Sísọ Ọ̀rọ̀ ÌyèÀpẹrẹ
Yíyàn Láti Sọ̀rọ̀ Ìyè
Ọ̀rọ̀ ẹnu wa ṣe pàtàkì. Ọ̀rọ̀ fẹ́rẹ̀ jẹ́ ipá tó nípọn jùlọ tí a fifún ẹ̀dá ènìyàn. A lè yàn láti lo agbára yí lọ́nà tó dára, nípa rírú ènìyàn sókè, tàbí nípa fífà wọ́n lulẹ̀. Lótìítọ́ ni ọgbẹ́ náà ma sàn ṣùgbọ́n àpá rẹ̀ yóò wà títí. Ọ̀rọ̀ wa ní ipá láti ṣe ìrànlọ́wọ́ tàbí ìpalára, láti ṣàtúnṣe tàbí ba ǹkan jẹ́, láti kọ́ tàbí wó palẹ̀, láti bánirẹ́ tàbí bánijà, láti kẹ́dùn tàbí bẹnu àtẹ́ lù.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nínú ilé ní ipa pàtàkì lórí àlàáfíà àti ìwàláàyè. Àwọn òbí lè fi ahọ́n ṣá àwọn ọmọ lulẹ̀. Ọmọ náà sì lè gbó àwọn òbí lẹ́nu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó lè tú ẹbí ká. Nígbà tí a bá fèsì sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó lè jáni lulẹ̀, ǹkan tí yóò t'ẹ̀yin rẹ̀ yọ lè mú ìdibàjẹ́ ńlá dé bá ẹni tí a sọọ́ sí. Ó rọrùn láti sọ èrò àti ìmọ̀lára wa; àmọ́, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ọgbọ́n inú láti sọ̀rọ̀ láì ta àbùkù bá ẹnikẹ́ni ní gbogbo ọ̀nà. Tẹsẹ̀ dúró kí o sì ní sùúrù kí o tó sọ̀rọ̀, pàápàá nígbà tí ara rẹ̀ kò bá lélẹ̀. Gẹ́gẹ́bí òbí, a ní láti sọ̀rọ̀ ìyè sínú ayé àwọn ọmọ wa láti ọjọ́ tí a bí wọn sáyé.
Lọ́kọ-láyà gbọ́dọ̀ máa ṣe àgbéyẹ̀wò agbára ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ síra. Iṣẹ́ wa, ìròyìn àgbáyé, àwọn ọmọ àti ìgbésí-ayé gan a máa mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn wá. A wá nílò láti gbé ìgbéyàwó àti ẹbí wa lárugẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wá látinú ìgbàgbọ́ kìíṣe látinú làásìgbò, àníyàn tàbí ìfòyà.
Joyce Landorf Heatherley kọ ìwé kan tí ó pè ní Àwọn Ènìyàn Ọ̀dẹ̀dẹ̀. Àwọn ènìyàn kan wà ní 'ọ̀dẹ̀dẹ̀' ayé rẹ, tí wọ́n ń hó tẹ̀lé ọ, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìwúrí láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Àwọn mìíràn sì wà ní 'àjà-ilẹ̀' ayé rẹ tí wọ́n ń lépa ìdàkejì fún ọ. Ìwé yìí dá lóríi jíjẹ́ 'èèyàn ọ̀dẹ̀dẹ̀.' Ṣé ènìyàn ọ̀dẹ̀dẹ̀ ni ìwọ ńṣe? Àbí ènìyàn àjà-ilẹ̀?
Ète Sátánì láti mú wa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú agbára inú ọ̀rọ̀ wa. Nítorí ìdàrú-dàpọ̀ ni ìṣẹ̀dá Sátánì dá lórí, ó ń ṣiṣẹ́ láì sinmi láti mú ọ̀rọ̀ búburú máa súyọ lẹ́nu rẹ. Máṣe jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí! Ó mọ̀ wípé ọ̀rọ̀ rẹ kìí jáde láìní ìtumọ̀ tàbí láì lágbára. Wọ́n lágbára láti ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá, gẹ́lẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ní báyìí, a ní àṣẹ láti ṣe irú ìṣẹ̀dá yìí ní orílẹ̀ ayé.
Jíròrò lórí òtítọ́ wípé ọ̀rọ̀ rẹ kún fọ́fọ́ fún agbára. O lágbára láti yí ayé gbogbo àwọn tó sún mọ́ ọ padà…látorí ẹbí rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn alábàágbé àti àwọn àlejò tí ń kọjá lọ lẹ́bàá ọ̀nà. Ó wá kù sí ọ lọ́wọ́ láti lo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ láti gbéni sókè tàbí fà lulẹ̀. Rántí, lọ́gán tí ọ̀rọ̀ bá bọ́—tó fọ́, kò ṣeé kó mọ́.
Ṣe àkíyèsí ìsọ̀rọ̀sí rẹ.
Yàn láti sọ̀rọ̀ ìyè!
Gba èyí rò:
Ṣe àgbéyẹ̀wò agbára tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ rẹ kàǹkan láti múni dúró tàbí bì ṣubú. Ọ̀nà wo lo lè gbà láti máa sọ ọ̀rọ̀ ìyè sínú ayé àwọn ẹlòmíràn?
Gbàdúrà:
Háà Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti máa ṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ kàǹkan tí ń tẹnu mi jáde. Kọ́ mi láti máa sọ àwọn òtítọ́ afúnni-níyè sínú ọkàn àwọn ẹlòmíràn.
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó kún fọ́fọ́ fún agbára! Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni ró tàbí èyí tí ń fani lulẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tàbí èyí tí ń mú ikú wá. Èyí tí o yàn wá kù sí ọ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká jọ ṣe àgbéyẹ̀wò agbára inú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde.
More