Àyànfẹ́ Ni Ọ́Àpẹrẹ
A pè wá Láti Fẹ́ràn Ọlọ́run Àti Àwọn Ẹlòmíràn Pẹ̀lú.
Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. (Róòmù 12:9)
Jésù sọ ní ṣókí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òfin Májẹ̀mú lailai pẹ̀lú àṣẹ ńlá láti fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti èkejì sì dàbí rẹ́ láti fẹ́ràn ọmọnìkejì wá gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Mátíù 22:37-40). “Ọmọnìkejì ” nínú apá kan ẹ̀kọ́ yí kò pin si àwọn ènìyàn tí ó ń bá ọ pín ohun-ìní. Ọmọnìkejì rẹ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdé tàbí tí ó ní ànfàní láti nípa nínú ayé rẹ̀. Ohun tí ó rọrùn fún wa ni làti fẹ́ràn ara wa. A máà ń gbaradi láti fí ojú fò àṣìṣe wá kí a sì dojú kọ ohun rere tí a ṣe. Ohun tí ó nira fún wa jú ni làti fẹ́ràn ẹlòmíràn.
Tí ó bá jẹ pé ní òdodo ni a ní òye ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìròyìn dáradára tí ìhìn rere, àwa yíò fí ọkàn sí láti jẹ alábàápín ìfẹ́ yẹn pẹ̀lú gbogbo ènìyàn tí ó bá wà ní ipá wá láti ṣe. Ibi kíkà tí òní kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣẹ tí ó pèsè àwọn àpẹẹrẹ bí a ṣe lè fí ìfẹ́ hàn, bí a ṣe ní ìdáríjìni, àti fi óòre-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn mìíràn. Èwo nínú àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni Ọlọ́run lè ló fún ọ gẹ́gẹ́ bí ìpèníjà láti ló nínú ìbásepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn loni?
Kí a tó bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe àwáwí, ẹ má ṣe jẹ ki a gbàgbé pé Jésù ń tọ ọna ikú lọ, pàápàá ikú orí igi àgbélébùú, láti nifẹ wá. Ká má ṣe gbàgbé wípé Ọlọ́run pé Kristẹni kọ̀ọ̀kán láti fi ara wa rú ẹbọ ààyè (Róòmù 12:1)! Ó lè má rọrùn fún wa láti fẹ́ràn àwọn mìíràn, ṣùgbọ́n ó jẹ déédéé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún wá. Bẹ̀rẹ̀ láti máà gbàdúrà fún àwọn mìíràn, àti pé Ọlọ́run yíò sọ ìbínú rẹ̀ di ẹ̀rọ, yíò sì jẹ ki o borí àwọn àwáwí rẹ̀, yíò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ fún ọ láti fi ìfẹ́ hàn àti láti jẹ alábápín ìfẹ́ Kristi.
Bí ó ṣe ń gbàdúrà, béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ìfẹ́ wá láti rán ọ lọ́wọ́ láti nifẹ àwọn mìíràn.
A nírètí pé ètò yí gba wa níyànjú sí. Fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣàrò ẹ̀kọ́ Bíbélì sí láti ọwọ onígègé bí Duane Loynes, ṣe àwárí àwọn orísun Bíbélì mìíràn láti Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń fún ní nírètí .
Idagbasoke Bọtini : ọjọ_4Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.
More