Ọdún tuntun, Ọlọ́run Kan NáàÀpẹrẹ
![New Year, Same God](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F22987%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ní ìgbàgbọ́ nínú ara rẹ
Ó rọrùn fún wa láti ríi ohun dídára nínu ohun gbogbo àti gbogbo ènìyàn pẹ̀lú. À ń lo ìgbésí ayé wa láti ṣe àpọ́nlé àti láti yìn àwọn míràn tí ó ní ẹ̀bùn abínibí àti bí wọ́n ṣe ri, èyí sì jẹ ohun ti o jọ́ni lójú. Ṣùgbón nígbàtí ó bá jẹ́ ti ara wa, ó dàbí ẹnipé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Bóyá o fẹ́ tàbí okọ̀, ìwọ yóò lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ pẹ̀lú ara rẹ, nítorí nàà máṣe fi ojú fo bí ó ṣe jọjú to!
Ọlọ́run dá olúkúlukú wa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn abínibí àti agbára orísirísi, Ó dá wa ní àwòrán àti ìrínisí ara Rẹ̀, Ó sì ni èrò tí ó ga fún wa. Ó ríí gbogbo ohun tí o ní agbára láti ṣe, àti wípé nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ó ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránnilétí bí ó ti se pàtàkì àti níyelórí tó, nítorí Ó mọ̀ pé o lè gbàgbé rẹ ní ìkóríta kan.
Gbígbàgbọ́ nínú ara rẹ àti mímọ rírì bí Ó ṣe dá ọ ṣe kókó. Àwọn nǹkan mélo ni ìwọ kò ti gbìyànjú láti gbé ṣe tí ìwọ yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ máà rò pé o kò ni ohun àmúyẹ? Nígbà mííran a le pàdánù àwọn ànfàní ńlá nípa àíní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wa. Mo ní írètí pé gbogbo wa lè bẹ̀rẹ̀ ọdún tí ó ní ìbùkún, láì ṣe iyèméjì. Èyí jẹ ọdún tí ìgbẹ́kẹ̀lé, kìì ṣe ti ìbẹ̀rù. Èléyi ni ọdún láti gba àwọn ìpèníjà láyè nítorí pé "ohun gbogbo tí o fẹ́ ni ó jẹ́ òdìkejì ẹ̀rù." (Jack Canfield).
Àwọn ìtani-lólòbó kúkúrú mẹ́rin tí ó le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara ẹni pọ̀ sí ní ìwọ̀nyí:
1. Ní èrò wípé o lè ṣe Gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nínu ọpọlọ rẹ, nítorí nàà ó ṣe pàtàkì láti ní ọkàn tí ó dára. Ìgbéṣẹ̀ àkọ́kọ́ láti ṣe àṣéyọ́rí nǹkan kan ni kí ó gbàgbọ́ pé o lè ṣé.
2. Bá àwọn ènìyàn tí ó nífẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀. Àwọn ènìyàn tí ó mọ rírì rẹ má ń ríí àwọn ńkan nínú rẹ tí ìwọ fúnra rẹ kò ríí àti rán ọ létí bí o ti ṣe iyebíye tó. Darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára pé wọ́n nilo rẹ tí wọ́n sì ni ìfẹ́ rẹ pẹ̀lú, (Ọlọ́run, fún àpẹẹrẹ).
3. Wá nǹkan tí ó wù ọ́ lọkan tàbí ńkan tí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti ṣe. Ó rọrùn púpọ̀, àti pé mo fi ìgboyà sọ pé ó dùn, láti jà fún ńkan tí a fẹ́ràn gidigidiọdún. Ríí dájú pé o wá àwọn nǹkan tí o ní ìtara fún gangan, kí ìfẹ́ àti akitiyan rẹ bà le pọ̀ si.
4. Gba ohun tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ gbọ́.Ò ṣe pàtàkì púpọ̀ débi pé tí Jésù bá ní láti tún fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ọ, Òun yóò ṣé bẹ́ẹ̀. Nínú Bíbélì ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹsẹ tí ó rẹwà ni a yà sọ́tọ̀ fún ìwọ fúnra rẹ. Ọlọ́run sọ pé òhun ní ìfẹ́ rẹ, pé o lágbára, pé o níye lórí àti pé ojúṣe rẹ ni. Tí Oba gbogbo àgbáyé bá nígbàgbọ́ nínú re, kíló se ọ́ tí ìwọ kò fi ní ìgbàgbọ́ nínú ara re?
Lóni o lè yàn láti má ṣe íyèméjì sí ara re mọ́. Èyí le jẹ́ ọdún tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí o bá wo dígí, ìwọ yóò ríí ẹnìkan tí ó rẹwà àti tí ó pé nínu Krístì. Máṣe jẹ́ kí àìní ààbò àti ìbẹ̀rù gba ìṣàkóso ayé rẹ, Ọlọ́run ti gba ìṣàkóso wọn
Iṣẹ́ Àkànṣe: Ṣe ìdámọ̀ àwọn ńǹkan mẹ́ta tí ó ṣòro fún ọ láti mọ rírì wọn nípa ara rẹ. Ohun tí o le yípadà, ṣé; Ohun tí ìwọ kò le yípadà, ní ìfẹ sì.
Leslie Ramírez
Nípa Ìpèsè yìí
![New Year, Same God](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F22987%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọdún tuntun ti dé, ó sì wá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn tuntun àti àwọn ìpinnu tí a fẹ́ láti ṣàṣeyọrí. Ohun gbogbo ti yípadà ní àgbáyé; síbẹ̀síbẹ̀, a ní Olódùmarè Ọlọ́run kannáà tí ó lè fún wa ní ọdún tí ó ní Ìbùkún. Darapọ̀ mọ́ mi ní àwọn ọjọ́ mẹ́rin wọ̀nyí tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pẹ̀lú ìdí kàn tàbí òmíràn ní pàtó.
More