Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́Àpẹrẹ

Living Changed: Embracing Identity

Ọjọ́ 3 nínú 6

Yíyàgò Fún Pańpẹ́ Ìfarawéra

Ṣé o tilẹ̀ ti ronú báyìí rí pé, “K'ání mo tẹ́ẹ́rẹ́ ni, mi ò bá ti l'ọ́kọ,” tàbí “K'ání mo já fáfá bì i ti lámọrín ni, mi ò bá ti ní ìgbéga yẹn,” tàbí “kílódé ti àwọn ọmọ mi kò hùwà bí i ti ọmọ lámọrín?” Bí o bá tí kéré lójú ara rẹ rí, nítorípé o kò dàbí ẹnìkan, a jẹ́ pé ìwọ náà ti kó sí pańpẹ́ ìfarawéra nìyẹn.

Nígbàtí mò ńdàgbà, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin a máa fi mí wé arábìnrin mi. Wọn a wí pé mi ò kẹ̀rẹ̀, àmọ́ arábìnrin mi ni ẹni tí ó “wuyì jọjọ.” Bí mo bá ti gbọ́ eléyìí ni yíó dàbí pé a ré mi ní ìfásẹ̀. Ó wù mí gidi pé kí n jẹ́ ẹni ayé ńfẹ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ígbà ni ọkàn mi máa ń gb'ọgbẹ́ látàrí ìjákulẹ̀. Mo mọ̀ pé bí mo bá dín oúnjẹ jíjẹ mi kú, tí mo yí àwọ̀ irun mi padà, tí mó sì wọ àwọn aṣọ tó yááyì, mi ò lé dàbí arábìnrin mi láí àti pé mi ò lé kún ojú òṣùwọ̀n rẹ̀.

Léyìnọ̀rẹyìn, bí mo ti dúró tí mò ńwo àwọn agbègbè tí à ń pè ní Òkè Rocky, ẹnu yà mí gidi fún bí wọn ti rẹwà tó tí wọn sì kún fún ọlańlá. Ní àkókò yẹn gan an, Ọlọ́run sọ kẹ́lẹ́ sí ọkàn mi pé Òun ṣ'èdá àwọn òkè yẹn àti èmi náà. Ó rọra sọ fún mi pé, “O rẹwà ju àwọn òkè yẹn lọ.” Ó ṣòro fún mi láti gbà pé Ẹlédàá kannáà tó dá àyíká tó wú 'ni lórí tóbẹ́ẹ̀, l'Ó hun mí pọ̀ nínú ìyá mi tí Ó sí fún mi ní àwọn àbùdà tí mò ńbu ẹnu àtẹ́ lù. Ìgbà yìí ni mo wáá pinnu pé, bí Ó bá sọ pé mo rẹwà, mo ní láti gbà yí gbọ́ nígbànáà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa ló tí gbà pé a kò dára tó. Ohunkóhun tó wù tí a fẹ́ jẹ́—ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, ẹni l'ókun nínú, alágbára, ẹni to já fáfá, adẹ́rìnpòṣónú—a kò lè kún ojú òṣùwọ̀n. Ní tòótọ́, a kàn ń ṣe àfiwé ohun tí a lè f'ojú rí ni, àti pé lópọ̀ ìgbà ohun tí ó f'ara pẹ́ ìgbé-ayé ìrọ̀rùn, lè ṣòro gidi. A lè máa fi ara wa wé ẹni tó tíńrín tó sì jẹ́ pé onítọ̀hún ní àrùn málèjẹ́un. A lè rò pé alábàṣiṣẹ́pọ̀ wa ní ohun gbogbo, tó sì jẹ́ pé ìgbeyàwó rẹ̀ ń f'orí ṣánpọ́n lọ. A lè rò pé a fẹ́ irú ẹbì ẹlòmíràn bó ṣe wù ojú rí yẹn, tó sì jẹ́ pé gbogbo wọn ń la ìkáríbọnú ńlá kọjá. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé kò sí ẹni tó pé nínú wa.

A ní láti d'ẹ́kun láti máa fi ara wa wé ẹlòmíràn. Bí Ọlọ́run bá fẹ́ kí a rí bákannáà, yí Ó tí dá gbogbo ẹ̀dá bákannáà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ó dá wa lárà ọ̀tọ̀. Ó ṣe pàtàkì pé kí èyí yé wa nítorípé bí a bá ṣe rí ara wa níí ṣe pẹ̀lú bí a ó ṣe ṣe sí ẹlòmíràn. Ó tún tabá àwọn ìpinnu tí à ń ṣe. Ó ńdarí ayé wa. Nígbàtí a bá fi ara wa wé ẹlòmíràn, a ó sọ àlááfíà, ayọ̀, àti ìgboyà tí Ọlọ́run fún wa nù. Àmọ́, bí a bá mú èrò wa wá sí ìbámu pẹ̀lú Krístì tí a sì ṣe ọkàn wa l'ọ́kan pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì, a ó rí ipa ọ̀nà Rẹ̀ fún ayé wa. Ìyè ní kíkún ni ayé t'Ó sì fẹ́ fún wa.

Ìgbésẹ̀:

Bí o kò bá tíì wí pé a dá ọ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tìyanutìyanu, bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ báyìí. Bí o bá ti gbàgbé làti máa gbé ìgbé-ayé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú òtítọ́ yìí, bẹ̀rẹ̀ l'ọ́tun. Mú gbogbo èrò “Mi ò dáa tó,” “Mo fẹ́ dàbíi lámọrín,” tàbí “K'ani Ọlọ́run lè fún mi ní kiní yẹn ni,” wá sínú ìgbèkún kí o sì pa wọ́n rẹ́. O jẹ́ ẹ̀dá kan tó rẹwá lárà ọ̀tọ̀, àṣeparí iṣẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run kìí sì ṣe àṣìṣe. A dá ọ ní àwòràn Rẹ̀. O ṣe iyebíye. Yàn láti gba èyí gbọ́.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: Embracing Identity

Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.

More

A fé dúpé lówó àwọn Changed Women Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, ẹjòwó ṣe ìbẹ̀wò sí: https://www.changedokc.com