè rẹ ṣe sopọ̀ m'ọ́ra wọn:

• Ọ̀nà wo ní iṣẹ́ rẹ ṣe ńsin ẹlòmíràn?

• Báwo ni yíó ṣe rí láti gbá'jú mọ́ sínsin ẹlòmíràn nípa iṣẹ́ rẹ?

• Báwo ni o ṣe lè ní ipa lórí àṣà ibi iṣẹ́ rẹ ní ọ̀nà tí ó dára síi?

Lo àsìkò díẹ̀ làti kọ àwọn ìdáhùn rẹ sílẹ̀. Wọ́n lè jọ ìbéèrè tó rọrùn lójú rẹ, ṣùgbọ́n má kàn sáré dáhùn wọn. Pe Ọlọ́run sínú ìjíròrò náà nípa gbígba àdúrà bí o ṣe ńkọ àwọn èrò rẹ sílẹ̀. Bèèrè pé kí Ẹ̀mímímọ́ mú ọ mọ̀ síi nípa ìwàláàyè Rẹ̀ àti kí o darí rẹ ní gbogbo àkókò iṣẹ́ rẹ. Gbìyànjú làti jẹ́ kí ó di àṣà ojoojúmọ́ làti bi Ọlọ́run pé, “Tani O fẹ́ kí n fi ìfẹ́ Rẹ hàn sí lónìí?” Lẹ́hìn náà gbáradì làti dáhùn sí ìtọ́ni Rẹ̀.


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 13Ọjọ́ 15

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org