Sísọ Ọ̀rọ̀ ÌyèÀpẹrẹ

Speaking Life

Ọjọ́ 4 nínú 6

Bibára-ẹni Sọ̀rọ̀

Óhùn tí ó ròkè jù tí a máa ń gbọ́ ní óhùn tíra wa. Óhùn inú wa, ìyẹn óhùn tí a fi ń bára wa sọ̀rọ̀. Ó dakẹrọrọ, ṣugbọn ó lágbára. Bibára-ẹni sọ̀rọ̀ ṣe pataki, ó sì jẹ́ ǹkan tí a máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí a bá wa ní jíjí. Ó jẹ́ ẹya Ṣíṣètò Èdè tí Neuro. Nítorí ó jẹ́ ǹkan tí a máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, ó lè darí ìmọ̀-ára wá.

Àparun ní ọ̀tá wa. Ó fẹ́ràn láti máa mú irọ́ áti ìgbà èwe wa fi tàn wa jẹ nípa òtítọ́ wa. Òun kan ṣoṣo tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa wa jẹ òun tí Ọlọ́run, Aṣẹẹ́dà, Olùpilẹ̀ṣẹ̀, Ẹlẹ́dàá, Àkódá ayé, ń wí nípa wa. Ǹjẹ́ a lè dá àwọn óhùn méjèèjì yìí yàtọ̀? lyàtọ̀ jẹ pé ìkan ń fún wa ní ìyè, ìkéjì ń mú ikú wá, ìyẹn ikú àìyára.

A tí sọ̀rọ̀ nípa bí ìrò ọkàn wa ṣe ń di ọ̀rọ̀ tí a ń sọ. Ǹkan tí a bá ń sọ sábà máa ń di òtítọ́ wa. Tí a bá ro pe a jẹ́ aláìlọ́gbọ́n, ó lè mú kí a máa hùwà bí a ṣe tí sọ. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí a bá gbàgbọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa pé tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá wa? Pé ìyanu ní a jẹ́? Pé àwa l’ọmọ Ọba? Ṣé ìgbésí ayé wa a yàtọ̀? Tí a bá yàtọ̀, a ó ìgbé ayé wa yàtọ̀. Ìyípadà ní èrò wa máa mú kí inú wa kó yípadà bí a ṣe ń soro àti bí a ṣe ń hùwà.

Bibára-ẹni sọ̀rọ̀ rere: Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣ’akiyesi pé bibára-ẹni sọ̀rọ̀ rere lágbára láti mú kí a túbọ̀ máa ní ìgboyà áti láti dènà èrò òdì. Ó jẹ́ igbìmọ̀ ńlá fún ìyípadà. Ọ̀rọ̀ rere dára fún àlàáfíà wa nítorí ó máa ń jẹ́ kí a ni ìgboyà, kí a l’ayo, kí wàhálà dín ku, àti láti mú wa láradá. Èèyàn tí ó bá le kẹkọ bibára-ẹni sọ̀rọ̀ rere máa ń ní ìgboyà, máa jáfáfá àti máa ń ṣàṣeyọrí. Ọlọ́run dá wa fún ìyè, ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé bibára-ẹni sọ̀rọ̀ tọ́ èrò àti ìlérí Ọlọ́run fún ayé rẹ?

Bibára-ẹni sọ̀rọ̀ òdì: Àwa náà tí ń kíyèsi àwọn ipa ti ìtakò tinú wa ń fa, àti ọ̀rọ̀ òdì tí a bá ń sọ ń ṣe sí wa. Ọ̀rọ̀ òdì tí èèyàn bá sọ síra rẹ lè mú kí ìgboyà wa dín ku, kí èrò wa nípa áyé yàtọ̀, kí agbára wa dín ku, kí ìbálòpọ̀ wa pẹ̀lú àwọn mìíràn má lọ dédé, kódà kí a pàdánù àlàáfíà wa. Tí a bá kíyèsi bí ó ṣe ń wáyé, a lè gbé ìgbésẹ̀ láti yẹra fún ìwà yii. Ẹ jẹ́ kí a mú óhùn òdì nínú wa dákẹ́ kí a sì pàṣẹ ìyè àti òdodo si áyé wa.

Ọ̀rọ̀ tí a bá sọ sí ara wa ṣe pàtàkì. Ẹ jẹ́ kí a kíyèsi. Èèyàn máa ń sábà sọ ọ̀rọ̀ òdì nípa ara rẹ̀ l’áìmọ̀. Fún wákàtí mẹrinlelogun, kíyèsi èrò ọkàn rẹ ati ọ̀rọ̀ ti o ń rò nípa ara rẹ̀. Pinnu láti yọ ọ̀rọ̀ òdì kúrò kí o sì wá tọ́ èrò ọkàn rẹ áti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sí ìlérí Ọlọ́run.

Àṣàrò:

Àwọn ọnà wo ló lè fi Bibára-ẹni sọ̀rọ̀ rẹ fi tọ́ ǹkan tí Ọlọ́run pàṣẹ nípa rẹ? Ṣé ó máa ń ṣe àánú fún ara rẹ? Ǹjẹ́ ó mọ̀, áti máa ń sọ nípa ẹni tí ìwọ jẹ́ nínú Kristi?

Àdúrà:

Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ pé mo jẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹ ṣe pàṣẹ fún mi. Jẹ́ kí óhùn Yín jẹ́ ohùn tí ó ròkè jù l’ayé mi. Jẹ́ kí n lè pàṣẹ ọkàn rẹ̀ sí ọkàn mi.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Speaking Life

Ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó kún fọ́fọ́ fún agbára! Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni ró tàbí èyí tí ń fani lulẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tàbí èyí tí ń mú ikú wá. Èyí tí o yàn wá kù sí ọ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká jọ ṣe àgbéyẹ̀wò agbára inú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Roxane Parks fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.roxanneparks.com/home.html