Àlàáfíà tó SonùÀpẹrẹ

Missing Peace

Ọjọ́ 5 nínú 7

Àlàáfíà Pẹ̀lú Ọlọ́run 

A ti sọ̀rọ̀ nípa rí rántí àwọn ìlérí Ọlọ́run àti ìhùwàsí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kíni ti ìgbà tí ó bá dàbí pé a kò ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run? Bóyá o ti lẹ̀ ní inú dídùn sí Ọlọ́run mọ́ nítorí ó dàbíi pé Ó ti já ọ kulẹ̀ ní kòpẹ́kòpẹ́. Tàbí bóyá o kàn rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ó nira fún ọ láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run Onìfẹ́ lè Jẹ́kí ìnira tó pọ̀ tó èyí wà ní ayé. 

Èyí ni oun tí o nílò láti mọ̀: Ọlọ́run ní ara láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀lára rẹ. 

Yíò fẹ́ràn kí o sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Òun ju kí o rìn kọjá kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀. Ní dájúdájú, Ọlọ́run wá ọ tọkàntọkàn tó bẹ́ẹ̀ tí Ó rán Ọmọ Rẹ̀ wá sáyé láti la ọ̀nà sí àlàáfíà fún ọ. 

Láì sí Jésù, ati yà wá nípa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀. Àti pẹ̀lú, bí Ó ti jẹ́ Baba Onìfẹ́, Ń fẹ́ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú wa. Fun idi eyi, Ó ṣe ọ̀nà àbáyọ: 

Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá. Aisaya 53:5 YCB 

Jésù dá àlàáfíà padà sínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí túmọ̀sí pé ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún wa ní ọfẹ́ láti ipasẹ̀ Jésù sí ọ̀dọ̀ Bàbá wa tí Ó fẹ́ wa, t'Ódáríjì wá, bẹni Ó ún Ṣe ìtọ́jú wa. Kò burú láti bínú sí I nígbàtí nǹkan kò bá lọ bí o ṣe fẹ́—ṣá ma jẹ́ kí ìrora oun tí ò un là kọjá da kùrukùru bo dídára ìṣe Rẹ̀. 

Oníwàásù Amy Groeschel sọ báyìí pé: “A nílò láti sọ fún ìnira ta ń là kọjá òye ohun tí a mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́.” 

Àwọn ìmọ̀lára rẹ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n má ṣe fún wọn ní Ìṣẹ́gun lóríì rẹ. Ní dájúdájú, Orin-Dáfídì 46:10 kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣítí tí ó lágbára: 

Ó sọpé, “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè A ó gbé mi ga ní ayé.” Orin-Dáfídì 46:10 YCB

Ó kọ́ wa kí á dúró jẹ́ kí ásìmọ̀ pé Òun ni Ọlọ́run. Kòsọpé, “Dúró jẹ́kí o sì rò” pé Òun ni Ọlọ́run. Àwọn ìmọ̀lára wá ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n wọn kò gbilẹ̀ nínú òtítọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run, ìdí ìgbàgbọ́ wa, Ó jẹ́ Ẹni ìdúróṣinṣin àti Òtítọ́, torí kí á bàa lè lo ìgbàgbọ́ láti fi yẹ ìmọ̀lára wa wò.

Kò túmọ̀sí pé a kò le béèrè àlàyé ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ìwé Orin-Dáfídì kún fún igbe Dáfídì àti àwọn míràn sí Ọlọ́run, wọ́n ń bẹ̀ Ẹ kí Ó yí ìlàkọjá wọn, wọ́n sì ń wòye bóyá Ó tilè ń gbọ́. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn á padà sí orí òtítọ́—pé Ọlọ́runyìídára. Óètò dára dára fún wa. Ìṣàkóso wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Bákannáà Òun sì yẹ fún ìsìn àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa

Tí ó bá rí fún ọ bii pé o kò ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run lónìí, bá àwọn ìmọ̀lára yìí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí o sì rántí ìhìn rere yìí: Jésù ni ipa ọ̀nà wa sí àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ṣe iṣẹ́ náà fún wa. Ó sì ti san asán parí ìdíyelé àlàáfíà.

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Missing Peace

N jẹ́ ó ṣeéṣẹ nítòótọ́ láti ní ìrírí àlàáfíà nígbàtí ayé kún fún ìnira? Ìdáhùn kúkúrú ni: Bẹ́ẹni, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa. Nínú ọdún tó ti sọ wá di bíi ẹni tí a lù bolẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la kún fún ìbéèrè. Nínú Ètò Ẹ̀kọ́ Bíbélì olójọ́ méje yìí, tí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwàásù Oníwàásù Craig Groeschel, a ó ṣàwárí bí a ti leè rí àlàáfíà tó sọnù tí gbogbo wa ń pọ̀ùngbẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/