Àyànfẹ́ Ni Ọ́Àpẹrẹ

You Are Loved

Ọjọ́ 3 nínú 4

Ìfẹ́ Tó Rọrùn

Kí ìfẹ́ ará kí ó wà títí (Hébérù 13:1) 

Pẹ̀lú ọmọ méjì ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀, gbogbo ìgbà ni mo máa ń bu'wọ́ lu ètò fún iṣẹ́ àmúrelé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti lè mọ bí ǹkan ti ń lọ ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ àti gbígba àkọsílẹ̀ gbogbo iṣẹ́ àmúrelé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe tàbí èyí tí wọn kò ṣe. Àwọn ìwé èsì máa ń kànmí lára nílé nípa bí àwọn ọmọ mi ti ńṣe nínú ẹ̀kọ́ wọn. Àti wípé a máa ńṣe àfikún máàkì wọn tí kò bá wù ni lórí.

Nígbà míràn ìhà kan náà tí a kọ sí gbígba máàkì akẹ́kọ̀ọ́ ni a kọ sí títẹ̀lé Jésù. A ó ma wà ní ìyanu nígbà mìíràn bóyá a pójú òṣùwọ̀n fún máàkì dídára tí a rí gbà. Tí mo bá ti fi oúnjẹ ṣọwọ́ sí àwọn aláìní l'óṣù yí, ǹjẹ́ ó tún nílò fún mi láti f'ara ṣiṣẹ́ nílé ìdáná gbogbogbò? Mo mọ̀ wípé ó tọ́ fún mi láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ẹniti ó ń sọ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn nípa mi ńkọ́? Ní ṣeni a dà bíi Pétérù tí ń béèrè lọ́wọ́ Jésù wípé, “Olúwa, tí ọmọ ìjọ mìíràn bá ṣẹ̀ sí mi, ẹ̀melòó ni kí n dárí jì í?” (Mátíù 18:21 ).

Enití ó kọ ìwé Hébérù rán wa létí láti ṣe ohun gbogbo ní ìrọ́wọ́-rọsẹ̀. Má ṣe ìyọnu nípa gbígba ẹ̀san—ìwọ ṣáà ti ní ìfẹ́! Ó ṣeé ṣe fún wa láti lépa máàkì kan nítorí ó fi ibi tí a dé dúró hàn sí wa. Àmọ́ ní ti Ọlọ́run, kìíṣe nípa máàkì, bíkòṣe nípa àyè tí ọkàn wa gbé wà. Ọlọ́run fẹ́ kí a fẹ́ràn láì fi ìjánu síi, nítorí a ti fẹ́ràn àwa pẹ̀lú (Jòhánù Kínní 4:19). Dípò bíbèrè bóyá o ti pójú òṣùwọ̀n, bèrè lọ́wọ́ ara rẹ ibi tí Ọlọ́run ti ń fún ọ ní àǹfààní láti fi ìfẹ́ hàn sí ẹlòmíràn: rántí àwọn tó wà ní ìtìmọ́lé, pèsè fún aláìní, ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èyí tí o ní—àmọ́ látinú ìtọ́ni kan ṣoṣo ni gbogbo rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá: ìfẹ́. 

Bí o ti ń gbàdúrà, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìfẹ́ tó rọrùn tó ní sí ọ. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

You Are Loved

Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Words of Hope fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.woh.org/youversion