Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́Àpẹrẹ
Kíkó Ìdánimọ̀ Nínú Krístì Mọ́ra
Ìyàtọ̀ kan wà láàrin mímọ ohun tí a kọ sínú Bíbélì àti gbígbàgbọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ dé'bi tí ó yí ayée wa padà. Gbígba ìdánimọ̀ wa nínú Krístì nítòótọ́ ni ohun tí ó fún wa ní ipá láti d'ojú kọ ìdánwò pẹ̀lú ìgboyà. Ó kún ayé wa pẹ̀lú ayọ̀, àlàáafíà, àti èrèdí. Ó mú kí a leè fẹ́ràn ara wa nítorí péÓ fẹ́ràn wa. Níní òye ẹni tí a jẹ́ àti ti ẹni tí a jẹ́ yí gbogbo nnkan padà, ṣùgbọ́n a ní láti máa kíyè sára nígbàgbogbo.
Láti kété tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbọ́ pé a ní'ye lórí, pé a fẹ́ràn wa, àti pé Ọlọ́run ti yà wá s'ọ́tọ̀, ni ọ̀tá ti máa fẹ́ ká gbogbo rẹ̀ kúrò. Ó kórìra kí á fi ìdanimọ̀ kọ́ sínú Jésù nítórí pé ó máa ń sọ ọ́ di alàìlágbára nínú ayé wa àti ayé àwọn ẹlòmíràn nítorí pé àwọn náà máa wá ní ìrètí. A kò lè gba Sàtánì láàyè láti rán wa létí ohun tó ti kọjá sẹ́hìn nínú ayé wa tàbí kí ó pàrọwà fún wa pé a kò lè yí padà. Bíbélì sọ pé nígbà tí a bá gba Jésù sínú ọkàn wa, a di ẹ̀dá títun. Oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ bo ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìtìjú wa àti ohun tí ó ti kọjá sẹ́hìn. A ní láti di òtítọ́ pé a jẹ́ Tirẹ̀ mú ṣinṣin.
Ó rán mi létí igi kan nínú àgbàlá wa. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbìn ín, ó nílò irin láti gbé e dúró kí ó sì fún un lágbára. B'ọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, igi náà hù yí irin yìí ká, t'ó jẹ́ kí ó má ṣeéṣe láti yọ irin yì kúrò. Báyìí, irin ti di ara kanná pẹ̀lú igi. Bákannáà, òtítọ́ Ọlọ́run ń fún wa ní okun. Tí a bá dìí mú pẹ́ tó, á di ara ìdánimọ̀ wa tí a kò lè ṣí kúrò.
Ìgbésẹ̀:
Ọlọ́run f'arabalẹ̀ láti dá gbogbo ohun tí ó mú kí ó jẹ́ ìwọ. O rí ojúlówó rẹ Ó sì fẹ́ràn rẹ láìka ohunkóhun sí. Jẹ́ kí òtítọ́ yìí wọlé sínú rẹ. Má sálọ fún un, má sápamọ́ fún un, má sì gbìyànjú láti f'ọwọ́ rọ́ ọ sẹ́gbẹ̀ẹ́. Béèrè kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbà á gbọ́ kí ó sì di ohun tí a kò lè yà kúrò láyé rẹ. Nígbà tí o bá gba ìdánimọ̀ rẹ nínú Krístì ní tòótọ́, wàá di òmìnira kúrò lọ́wọ́ irọ́ tí ó dè ọ́ mọ́lẹ̀, wàá sì ní ìgboyà láti d'ojú kọ ìdánwò kídánwò.
Ọlọ́run Bàbá, o ṣeun pé o darí mi sí ìlànà ẹ̀kọ́ yìí o sì ràn mí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò fífi ìdánimọ̀ mí lélẹ̀ nínú rẹ. Dákun ràn mí lọ́wọ́ láti rí àwọn àkọlé tí mo ti ń gbé lábẹ́ẹ wọn gẹ́gẹ́ bí irọ́ tí wọ́n jẹ́ kí O sì ràn mí lọ́wọ́ láti fi òtítọ́ Rẹ rọ́pò wọ́n. Ràn mí lọ́wọ́ láti má fi ara mi wé àwọn elòmíràn kí n ṣì yé gba ìbára-ẹni sọ̀rọ̀ òdì láti darí ayé mi. Fún mi ní ojú tó rí ara mi gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí mi - ẹni tí a fẹ́, tí ó ṣe iyebíye, tó wu ni, tó lágbára, tó ní ẹ̀bùn tó yàtọ̀, tí a sì dá pẹ̀lú ẹwà. Ìwọ ni mo fẹ́ kí wọ́n fi ṣe àpèjúwe mi, kìí ṣe nnkan míràn. Mo fún òtítọ́ rẹ ní àṣẹ lórí ayé mi mo sì bèèrè pé kí o fi hàn mí bí mo ṣe leè mú ìjọba Rẹ gbòòrò pẹ̀lú ohun tí O fi fún mi. O ṣeun fún ìfẹ́ àìlódiwọ̀n tí kò pa mí tì síbi tí mo wà ṣùgbọ̀n tí ó ń fà mí súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ síi. Mo fẹ́ràn Rẹ mo sì gbẹ́kẹ̀lé Ọ. Ní orúkọ ńlá Jésù, àmín.
A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run lo ìlànà ẹ̀kọ́ yìí láti bá ọkàn rẹ pàdé.
Ṣàwárí Àwọn È̩kọ́ Bíbélì Míràn Lórí Gbígbé Ayé Tóti N'ìyípadà
Nípa Ìpèsè yìí
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.
More