Sísọ Ọ̀rọ̀ ÌyèÀpẹrẹ

Speaking Life

Ọjọ́ 2 nínú 6

Ronú Nípa Ǹkan Tí Máa Sábà Wá Sí Ọ Lọ́kàn

Agbára ìyè ń bẹ nínú èrò-ọkàn wa. Èrò wa ṣe pàtàkì. Òwe 23:7 (KJV) sọ wípé, “Nítorí bí ènìyàn ti rí, ni èrò-ọkàn rẹ̀.” Èrò wa ṣe pàtàkì nítorí látinú ìṣúra èrò-ọkàn ni ọ̀rọ̀ ti máa ń jẹyọ. Èrò àti àyàbá ọkàn wa á máa nípa lórí irú èèyàn tí a jẹ́. Ǹkan kan náà tó ṣe atọ́nà fún èrò wa náà ni yóò tọ́ ipa ọ̀rọ̀, àti ìwà wa pẹ̀lú. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ tí a sọ ṣe pàtàkì àmọ́ èrò-ọkàn wa tún ṣe pàtàkì jù ú lọ. Bíbélì rọ̀ wá láti máa ronú, pẹ̀lú àṣàrò tó jinlẹ̀, nípa ǹkan tó ní ìròyìn rere. Ǹjẹ́ a tilẹ̀ ń fi ìgbọràn ṣe ojúṣe wa bí?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé la ti kọ nípa bí ọ̀rọ̀ tií ṣiṣẹ́ atukọ̀ fún èrò-ọkàn àti ìmọ̀lára wa. Ǹkan tó gba ọkàn rẹ kan yóò nípa lórí èrò rẹ. Ṣé “ǹkan tí ẹyẹ bá jẹ ló máa gbé fò?” Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a ní láti fi ọwọ́ dọin-dọin mú èrò wa, pàápàá níwọ̀n ìgbà tí okùn àlàáfíà ara àti ìgbé-ayé wa so mọ́ ọ. Ọ̀tá wa fẹ́ kí ọkàn wa jẹ́ kìkìdá onírúurú ìdọ̀tí àti èrò asán. Ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ èrò-ọkàn wa. 

Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Àsopọ̀ Ọpọlọ àti Èdè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àsopọ̀ tó ṣe pàtàkì wà láàárín èrò inú ọpọlọ wa, èdè tí a fi ń sọ̀rọ̀, àti àwọn ìhùwàsí pẹ̀lú ìgbésẹ̀ wa gbogbo. Àwọn tó ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yí ńṣe àgbéyẹ̀wò àmúlò èrò-ọkàn tó ní ìjánu fún ìgbé-ayé àlàáfíà.

Ohun ojú wá ṣ'óhun l'ojú rí, a ní láti ronú dáradára nípa ǹkan tí à ń lépa rẹ̀. Bí ó ti wà nínú ìtàn kan…ẹyẹ igúnugún kan àti ẹyẹ eléso kan ń fò ré àṣálẹ́ kan náà kọjá. Igúnugún náà ń wá òkú ẹran tó ti ń kẹ̀ láti jẹ. Igúnugún yíì padà rí òkú ẹran. Ní ìdà kejì, ẹyẹ eléso náà ń wá ìyè tí ń bẹ nínú oje inú koríko-eléso. Ẹyẹ eléso yìí sì padà rí koríko-eléso. Ǹkan tí ẹyẹ méjèèjì ń lépa ni wọ́n padà rí. Ṣọ́ra fún irúfẹ́ ǹkan tí ò ń lépa, ohun tí ò ń gbàrò àti ǹkan tí o gbà láàyè ní kọ̀rọ̀ ọkàn rẹ. Nítorí látinú ìṣúra èrò-ọkàn wa ni ọ̀rọ̀ ti ń ṣàn jáde. 

Kọ́ríńtì Kejì 10:5 sọ fún wa wípé a ní láti ""bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu."" Ó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ìgbé-ayé tó ṣe àkíyèsí sí èrò-ọkàn àti láti mú gbogbo rẹ̀ ní ìgbèkùn! Ọlọ́run ti fún wa ní Ẹ̀mí Mímọ́ láti ró wa lágbára fún èyí. Mímú èrò-ọkàn rẹ ní ìgbèkùn túmọ̀ sí wíwà ní ìkápá ǹkan tí ò ń rò nípa araà rẹ àti ìgbésí ayé lápapọ̀.

Nígbà tí a bá ń ronú nípa gbogbo ìbùkún wa, àmúyẹ Ọlọ́run àti Baba tó ní ìfẹ́ wa, àti ẹwà Rẹ̀ nínú ìṣẹ̀dá, àwọn òtítọ́ yìí ni yóò jẹ́ ìtùnú fún wa. Àmọ́, nígbàkúùgbà tí a bá fi àìní wa àti kùdìẹ̀-kudiẹ ayé yìí ṣe àfojúsùn, yóò mú ìkárísọ àti àníyàn dé bá wa. Ìjàkadì ńlá ń ṣẹlẹ̀ ní gbàgede ọkàn rẹ. Ọ̀nà tí èrò tó nípọn jù nínú ọkàn rẹ bá korísí ni ìgbésí-ayé rẹ pẹ̀lú yóò tẹ̀lé. Fún ìdí èyí, di ìhámọ́ra òtítọ́ tí ń fúnni ní ìyè fún ọkàn àti èrò rẹ!

Gba èyí rò:

Wá àkókò láti gbé èrò rẹ jálẹ̀ ọjọ́ kàǹkan yẹ̀wò. Ṣé èyí tó dára tó sì mú ìyè dání ló jẹ́? Àbí ṣé èyí tó mú aburú dání ni? Kí ni àwọn ǹkan tó ń mú èrò onírúurú jẹyọ lọ́kàn rẹ lójojúmọ́?

Gbàdúrà:

Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àkíyèsí èrò mí nítorí òhun ló ńṣe atọ́nà ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Mo fẹ́ kí èrò ìyè máa dárí ahọ́n mi láti máa sọ̀rọ̀ ìyè. Mo nílò Ọ̀rọ̀ Òtítọ́ Rẹ láti máa gbénú ọkàn mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti mú gbogbo èrò tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú Òtítọ́ Rẹ ní ìgbèkùn.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Speaking Life

Ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó kún fọ́fọ́ fún agbára! Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni ró tàbí èyí tí ń fani lulẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tàbí èyí tí ń mú ikú wá. Èyí tí o yàn wá kù sí ọ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká jọ ṣe àgbéyẹ̀wò agbára inú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Roxane Parks fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.roxanneparks.com/home.html