Ọdún tuntun, Ọlọ́run Kan NáàÀpẹrẹ

New Year, Same God

Ọjọ́ 1 nínú 4

Jẹ́ kí àpótí rẹ wà ní òfo

Àwọn ìyá ní Latin America nígbà gbogbo a máa ra àwọn ohun ìrántí láti fi ránṣẹ́ bíi ẹ̀bùn sí gbogbo àwọn ìbátan wọn nígbà kúgbà tí wọ́n bá lọ sí ìrìn-àjò. Ohun tí ó dùn jùlọ ni pé wọn a máa lo àwọn àpótí wọn láti gbé gbogbo ẹ̀bùn náà láì bìkítà iye ààyè tí yíó gbà!

Ǹ jẹ́ o ti jẹ́ arin ìrìn-àjò báyìí rí?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó jẹ́ ohun tí ó pani lẹ́rìn, òtítọ́ rẹ̀ ni wípé ó jẹ́ ohun tí kò rọrùn nígbà míràn. Àwọn nǹkan tí a ti pèsè fún àwọn ẹlòmíràn yíò gba gbogbo àyè nínú àpótí náà, dé ibi pé kò ní sí àyè fún àwọn nkàn tí ó ṣe kókó julọ

Ohun kannáà ní máà ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé wa. À ń fa ẹrù tí ó kún fún àwọn ìrírí tí a ti là kọjá sẹ́yìn. À ń gbé àwọn nkan tí ó ń jẹ́ kí àpò ayé wa wúwo rìnrìn, ó burú bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó jẹ́ wípé ó ti gba àyé àwọn nkan tí a nílò láti gbé.

Kíni ó yẹ kí á mú kúrò láti pèsè àyè? O lè jẹ àwọn nkan tí a ti là kọjá seyin ní o ṣé ìdíwọ́ fún wa lati tún gbìyànjú si. Bóyá iyèméjì ni kò jẹ́ kí á tẹ̀ síwájú, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ìpalára tí wọ́n ti sọ sí wa tí a fi sọ́kàn.

Ó ṣe pàtàkì fún wa láti máa wípé kìí ṣe dandan kí á gbé àwọn nkan wọ̀nyí, nítorí wọn kìí ṣe tiwa. Wọ́n jẹ́ àwọn nkan tí a ti là kọjá sẹ́yìn. Tí a bá fi wọ́n sílẹ̀ síbẹ̀ ńkọ́?

A ní láti pèsè àyè sílẹ̀ fún gbogbo àwọn nkan dáradára tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa ní ọdún yìí! Àwọn ìrírí tuntun àti ẹ̀kọ́, àwọn ènìyàn tuntun, àwọn àṣeyọrí tuntun ...

Kí ọdún yí báà ni ìbùkún, ó ṣe kókó kí á pèsè àyè fún àwọn ìbùkún. Mo mọ̀ wípé ó sòro láti ní ìrètí fún nkan tí ó dára jù tí a bá bójú wo ẹ̀yìn tí a sì rántí gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dára, sùgbọ́n rántí wípé Ọlọ́run lè jẹ́ kí gbogbo nkan ṣiṣẹ́ pọ fún rere. A ni ànfàní loni láti gbé ìgbé ayé tí ó yàtọ̀, láti gbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti kí á má ṣe bẹ̀rù, láti gba àwọn nkan tí ó yẹ, kí á sí jù àwọn nǹkan tí kò dára sílẹ̀, kí á sì tẹ̀síwájú

Ẹ jẹ́ kí á gbé àpò tí ó kún fún ìrètí, ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, àti àwọn àlá tí ó dára. Ẹ jẹ́ kí á fi gbogbo nkan tí ó ti jẹ́ ẹrù sẹ́yìn, kí á máa wò bí Ọlọ́run yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tí ó tọ́ kún un fún wa. Mọ ti di àpò mi fún ìrìn àjò yìí, kíni ìwọ́ ń dúró dè?

Isẹ́ àkànṣe: Rò nípa nkan mẹ́ta tí o tí n gbe fún ìgbà pípẹ́ tí ó ti ń jọba lórí rẹ. Kò wọn lé Ọlọ́run lọ́wọ́ kí o sì bèèrè lọ́wọ́ Rẹ kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ kí àwọn ẹrù yìí má jẹ̀ ohun tí yíó máa wà títí lọ

Leslie Ramírez

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

New Year, Same God

Ọdún tuntun ti dé, ó sì wá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn tuntun àti àwọn ìpinnu tí a fẹ́ láti ṣàṣeyọrí. Ohun gbogbo ti yípadà ní àgbáyé; síbẹ̀síbẹ̀, a ní Olódùmarè Ọlọ́run kannáà tí ó lè fún wa ní ọdún tí ó ní Ìbùkún. Darapọ̀ mọ́ mi ní àwọn ọjọ́ mẹ́rin wọ̀nyí tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pẹ̀lú ìdí kàn tàbí òmíràn ní pàtó.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Leslie Ramírez Lázaro tíó pèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://aboutleslierl.web.app/