Àyànfẹ́ Ni Ọ́Àpẹrẹ
Sùúrù Ìfẹ́ Ọlọ́run
Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. (Hosia 2:14)
Nígbà tí mo wà ní kíláàsì kejì ti ilé ìwé alákọ̀ọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ọmọkùnrin kan ní kíláàsì mi búra pé òun yó sé èémí títí tí ọmọbìnrin tí òun fẹ́ràn yóò fi sọ pé òun náà fẹ́ràn òun. Bí gbogbo wa ṣe ń fi ìbẹ̀rùbojo wo ojú rẹ̀ bí ó ṣe ń dánranjẹ̀ lọ, ọmọbìnrin náà sáré pariwo pé, "Ó dára! Mo fẹ́ràn rẹ!" Láì ṣe àníàní, "ìbádọ́rẹ̀" ọ̀hún k'ò t'ọ́jọ́.
Níbi kíkà t'ó dùn yí nínú ìwé Hosia, a kà á pé nígbà tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bá pinnu láti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run míràn, Ọlọ́run kò sọ ìrètí nù lórí wọn. Dípò tí yó fi kàn án nípá fún wọn láti ní ìfẹ́ Òun, níṣe ni Ọlọ́run máa ń fà wọ́n mọ́ra, á sì sọ̀rọ̀ tútù sí wọn, láti fún wọn ní ìrètí níbi tí wọ́n bá ti sọ ìrètí nú. Nípasẹ̀ èyí, Ọlọ́run kéde pé, ọjọ́ kan ń bọ̀ tí wọn yó pè é ní "ọkọ mi" (ẹsẹ 16). Ìlérí Krístì nìyí. Nípa ikú àti àjínde Krístì, a ti fa aṣọ-ìkele t'ó wà láàrin àwa àti Ọlọ́run ya. A ti dárí jì wá pátápátá, gbogbo àìbìkítà wa àtijọ́ sì ti lọ sí òkun ìgbàgbé. Ọlọ́run ti ṣílẹ̀kùn ìrètí sílẹ̀ gbayawu. A ti rí i pé kìí ṣe ọ̀gá t'ó ń bèèrè fún ìfẹ́, ṣùgbọn Ọlọ́run onísùúrù tí ó ń wá ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú wa. Ìbáṣepọ̀ tí a kò kàn nípá fún wa, ṣùgbọ́n èyí t'ó wù wá nítorí pé ó ti fi bí ìfẹ rẹ̀ fún wa ti jinlẹ̀ tó nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù Krístì.
Lónìí, da ìfẹ́ onísùúrù ti Ọlọ́run rò. Ko ní bèèrè pé kí o ní ìfẹ́ òun, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà ni ó ń pè ọ́, ó sì ti ṣí apá rẹ̀ sílẹ̀ ó ṣetán láti gbà ó mọ́ra.
Bí o ti ń gbàdúrà, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa olódodo fún ìfẹ́ rẹ̀. Bèèrè pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ sí ọmọnìkejì bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ sí ọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.
More