Àlàáfíà tó SonùÀpẹrẹ

Missing Peace

Ọjọ́ 3 nínú 7

p> Ìbàlẹ̀ ọkàn

Tí ó bá ronú padà sí àkókò kàn tí ó ní ìdojúkọ tí ó ní agbára ní ìgbésí ayé rẹ. Bóyá ó ní ìpèníjà àìbálẹ̀ ọkàn tàbí ìbànújẹ́. Bóyá ó pàdánù olólùfẹ́ rẹ kán. Bóyá ó ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú àdánù àlá rẹ tàbí ohun tí ó rò pé ọjọ ọlá rẹ yíò tí rí. Kíni díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó wúlò julọ tí àwọn ènìyàn ṣe fún ọ?

Ó lè má rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹnikan sọ. Ṣùgbọ́n ó rántí ẹniti ó ṣe alátìlehìn rẹ. Ó ṣe ìrántí àwọn tí ó fetí balẹ láti gbọ̀ ẹ yé, àwọn tí ó wá ọ wá, àti àwọn tí ó fí àsìkò silẹ láti dúró ọ.

Nígbàtí a bá ní ìdojúkọ àwọn ìgbìyànju wá tí ó jinlẹ̀ julọ, á lè ní ìgbẹkẹ̀lé nínú òdodo pé Ọlọ́run wà wá pẹ̀lú wa nígbà gbogbo. Ní òtítọ́, nínú ìwé Aísáyà á pé Jésù ni Immanuẹ̀li tí ó túmọ̀ sí "Ọlọ́run wá pẹ̀lú wa"

Nígbàtí a bá ń gbìyànjú láti wá àlàáfíà ní àwọn ipò tí a wà, nígbà míràn ohun tí ó dára jù lọ tí a lè ṣe ní wípé kí á gbà pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa àti ẹ̀bùn tí Ó fún wà láti wá ní iwájú Rẹ̀

Àti pé ìròhìn rere náà ni pé a kò nílò láti ṣe eleyi nípa agbára wa. Ní ìwọ̀n ìgbà tí a bá ti tẹle Jésù, Ó fún wà ní ẹ̀bùn míràn- tí í ṣe Èmi Mímọ́. Á kò níláti ló agbára tàbí ìgboyà láti ọwọ ara wa làti ní àlàáfíà. Dípò bẹ́ẹ̀, á lè béèrè lọwọ Èmi Mímọ́ fún ìtọ́sọ́nà ìgbésí ayé wa, láti ṣọ́ ọkàn wa, kí ó sì ṣe àgbéjáde èso tí ó gbéwọ̀n ju ìbànújẹ́ wá lọ

.

Bí Pọ́ọ̀lù ṣe rán wá létí:

Àwọn tí ìṣẹ̀dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ gàba lé lórí ń ronú nípa ohun ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ńṣe adarí ń ronú nípa ohun tí ó tẹ Ẹ̀mí lọrun. Nítorí náà gbígba ìṣẹ̀dá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láyè láti ṣe adarí rẹ yíò yọrí sí ikú. Ṣùgbọ́n gbígbà Ẹ̀mí láyè láti darí ọkàn wa yíò yọrí sí ìyè àti àlàáfíàRomu 8:5-6 NLT

Nígbàtí oríṣiríṣi èrò bá gbá ọkàn wá kan nípa ìròhìn, àríyànjiyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára pẹ̀lú àwọn ìjàmbá tí ó fà lẹsẹ, ẹ̀rù àti ìrẹ̀wẹ̀sì kò ní ṣe aláì wá sí ọkàn wa. Àti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a ní láti ní àrídájú pé ohun tí a gbà láyè láti kún ọkàn wà ní ohun tí ó lè jí iná ẹ̀mí wá dìde

Ní òtítọ́, ọ̀nà kan láti wá àlàáfíà Ọlọ́run ní láti máà rántí àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wa kí á sì dojú kọ àwọn ìlérí wọ̀nyí ju àwọn òkè ìṣòro wá lọ

Ó ṣe ọ ní kàyéfì bí ó ṣe lè bẹ̀rẹ̀? Ká Orin Dáfídì 23 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kí ó sì rán ara rẹ létí pé Ọlọ́run wàpẹlu rẹ nígbà tí ó bá ńlá òkè ìṣòro kọjá, tí ó bá ń lọ láàrin àfonífojì, tàbí ó nílò ìtura. Ṣé àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí ó jẹ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ: Ọlọ́run sún mọ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn. Ó ń pèsè àlàáfíà tí ó tayọ òye lọ. Òun sì ní ààbò ní àkókò tí wàhálà bá dé. Òun sì ní Olùdámọ̀ràn ìyanu. Ọlọ̀run Alágbára wá. Ọmọ Aládé àlàáfíà wa!

Loni, tí ó bá ní ìmọ̀lára àìbálẹ̀ ọkàn tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì, mọ eleyi pé: Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ̀. Ó rí ọ. Ó fẹ́ràn rẹ. Ó wá pẹ̀lú rẹ. Ó wà fún ọ. Ó lè lépa àlàáfíà nípa sísọ àwọn ìlérí Ọlọ́run sí orí àwọn òkè ìṣòro rẹ àti kí ó jọ̀wọ́ àwọn èrò rẹ fún Ẹ̀mí Mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Missing Peace

N jẹ́ ó ṣeéṣẹ nítòótọ́ láti ní ìrírí àlàáfíà nígbàtí ayé kún fún ìnira? Ìdáhùn kúkúrú ni: Bẹ́ẹni, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa. Nínú ọdún tó ti sọ wá di bíi ẹni tí a lù bolẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la kún fún ìbéèrè. Nínú Ètò Ẹ̀kọ́ Bíbélì olójọ́ méje yìí, tí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwàásù Oníwàásù Craig Groeschel, a ó ṣàwárí bí a ti leè rí àlàáfíà tó sọnù tí gbogbo wa ń pọ̀ùngbẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/