Rúútù, Ìtàn ÌràpadàÀpẹrẹ
Jìnnà S'ílé
Ǹjẹ́ o ti wòye rẹ̀ rí bóyá Ọlọ́run tilẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú ayé rẹ? Mo ti wòó bẹ́ẹ̀ ní àìmọye ìgbà, àmọ́ṣá, a tún rán mi l'étí ìwé Rúùtù. A kò rí ìyanu tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ àtọ̀runwá; a rí Ọlọ́run l'ójú iṣẹ́ bí Ó ṣe ń rọra tọ́ àwọn obìnrin méjèèjì l'ójú ọ̀nà ìmúpadàbọ̀sípò àti ìbísí.
Ìwé Rúùtù bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtàn ìdílé kan tí wọn ńgbé ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n ńgbé ní ìlú kan tí à mọ̀ sí ilé oúnjẹ, síbẹ̀ ìyàn wà. Òǹkọ̀wé náà kò sọ ohun púpọ̀ fún wa nípa ìgbésí-ayé ìdílé náà; a kàn bẹ̀rẹ̀ l'ójú ọgàn pẹ̀lú wọn l'ọ́nà ìrìn-àjò wọn sí ilẹ̀ Móábù. Láti 'lẹ̀ ìlú Móábù jẹ́ ìlú ìwà búburú gbogbo. Síbẹ̀, Élímélékì pinnu láti sí àwọn ìdílé rẹ̀ nídìí kúrò ní ìlú oúnjẹ lári rìn ìrìn-àjò lọ sí ìlú àjèjì tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
A kò rìn jìnnà nínú orí kìńní kí a tó rí àfijọ rẹ̀ tó ṣe kókó nínú ayé wa. Nígbàtí a bà ń d'ojúkọ ìṣòro, a kò gbọdọ̀ sinmi lé òye ènìyàn tàbí kí á wá ọ̀nà àbáyọ kánmọ́nkíá; a gbọ́dọ̀ wá Ọlọ́run fún ìfẹ́ Rẹ̀. Élímélékì kò bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kíni ìfẹ̀ Rẹ̀ jẹ́, bẹ́ẹ̀ni kò gbékèlé Ọlọ́run. Dípòo bẹ́ẹ̀, ó sí ìdílé rẹ̀ nídìí kúrò níbití àwọn ènìyàn Ọlọ́run ńgbé láti lọ gbé ní ìlú búburú níbití kò níí sí ibi tí wọn yíó ti sin Ọlọ́run tí kò sì sí ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míràn.
Kàyéfì ibẹ̀ ni pé, Élímélékì kúrò láti sálà lọ́wọ́ ikú, síbẹ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin yíó ṣ'alábàpàdé ikú gan-an k'ọ́dún mẹ́wàá tóó pé. Kìí ṣe pé ìgbésẹ̀ èèṣi yìí padà buú lọ́wọ́ nìkan, ṣùgbón ó kóbá gbogbo ìdìlé rẹ̀ pẹ̀lú. Ó ní láti yé wa pé àwọn ohun tí a bá yàn láti ṣe l'áyé, àbọ̀wábá rẹ̀ yíó ta bá àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.
Ọgba tí Élímélékì kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kò ní agbára láti ṣe ìyàtọ̀ láàrin ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Ó gba àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láàyè láti fẹ́ àwọn obínrin Móábù tí kò mọ Ọlọ́run kí wọ́n sì fi àìdọ́gba dàpọ̀ ní ìgbeyàwó. Pẹ̀lú ìpinnu kan tí kò tọ́, Élímélékì darí ìdílé rẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú ohun tíí ṣe ti Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì kí ìwọ àti èmi wá ìfẹ́ Ọlọ́run dípò kí a ṣe ohun tí a rò pé ó yẹ jù. Ìgbésẹ̀ òdì kan lè mú kí a gbé àìmọye ìgbèsẹ̀ òdì ní ṣísẹ̀ǹtẹ̀lé.
Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ń múni padà bọ̀ sípò àti pé Ọlọ́run dára. A kò rí ìdílé tí a parun látàrí ìgbésẹ̀ òdì kan. Ọlọ́run kò ì tíì parí iṣẹ́.
Bíi ènìyàn Ọlọ́run a ní àǹfààní tó yàtọ̀ láti mọ ìfẹ́ Rẹ̀ àti láti gbé lábẹ́ ààbò Rẹ̀. Àwọn àkókò wà lááye wa tí ìjì á dé. Ní irú àwọn àkókò wọ̀nyí a lè wá ìfẹ́ Rẹ̀ kí a sì gbékèle, nídà kejì a lè sinmi lé òye ara wa kí a sì gbé ìgbésẹ tí a rò pé o dára jù. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ètò Ọlọ́run fún wa dára ju tiwa lọ.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn díẹ̀ ni a lè fi taratara f'ojú jọ nípa ìlàkọjá wọn nínú Bíbélì bíi Rúùtù; tálákà, òpó àtọ̀húnrìnwá tí o fi Ọlọ́run ṣíwájú tí o wá ń wò bí Ó ṣe yí ayé òun padà. Bí o bá ń wá kóríyá nínú àyídáyidà rẹ, má sa láì ka ẹ̀kọ́ yìí!
More
A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: brittanyrust.com