Àlàáfíà tó SonùÀpẹrẹ
Àlàáfíà tó Sonù
Ọdún 2020 yíò wọnú àkọsílẹ̀ ìtàn gẹ́gẹ́ bíi ọdún kan tí kò lórúkọ rere ní ìgbésí ayé ènìyàn. Láti orí àjàkálẹ̀ àrùn tó kárí ayé lọ sórí ìgbòrò àfihàn ìfẹ̀tọ́dunni nítorí ẹ̀yà títí dórí àìbalẹ̀ ọkàn nídìí ìṣèlú òun ìyapa, ó ti jẹ́ àkókò ìpèníjà gidi. Ọ̀pọ̀ wa ló dàbí ìgbà tí àlàáfíà wa ti sọnù, tàbí bí ẹni pé wọ́n jíi lọ.
Ṣùgbọ́n tó bá ṣe pé kìí ṣe ìlàkọjá wa ló jí àlàáfíà wa—tó bá ṣe pé wọ́n kàn fihàn pé a kò ní àlàáfíà rárá tẹ́lẹ̀?
Nígbàtí àkókò bá nira fún àdojúkọ, anì ọ̀nà tí a máa ń gbà ṣe àpọ́nlé oun tó ti kọjá, ní ìrònú pé tí àwọn ìrírí wa bá yàtọ̀ ni inú wa yóò dùn a ó sì rí àlàáfíà.
Síbẹ̀, lọ́dọọdún, ó dà bí ẹni pé a ṣì ń wá àlàáfíà. Nítorínáà, nígbàtí à ń sọ bí àkókò yí ti nira tó, a ò lè dá àkókò náà lẹ́bi fún gbogbo ìṣòro tí ó dojú kọ wá. Bákannáà ní a ò lè sọpé Ọlọ́run kò ṣe ohun kan, pàápàá nínú gbogbo rògbòdìyàn náà.
Fún ìdíèyí, kíni àlàáfíà? Báwo ni a ṣe fẹ́ ríi nígbàtí a wà ní ìyapa tí a ń ṣe àníyàn tí ọjọ́ iwájú kò sì dá wa lójú?
Ìròhìn ayọ̀ ni pé ní ní àlàáfíà kìí ṣe nígbàtí kò bá sí ìṣòro nìkan. À ń rí àlàáfíà níbití Jésù bá gbé wà.
Éfésù 2:14 rán wa létí pé Jésù wá gẹ́gẹ́ bí àlàáfíà wa. Kìí ṣe látikànfún wa ní àlàáfíà bíkòṣe nótòótó láti jẹ́ àlàáfíàwa. Ní kókó, ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún àlàáfíà nieirene, tó tún túmọ̀sí odindi. Jésù Ò wá kí á bàa lè wà dáadáa fún ọjọ́ dí ẹ̀. Ó wá láti ràwápadà—àti àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run—sí odindi.
A so àlàáfíà wa mọ́ ibití Ọlọ́run tí kìí yí padà bá wà. Ọkàn náà ni lánàá, lónìí, àti láíláí. Ẹni tó dúró ṣinṣin ni. Ó dára. Ó sì yẹ ní Ẹni tí à ń gbẹ́kẹ̀le.
A ò ní rí àlàáfíà nínú ipò wa tó ń yípadà tàbí nípa ṣíṣe àwárí rẹ̀ fún ra wa. Jésù ni àlàáfíà wa tó sọnù, nígbàtí a kò bá sì tẹjú mọ ìṣòro wa mọ́ ṣùgbọ́n tí a tẹjú mọ Jésù, a ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ma ìrírí àlàáfíà tó dáàbò bò ọkàn wa tí ó sì ju gbogbo òye lọ. Kàn wo ìrántí yìí láti inú Ìwé Mímọ́:
Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà. Isaiah 26:3-4 BYO
Àlàáfíà pípé jọ oun tí ó jìnnà sí òtítọ́, àbí? Ṣùgbọ́n a leè ríi tí darí gbogbo èrò ọkàn wa sí Jésù tí a sì gbẹ́kẹ̀le lè E pátápátá.
Fún ìdí èyí, àlàáfíà lè dàbíi pé ó ti sọ nù tàbí pé ọ̀nà rẹ jìn. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni pé Ènìyàn ní àlàáfíà, tí a bá sì gbẹ́kẹ̀le E tí èrò ọkàn wa sì dúró lé Ẹni tí Ó jẹ́, a ó ṣe alábapàdé Rẹ̀. Kò túmọ̀sí pé gbogbo ìgbà ni a ní inú dídùn tàbí pé a kò ní ṣe àìní ìrírí ìpayà tàbí ẹ̀rù. Ó túmọ̀sí pé a mọ bí á tiṣe rí àlàáfíà nígbàtí à ń dura, torípé àlàáfíà jẹ́ oun tí ó ń ti òdò Olórun wá.
Nípa Ìpèsè yìí
N jẹ́ ó ṣeéṣẹ nítòótọ́ láti ní ìrírí àlàáfíà nígbàtí ayé kún fún ìnira? Ìdáhùn kúkúrú ni: Bẹ́ẹni, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa. Nínú ọdún tó ti sọ wá di bíi ẹni tí a lù bolẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la kún fún ìbéèrè. Nínú Ètò Ẹ̀kọ́ Bíbélì olójọ́ méje yìí, tí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwàásù Oníwàásù Craig Groeschel, a ó ṣàwárí bí a ti leè rí àlàáfíà tó sọnù tí gbogbo wa ń pọ̀ùngbẹ.
More