Ọdún tuntun, Ọlọ́run Kan NáàÀpẹrẹ

New Year, Same God

Ọjọ́ 2 nínú 4

Láti ni Àṣeyọrí Àfojúsùn

Eh!, ọdún tuntun dé nígbẹ̀yìngbẹ́yín! Ìmọ̀lára igbiyanju mi fún mi ní ìṣírí láti ṣe é

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀nà tí oníkálukú máa ń gbà bẹ̀rẹ̀ ọdún yàtọ̀ sí ara wọn, nítorí náà mo béèrè lọ́wọ́ àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi nípa bó ṣe máa ń rí lára wọn nígbà tí ọdún tuntun bá dé, àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe àti bóyá nǹkan kan wà tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. Wọ̀nyí ni díẹ̀ lára ohun tí wọ́n fí fèsì

- "Ká sòótọ́, èmi kò kì í fi ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe àfojúsùn mi torí mo mọ̀ pé mi ò ní lè ṣe gbogbo rẹ̀, ṣùgbọ́n inú mi dùn pé mo rí iparí ọdún kan yí pé mo ⁿ wà láàyè."

- “Nígbà míràn inú mi máa ń dùn, ìgbà míràn sì wà tí èmi kì í fi bẹ́ẹ̀ kà á sí, gbogbo rẹ̀ ló dá lórí bí ọdún náà ṣe parí. Mo ní àwọn àfojúsùn, mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú nǹkan bíi méje. "

- "Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúró de ọdún tuntun nípa fì fí ọkàn yííri bí ó ṣe yẹ kó rí, mo sì máà ṣe ọ̀rínkiniwín ohun tí mo fẹ́ àti ìmọ̀lára mi ni àkókò yẹn."

- "Nígbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ ọdún mo máa ń rí i pé ojúṣe mi ni láti ṣe gbogbo ohun tí mo ní lọ́kàn láti ṣe kí n sì fi àwọn àṣà tó máa ràn mí lọ́wọ́ lélẹ̀ láti ni ìlọsíwájú sí i."

- “Èmi kò ro pe mo já fafa fún eleyi. Ọdún tuntun ti dé tán, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀."

Ṣé ìwọ náà fi ara mọ ìkankan nínú irú èsì bayi? Ọ̀kọ́ọ̀kan nínú wọn ńi nǹkan tí ó bá ara wọn mú: Ó kéré tán,wọ́n ní àfojúsùn kan náà. Ohun yòówù kó jẹ́ ìhà tí ó kọ sí ìbẹ̀rẹ̀ tuntun yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ náà ní àwọn àfojúsùn láti mú kí ọdún yìí jẹ́ ọdún tó ní ìtumọ̀. Àwọn àfojúsùn máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé nǹkan ka orí nǹkan kan, ó máa ń jẹ́ ká ní ìkóra-ẹni-níjàánu, ó sì máa ń jẹ́ ká ní ojúṣe dáradára bí a ti ń tẹ́ síwájú. Àwọn nǹkan wo lo fẹ́ gbé ṣe? Ní àwọn àfojúsùn tí o mọ̀ pé o lè mú ṣẹ, ṣùgbọ́n tó lè fún ọ ní ìpèníjà bákan náà

Níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì wà láàyè, a óò máa ní àǹfààní láti yí padà ká sì máa tẹ síwájú, nítorí náà, máa lo àǹfààní yẹn. Ìgbà kan wà tí ọ̀rẹ́ mi kan sọ fún mi pé òun kò ní àfojúsùn kankan, pé òun á jẹ́ kí gbogbo nǹkan máa lọ bó ṣe wù ú. Ǹjẹ́ o rò pé ọdún yí lè ní ìtumọ̀ sí? Làti jẹ́ kí eleyi ṣe èṣe jẹ ohun ti o ṣọ̀wọ̀n díẹ̀. Àwọn nǹkan kì í kàn ṣàdédé wáyé, àwa la máa ń mú kí wọ́n wáyé.

Ọlọ́run kò mú ọ wá sí ayé láti wá gbé ìgbé ayé tí kò ní ìtumọ̀. Ó fẹ́ kí a máa dàgbà sì, kí a ní ìlọsíwájú, kí a sì ṣe àṣeyọrí nínú ohun tí a nifẹ si. Ètò tí Ó ní fún ọ ye Òun dáradára. Àwọn àfojúsùn wa nínú ayé lè yí pa dà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò yí pa dà, ó máa ń fún wa lókun nígbà gbogbo, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohunkóhun tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀

Iṣẹ́ àkànṣe: Ṣe àtòjọ ohun mẹ́wàá tí o fẹ́ ṣe lọ́dún yìí sílẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ohun tó rọrùn jù lọ títí dé órí àwọn tí ó gba pé kó ṣiṣẹ́ kárakára. Ṣé ìdánimọ̀ àwọn àṣà tó yẹ kó ní láti ṣe àṣeyọrí nínú wọn.

Leslie Ramírez

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

New Year, Same God

Ọdún tuntun ti dé, ó sì wá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn tuntun àti àwọn ìpinnu tí a fẹ́ láti ṣàṣeyọrí. Ohun gbogbo ti yípadà ní àgbáyé; síbẹ̀síbẹ̀, a ní Olódùmarè Ọlọ́run kannáà tí ó lè fún wa ní ọdún tí ó ní Ìbùkún. Darapọ̀ mọ́ mi ní àwọn ọjọ́ mẹ́rin wọ̀nyí tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pẹ̀lú ìdí kàn tàbí òmíràn ní pàtó.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Leslie Ramírez Lázaro tíó pèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://aboutleslierl.web.app/