Rúútù, Ìtàn ÌràpadàÀpẹrẹ
Pípadà sí Ibi Ìpèsè
Ó jẹ́ nnkan ìwúrí pé Ọlọ́run wà fún wa, Ó wà pẹ̀lú wa, Ó sì ní ìfẹ́ wa. Bí ó ti lè wù kí nnkan burú tó tàbí kí ayé d'omi tútù sí wa lọ́kàn tó, òtítọ́ tí kò lè yí padà ni pé kò sí ohun t'ó le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ìtàn t'ó lè sọ eléyì dára tó ìtàn Nàómì àti Rútù kò tó nnkàn. Lónì, a rí wọn bí opó; ọmọbìnrin méjì tí wọn ń ṣ'ọ̀fọ̀ àwọn ọkọ tí wọ́n n'ífẹ̀ sí, àwọn nìkan ní orílẹ̀ èdè t'ó kún fún ìwà búburú. Àmọ́, nnkan ti fẹ́ yí padà fún wọn. L'ọ́jọ́ kan Nàómì gbọ́ pé ojú rere Ọlọ́run ti padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti pé oúnjẹ tún ti sùn wọ́n bọ̀ ní "ilé oúnjẹ." Ní ẹyẹ ò sọkà, Nàómì pinnu láti padà sí ilẹ̀ ìbí rẹ̀ àti sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ́rpà àti Rútù pinnu láti tẹ̀le Nàómì lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò nígbà tí ó dàbí pé Nàómì yí èrò rẹ̀ padà nípa àwọn tí wọ́n jọ ń lọ. Pẹ̀lú rírọ̀ Nàómì, Ọ́rpà padà sí Móábù. Ìpinnu ti Rútù yàtọ̀. Rútù pinnu láti tẹ̀lé Ọlọ́run, a sì rí ìyípadà ọkàn tòótọ́ lójú ọ̀nà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
Àwọn obìnrin méjèèjì tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjo wọn tí wọ́n fí dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí wọ́n dé'bẹ̀, Bíbélì sọ pé gbogbo ìlú mì tìtì. Ó dàbí pé gbajúmọ̀ ni Náómì àti ẹbí rẹ̀ níbẹ̀. Dídé Nàómì ya àwọn obìnrin ìlú náà lẹ́nu, dé'bi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé bóyá àwọn ń lá àlá tàbí àwọn ń ṣiwèrè ni.
Nígbà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ kàn án lójú, Nàómì bẹ àwọn obìnrin ìlú náà pé kí wọ́n má pè òun ní Nàómì (adùn) mọ́, ṣùgbọ́n kí wọ́n máa pe òun ní Márà (kíkorò). Njẹ́ ìgbà kan wà tí ìwọ pẹ̀lú dàbi Nàómì, ẹni tí ó kún tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ti wá ṣófo báyìí? Ní irú àwọn àsìkò tí a bá gba nnkan tó ṣe pàtàkì kúrò lọ́wọ́ wa, ara a máa kan wá, inú a sì máa bí wa. Kò sí ohun t'ó ṣe àjèjì nínú k'á bínú; a kàn níláti ríi pé ìbínú wa kò di ìkorò ọkàn ni.
Mo ní láti sọ pé nínú ìtàn yìí, mo fẹ́ràn ìṣesí Nàómì. Nígbà t'ó padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kò díbọ́n; ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí bí òun ṣe rí lótìítọ́. Mo gbàdúrà pé kí gbogbo wa léè ṣe olótìtọ́ pẹ̀lú àwọn t'ó yí wa ká nínú ìlàkàkà wa, kí á sì lè sọ̀rọ̀ síta nígbà tí ọkàn wa bá rẹ̀wẹ̀sì. Wíwà ní àárín àwùjọ àwọn ònígbàgbọ́ ní irú àsìkò t'ó nira báyì jẹ́ ọ̀nà t'ó ṣe kókó fún ìmúláradá.
Rútù àti Nàómì padà sí ilé oúnjẹ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà báálì. Ṣé kòńgẹ́ wa leléyìí? N kò rò bẹ́ẹ̀. Ipa tí a kò lè fojú rí kan ń rìn, àwọn obìnrin méjéèjì yìí kò ní pẹ́ rí nnkan ńlá àti iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run máa ṣe, ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì lè fojú rí ní àsìkò yìí.
Ìmọ̀ràn mi fún ọ lónì ni pé kí o gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. Gbà pé èètò Rẹ̀ ń tẹ̀síwájú àti pé ojú Rẹ̀ wà lára rẹ. Kò gbàgbé rẹ, kò sì sí ohun kankan t'ó lè mú kí Ó má fẹ́ràn rẹ mọ́. T'ó bá dàbí pé ò ń dá ja ìjàkadì ayé tàbí ó dàbí pé kò sí ẹni tí o lè f'ọ̀rọ̀ lọ̀, má tẹ̀tì láti ké gbàjarè sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run t'ó wà ní sàkáání rẹ.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn díẹ̀ ni a lè fi taratara f'ojú jọ nípa ìlàkọjá wọn nínú Bíbélì bíi Rúùtù; tálákà, òpó àtọ̀húnrìnwá tí o fi Ọlọ́run ṣíwájú tí o wá ń wò bí Ó ṣe yí ayé òun padà. Bí o bá ń wá kóríyá nínú àyídáyidà rẹ, má sa láì ka ẹ̀kọ́ yìí!
More
A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: brittanyrust.com