Ọdún tuntun, Ọlọ́run Kan NáàÀpẹrẹ
Ẹgbẹ́ tí ó dára jù
Ilé ayé tí ó jẹ́ òtítọ́ dà bíi ilé-ìwé: Gbogbo ènìyàn fẹ́ láti dara pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́gbón jù lọ, àti wípé ní ojoojúmọ́ a tún gbọ́dọ̀ wá àwọn ènìyàn tí ó le ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ṣe àṣeyọrí.
Ní àkókò ètò ẹ̀kọ́ yìí mo ti fún ọ ní àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí o le gbé láti bẹ̀rẹ̀ ọdún ìbùkún, ṣùgbọ́n mọ ti fi èyí tí ó dára jù lọ fún ìkẹyìn.
Ìgbésí ayé má ń dára jù lọ ní ìgbà tí a bá ní àwọn ẹgbẹ́ tí ó dára; àwọn ẹrù máa fúyẹ́ àti pé ojú ọ̀nà kò ní fi bẹ́ẹ̀ le. Ìdí nìyí tí ó fi dára fún wa láti wà nínú ẹgbẹ́ kan: O kò nílò láti nìkan dojú kọ àgbáyé.
Mo fẹ́ kí o ronú ṣí kí ẹnìkan tí mo mọ̀ wà ní ìgbésí ayé rẹ. Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ó dúró ṣinṣin àti pé yóò dá ààbò bò ọ́. OHUN GBOGBO, àní ohun gbogbo, máa yọrí sí rere pẹ̀lú Rẹ̀ ní ègbé rẹ. Ní ìgbà gbogbo ni Ó borí, kò sí ogun tí mo ti rí pé Ó pàdánù. Ó ní àánú púpọ̀, ní ìgbà tí o bá ṣe àìní tàbí nílò ǹkan kan, o le gbà á láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Òun kì yóò jẹ́ kí o rẹ̀wẹ̀sì, Òun yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ọ nínú àwọn iṣẹ́ àkànṣe rẹ. Òun yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àwọn àkókò tí ó níra jù lọ àti pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ sí iwájú. Ènìyàn òtítọ́ ni, Òun yóò sọ fún ọ ní ìgbà tí o bá yí padà kúrò ní ọ̀nà rẹ̀, yóò sì gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn láti tún wà ní ọ̀nà rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan si. Apá kan tí ó dára jù lọ ní pé mo ti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti pé Ó fẹ́ láti jẹ́ ara ẹgbẹ́ rẹ.
Jésù ni orúkọ Rẹ̀; ṣé o mọ̀-Ọ́n?
Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún titun yìí, ní àkọ́kọ́ bèèrè fún ìbùkún àti ìtẹ́wọgbà Ọlọ́run. Dara pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ lónìí. Jẹ́ kí a dẹ́kun àwọn ọ̀pọ̀ ìjà wa sí Ọlọ́run, gbà Á láàyè láti wá sí ọ̀nà rẹ kí o gbẹ́kẹ̀ lé pé ibi tí Òun yóò mú ọ lọ kíi ṣe ibi tí o fẹ́, ṣùgbọ́n ibi tí o nílò láti lọ.
Láti rìn pẹ̀lú Ọlọ́run túmọ̀ sí láti rìn ní àìséwu, nítorí pé Òun ni olùdarí wa.
Ọdún yìí tí ó kún fún ìbùkún àti oríṣiríṣi ìrírí ń dúró dè wá; Ara mi balẹ̀ nítorí pé mọ wà nínú ẹgbẹ̀ olùborí. Àwọn ìṣòro yóò wá; kìí ṣe ohun gbogbo ni yóò lọ létòlétò ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run fi agbára àti ìtọ́jú Rẹ̀ hàn wá.
Rántí: Má ṣe fí ohun kankan sí inú àpótí rẹ nípa gbígbé oun tí kò dára sí ẹ̀yìn. Ṣe ètò àwọn àfojúsùn tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ní ọdún tí ó ní ìtumò. Wo ara rẹ bí Ọlọ́run ti rí ọ; o le ṣe ohun gbogbo. Àti ní ìkẹyìn, fi ayé rẹ (ọdún) sí ọwọ́ Ọlọ́run.
Ọlọ́run + ìwọ = Ìṣẹ́gun tí ó dájú.
Títí di ìgbà míràn!
Pẹ̀lú ìfẹ́, Leslie Ramírez.
Nípa Ìpèsè yìí
Ọdún tuntun ti dé, ó sì wá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn tuntun àti àwọn ìpinnu tí a fẹ́ láti ṣàṣeyọrí. Ohun gbogbo ti yípadà ní àgbáyé; síbẹ̀síbẹ̀, a ní Olódùmarè Ọlọ́run kannáà tí ó lè fún wa ní ọdún tí ó ní Ìbùkún. Darapọ̀ mọ́ mi ní àwọn ọjọ́ mẹ́rin wọ̀nyí tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pẹ̀lú ìdí kàn tàbí òmíràn ní pàtó.
More