Rúútù, Ìtàn ÌràpadàÀpẹrẹ
Níbi Ilẹ̀ Ìpakà
Rúùtù àti Bóásì jẹ́ irú ènìyàn tí à ń bá pàdé lojojúmọ́ ṣùgbọ́n tí a polongo ní ti ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Rúùtù láì sí iyèméjì jẹ́ Obìnrin onígbàgbọ́. Ó ní ìyípadà tòótọ́ ní ojú ọ̀nà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó si ń tẹsíwájú lọ sí ìlú tuntun náà. Ó gbàgbọ́ pe Ọlọ́run leè pèsè fún òun àti Náómì bí ó n ṣe ń jade lati sá lẹ̀. Ó gbàgbọ́ ó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìpọ́njú.
Tí o un kan bá wà tí ó dáni lójú òun ni pé bí ó ti wù kí ìgbà wa nira tó, a gbọ́dọ̀ gba Ọlọ́run gbọ́ kí á sì gbẹ́kẹ̀le pé Yíò pèsè. Bí ó ti wù kí àwọn àkókò kan nira tó, a nílò láti gba ìgbàgbọ́ wa láyè láti nàyẹ dé ibi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìgbàgbọ́ wa kò ní dàgbà tó láti rí àṣekún oun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe láyé wa.
Rúùtù jẹ́ Obìnrin oníwà-rere, bákan náà ni okùnrin tí ó sùn sí ní ẹsẹ̀. Bóásì àti Rúùtù bá ara wọn mu ní ọ̀nà yí. Àwọn ènìyàn iyì méjì tí a dàpọ̀ nípasẹ̀ dídára àti ìbùkún Ọlọ́run. Mo gbàgbọ́ pé ìtàn yí tún ní ọ̀pọ̀lọpọ nǹkan láti yẹ̀ wò.
Bí Rúùtù ti rìn nínú àánú, ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀, ó gbà ikansarasi láti ọ̀dọ̀ arákùnrin tí ó fẹ́ràn rẹ̀. Bóásì kíyèsi ìjáfáfá àti ìwà réré ó sì bu ọlá nípa dídáhùn àdúrà òun tìkara rẹ̀ ní orí 2 fún ún. Ṣùgbọ́n ju èyí lọ, Ọlọ́run kíyèsi ìjáfáfá àti ìwà réré rẹ̀.
Mo ti gbọ́ gbólóhùn tó sọ pé, "ìṣe ẹni ní oun tí a jẹ́ nígbà tí ẹnikẹ́ni ò rí wa." Rúùtù ò fi ìgbà kankan lérò pé ayé òun yóò di oun tí a tan ná sí fi hàn tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ ń tọ́ka síi bíi àwòkọ́ṣe. Gbà á ní èrò oun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe láti ipasẹ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ tó ni. Ní irú àkókò báyìí tí a rò pé kò sí ẹni tí ó ń wò wá tabi pé kò sí èrè fún oun tí a ṣe, Ọlọ́run Ún rí igbiyanju yẹn.
Ìwọ àti èmi ì bá jẹ́ ènìyàn tí a lè pè ní okùnrin àti obìnrin oní ìwà réré bíi ti Rúùtù àti Bóásì. Ṣiṣẹ́ nínú ìgbàgbọ́ nígbàtí ìrètí ti fẹ́ ẹ̀ bọ́ tán. Fèsì ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ sí àǹfààní tí a fi lọ ẹ. Ẹ na ọwọ́ àánú sí àwọn tó yíi yín ká. O lè má ní àǹfààní láti mọ iye àwọn tí ayé rẹ n bá pàdé.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn díẹ̀ ni a lè fi taratara f'ojú jọ nípa ìlàkọjá wọn nínú Bíbélì bíi Rúùtù; tálákà, òpó àtọ̀húnrìnwá tí o fi Ọlọ́run ṣíwájú tí o wá ń wò bí Ó ṣe yí ayé òun padà. Bí o bá ń wá kóríyá nínú àyídáyidà rẹ, má sa láì ka ẹ̀kọ́ yìí!
More
A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: brittanyrust.com