Rúútù, Ìtàn ÌràpadàÀpẹrẹ

Ruth, A Story Of Redemption

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ìparíi ti Ọlọ́run

Orí kẹrin ṣí sí Bóásì ní ẹnubodè, ní àárín ìlú náà. Ó wà ńíhìn-ín nítorí pé ó fẹ́ fẹ́ Rúùtù, ó sì ń wá olùràpadà àwọn ìbátan rẹ̀. Arákùnrin tí ó súnmọ Rútù àti Nàómì jẹ ọkùnrin tí a kò mọ, síbẹsíbẹ a le kọ ẹkọ díẹ nípa ìwà rẹ nìkan nípasẹ àyè kúkurú yìí.

A mọ̀ pé ó di dandan fún ọkùnrin yìí láti tọ́jú àwọn obìnrin méjèèjì náà, ṣùgbọ́n kò tíì gòkè wá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Bóásì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá òun yóò fẹ́ ra Rúùtù padà, ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí jẹ́ ọkùnrin kan tí kò ní ìwà títọ́ àti ìwà, pàápàá ní ìfiwéra pẹ̀lú Bóásì.

Bóásì bá ìbátan náà ṣe àdéhùn lábẹ́ òfin láti ní ẹ̀tọ́ ìràpadà fún Rúùtù kí ó lè fẹ́ ẹ. Kò ní ojúṣe rẹ̀ lábẹ́ òfin láti ṣe ohunkóhun fún Rúùtù, ṣùgbọ́n kò ṣe ohunkóhun ju bíbójútó Rúùtù nínú u gbogbo ìwé náà. Bóásì ti nawọ oore-ọfẹ gẹgẹ bi Jésù ti nawọ oore-ọfẹ si wa.

Oore-ofe Ọlọ́run tó fún wa. A ti rà wá padà láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, àwọn àjèjì tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí nǹkan kan bí kò ṣe pé wọ́n ti fún wa ní ẹ̀tọ́ ajogún. Báyìí bí Jésù ti ra ìyàwó rẹ (ljo), Bóásì ra ìyàwó re (Rúùtù). Ó fẹ́ ẹ, ó sì lóyún.

Ó dùn mọ́ni pé, Rúùtù ò tíì lóyún nínú ìgbéyàwó re ti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. A lè rò pé ó yàgàn ní àkókò yìí, bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọ́run ti ṣí ile omo rẹ̀ ní àkókò yìí láti bímọ. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ó bí ọmọkùnrin kékeré kan tó ń jẹ́ Óbédì, tó jẹ́ bàbá bàbá Dáfídì Ọba ńlá.

Mo fẹ láti ya àwòrán kan diẹ sii ti oore-ọfẹ Ọlọrun ati ọba-alaṣẹ nípasẹ ibí ọmọ yìí. Rúùtù jẹ́ ará Móábù; àlejò tí kò ní ẹ̀tọ́. Sibẹsibẹ, nipasẹ ore-ọfẹ àti ìràpadà ó di apákan ti ìtàn-àkọọlẹ ti Krístì. Ìtàn yí jé ìyàlénu!

Kò rọrùn fún Rúùtù. Ó dàgbà ní orílẹ-èdè búburú. Ó jìyà ikú ọkọ rẹ. Ó tẹ̀ lé Náómì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ó sì ń gbé nínú òṣì. Gbogbo àwọn ipò tí ó nira púpọ ló là kojá.

Bibẹẹkọ, gẹgẹ bí mo ti tọka sí ní ibẹrẹ járá yìí, a le ríi àwọn ìka ọwọ Ọlọrun ní gbogbo itan Rúùtù àti pé kò si iyèméjì pé Oun wà ní iṣẹ ní gbogbo àkókò náà. Ó jẹ ìrìn-àjò gígùn tí ó ní ìṣòro, ṣùgbọn ó parí pèlú ìràpadà. Rúùtù bẹ̀rẹ̀ l'òfo, àmọ́ ó parí ní kíkún!

Ohunkóhun tí àkókò rẹ lè jẹ, rántí pé Ọlọrun wa ni iṣẹ ni igbesi aye rẹ. Ó ń hun tapestry ẹlẹ́wà; ko tii pari, ṣugbọn o wa ni ilọsiwaju. Mọ pe Ọlọ́run jẹ olóore-ọfẹ, Ó dára, àti pé Ó nifẹ rẹ. Tí o bá rẹwẹsi ní ìrìn-àjò yìí, tún wo ìgbésí-ayé Rúùtù kí o sì rántí pé Ọlọ́run nṣiṣẹ fún ire àwọn ènìyàn Rẹ.

Ìwé mímọ́

Day 4

Nípa Ìpèsè yìí

Ruth, A Story Of Redemption

Àwọn díẹ̀ ni a lè fi taratara f'ojú jọ nípa ìlàkọjá wọn nínú Bíbélì bíi Rúùtù; tálákà, òpó àtọ̀húnrìnwá tí o fi Ọlọ́run ṣíwájú tí o wá ń wò bí Ó ṣe yí ayé òun padà. Bí o bá ń wá kóríyá nínú àyídáyidà rẹ, má sa láì ka ẹ̀kọ́ yìí!

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: brittanyrust.com

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ