Àlàáfíà tó SonùÀpẹrẹ

Missing Peace

Ọjọ́ 2 nínú 7

Àlàáfíà Nínú Ìbáṣepọ̀ 

Àìdànílojú máa ń fẹ́ẹ́ fẹ aáwọ̀ àti àìgbọ́ra-ẹni-yé lójú. Ní ọdún t'ó bá jẹ́ pé jẹ́ pé "àìròtẹ́lẹ̀" ni ọ̀rọ̀ tó rọrùn jù láti sàpèjúwe èrò olúkálukú, ó túmọ̀ sí pé gbogbo wá ti d'ojú kọ àwọ́n aáwọ̀ kan tàbí òmíràn. 

Bóyá àríyànjiyàn lóríi òṣèlú tó bẹ̀rẹ̀ nídì oúnjẹ ọdún ni, ìtahùnsíni tó dálé ọ̀rọ̀ tó jẹyọ lórí ẹ̀rọ alátagbà tó ká ni lára ni, tàbí ọ̀rọ̀ líle nípa ààlà, ìgbà míràn àwọn tí a nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ ni wọ́n máa ń gbé wa lẹ́mìí gbóná jù. 

Ṣùgbọ́n wíwà lálààfíà ṣeé ṣe nínú àwọn ìbáṣepọ̀ wa. Ní pàtó, gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́hìn Jésù, a pè wá láti mú àlàáfíà wá sínú ayé. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè rẹ̀, Jésù wí pé: 

Alábùkúnfún ni àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n. Matiu 5:9 BM

Kíyèsíi pé "tí ó ń mú kí alaafia wà" ló sọ - kìí ṣe "tó ń pa àlàáfíà mọ́". Mímú kí àlàáfíà wà jẹ́ ìgbésẹ̀ tí kò lópin. Kò túmọ̀ sí pé kí á f'ọwọ́ sí gbogbo àbá tàbi èrò tí ẹnikẹ́ni bá mú wá. Kò sì tún túmọ̀ sí pé kí á gba gbogbo èrò wọlé lórúkọ àlààfíà. Kí á má máa ṣe àtúpalẹ̀ èrò kí á tóó gbà á wọlé nítorí kí àlààfíà lè wà lè tàn wá jẹ pé àlààfíà wà, ṣùgbọ́n irọ́ ni.. 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọrùn láti má jà aáwọ̀ kúnra tàbí k'a ṣe bí ẹni pé kò sí aáwọ̀, síṣe báyìí kìí ṣe ìlànà ìfẹ́. Romu 12:9 rán wa létí pé ìfẹ́ ní látiṣòdodo. Tí a bá fi ẹ̀dùn ọkàn wa pamọ́, a ò ṣánnà àlààfíà - dípò bẹ́ẹ̀ à ń yààgò kúrò lọ́nà tí àlààfíà yóo fi wà ni. 

Àmọ́, nínú Romú 12 Pọ́ọ̀lù ń pè wá níjà pé kí á f'ojú sùnnùkùn wo bí àlààfíà ṣe rí nítòótọ́, kò rọrùn. Lẹ́hìn t'ó ti gbà wá níyànjú láti bùkún àwọn tí ó ṣẹ̀ wá, kí á yẹra fún gbígbẹ̀san, kí á sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, ló pè wá níjà pé: 

Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀nba bí ó bá ti wà níkàwọ́ọ́ rẹ, máa gbé ní àlààfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Romu 12:18 BM

Ṣàkíyèsí pé ó ní, “níwọ̀nba bí ó bá ti wà níkàwọ́ọ́rẹ.” Èyí túmọ̀ sí pé a kò ní kí wa ní sàdánkátà nítorí ìhùwàsi wèrè àbúrò bàbá wa. Bí ó ti lè wù kí nnkan tó yí wa ká rí rúdurùdu tó, Ọlọ́run ṣì fẹ́ kí á sánnà àlàáfíà, yálà nípa kíko ẹnìkan lójú ni tàbí kí a yẹra kúrò tí a bá ríi pé yíyẹra ni yó mú àlàáfíà wá lásìkò yí.

Báwo lo wá ṣe lè jẹ́ ẹnìkan tó ń mú àlàáfíà wá ní gbogbo ìgbà? A rí ọgbọ́n díẹ̀ kọ́ síi láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù: 

Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá,a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji,kì í ṣe àgàbàgebè. Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia. Jakobu 3:17-18 BM

A lè fi jíjẹ́ ẹni tó ń mú àlàáfíà wá wé bíbèèrè ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí á wá ń dán ọgbọ́n yí wò nípa ṣíṣe àkíyèsí bóyá ó kún fún àlàáfíà ni tàbí òye tiwa. Ó túmọ̀ sí pé bí ó tilẹ̀ dára kí á sọ èrò wa àti ohun tó ń kọ wá lóminú síta, a níláti fi èrò ti àwọn ènìyàn míràn ṣíwájú tiwa. 

Ó túmọ̀ sí pé kí á jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí á sì kún fún ìwà rere nígbà tí a bá ń sọ àwọn ìwòye wa síta. Ó túmọ̀ sí pé kí á máa ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí a fi ń sọ̀rọ̀ kí á lè rí dájú pé à ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú èróńgbà láti mú àtúnṣe wá. A lè sọ pé ó dàbí pé kí á máa bèèrè bóyá ibi-àfẹ́dé wa ni kí á máa wá ọ̀nà òdodo tàbí pé kí á tọ̀nà. 

Nítorí náà, nígbà tí o bá bá ara rẹ ní ipò tí o ti nílò àlàáfíà nínú ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, dúró díẹ̀. Má ro èrò tí kò dára nípa ẹnìkejì. Sọ nnkan tí ò ń rò tàbí tí ó ń lọ lọ́kàn rẹ jáde. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Jẹ́ aláànú. Gbàdúrà nípa rẹ̀. Bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé kínni ìgbésẹ̀ t'ó kàn tóo lè gbé láti mú àlàáfìá wá sí ipò tí o wà yẹn. 

Nígbà tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń jẹ́ ẹni tí ó ń mú àlàáfíà wá - o sì ń jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Missing Peace

N jẹ́ ó ṣeéṣẹ nítòótọ́ láti ní ìrírí àlàáfíà nígbàtí ayé kún fún ìnira? Ìdáhùn kúkúrú ni: Bẹ́ẹni, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa. Nínú ọdún tó ti sọ wá di bíi ẹni tí a lù bolẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la kún fún ìbéèrè. Nínú Ètò Ẹ̀kọ́ Bíbélì olójọ́ méje yìí, tí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwàásù Oníwàásù Craig Groeschel, a ó ṣàwárí bí a ti leè rí àlàáfíà tó sọnù tí gbogbo wa ń pọ̀ùngbẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/