Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 6 nínú 15

ÀDÚRÀ:

 Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ọ loni


Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ:

Nkan tí ó rọrùn ni láti ṣì àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kà nínú ìwé Gálátíà. Ní ìgbà gbogbo ni a máà si àtúnwí sọ gẹ́gẹ́ bí "àwọn èso" tí Ẹ̀mí. Ó ṣeé ṣe kí ó dàbí ẹni pé Pọ́ọ̀lù ń fún wa ní àtòsílẹ̀ oríṣiríṣi, àwọn ìwà tí kò jọ ara wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ kí ó jẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà ọmọlẹ́yìn Jésù. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kò sọ pé "àwọn èso", ó sọ pàtó pé "èso" bí ohun tó jẹ́ ẹyọ kàn. Nítorí náà kini ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yí?


Òní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ọgọrun méjìdínlógún sẹhin Jónátánì Ẹ́díwọ̀ọ̀dú kọ́ni nípa ìmọ̀ràn yí.“… Ó dàbí ẹni pé gbogbo àwọn oore-ọfẹ onígbàgbọ́ tó lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àsopọ̀ tí ó yàn rántí àti ifọkanbalẹ lórí ara wọn.”


"Títò lẹ́sẹẹsẹ" jẹ ona kan gbógì ni ìgbà àtijọ́ tí a fi ń sọ pé "gbogbo àwọn oore-ọfẹ Kristẹni ni ó ní àsopọ̀ dọin-dọin. Èyí túmọ̀ sí pé à kò lè ní ìdàgbàsókè ni ọna kan tàbí méjì kí a sì jọ̀wọ́ àwọn tó kú. Ti ó bá jẹ ìdàgbàsókè Ẹ̀mí tòótọ́, gbogbo àwọn ìwà ni yíò jẹ yọ papọ̀ nígbà kaná. 


Eléyi ṣe pàtàkì láti ni òye; bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ó rọrùn ká ṣe àkọsílẹ̀ tí ó yẹ láti ṣe lásán. - tàbí "èyí tí ó yẹ kí ó wáyé". A ni ìmọ̀lára tí ó lọ́rìnrìn láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìwà wọ̀nyí nípa agbára àti ìgbìyànju wá. Ó da lórí ìhùwàsí wá àti ẹni tí a jẹ, díẹ̀ nínú àwọn àbùdá yí lè wá ní ìrọ̀rùn. Ṣùgbọ́n àwọn míràn ni ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe - a sì lè ní ìdojúkọ láti ro wípé Ọlọ́run kò nifẹ si àyípadà àwọn ẹ̀yà ara wa kan.


Ṣùgbọ́n bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa èso, kì í ṣe àwọn èso, ìmúdára wá fún ìdàgbàsókè wá. Ó kò lè ní ayọ̀ láìsí ìfẹ́, àlàáfíà láìsí ìwà pẹ̀lẹ́, ìwà rere láìsí ìṣàkóso ara ẹni - ó kéré jù kìí ṣe ni ọna ti yíò pẹ́ nípa oore-ọfẹ tí Ọlọ́run fẹ́ nínú ayé rẹ. Gbogbo wọn ni ó sopọ̀ tí wọ́n sì ń dàgbà sókè lẹgbẹ ara wọn. Nwọn kí ì ṣe àwọn èso ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀yà èso kan náà, èso tí ó ń dàgbà sókè nípa agbára Ọlọ́run nígbà tí a bá ní asopọ̀ pẹ̀lú rẹ.


Nítorí náà, má ṣe ní ìrẹ̀wẹ̀sì nípa àkópọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí-kìí se àtòpọ̀ àkọsílẹ̀ ohun tí ó ní láti parí. Ọlọ̀run kan fi díẹ̀ hàn ọ nínú iṣẹ tí ó pinnu láti ṣe ni ìgbé ayé rẹ ni 


ÌJÍRÒRÒ

Èso Ẹ̀mí yí ń dàgbà nípa bí ó ṣe sopọ̀ mọ orísun, ìyẹn àjàrà fúnra rẹ, tí ìṣe Jésù. Bí ó ti ṣe ya àwòrán ọ̀rọ̀ yi ni ọkàn rẹ̀, kini àyè tí ọkàn rẹ wà lọ́wọ́ lọ́wọ́? Ṣé ó gbẹ hauhau ni tàbí ó l'ómi dáadáa? Ṣé ó rọrùn láti pilẹ̀sẹ̀ tàbí ó nira? Ǹjẹ́ irúgbìn míràn wá nibẹ tí kò gbà Jésù láyè nínú ayé rẹ?


Gbà Ọlọ́run láyè láti jọba ní ọkàn rẹ ni ọna ọ̀tun kí ó jẹ ki o fi hàn ọ bí ó ṣe yẹ láti dúró ṣinṣin kí ó sì fi ìdí múlẹ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org