Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́Àpẹrẹ
Àwọn Àtẹ̀mọ́ ti ó Ba lé Wa
Kò sí eni tó fé kí wọ́n fi àtẹ̀mọ́ pe òun. Látàrí pé àwọn àtẹ̀mọ́ má ń fi ojú ojú gbogboogbò wo nkan tó lè má rí bẹ́ẹ̀, wón ń máa kópápá mọ́ra, wón kìí sì ṣe déédé. Wọ́n ma ń wá pẹ̀lú oríṣi èrò, tó lè jẹ́ èrò òdì, wọ́n sì máa sábà fi àwọn àbùdá ènìyàn tó burú jùlọ hàn tàbí àwọn àṣìṣe wa tó tóbi jù. Àtẹ̀mọ́ kìí fáyé sílè fún ìyàtò, ìdàgbàsókè, tàbí ìràpadà. Nígbàtí àwọn mìíràn bá gbìyànjú láti fi àtẹ̀mọ́ pè wá, a ní àgbàrá láti yàn láti má gbé lábé àwọn àtẹ̀mọ́.
Nígbàtí mo lé dí ẹ̀ lẹ́ni ogún ọdún, àtẹ̀mọ́ tí a mọ̀ mí mọ́ ní ìrìn panṣágà. Mo ń gbéraga lóríi àgọ́ ará mi mo sì ma ń féràn rẹ̀ nígbàtí àwọn ọkùnrin bá ṣàkíyèsí mi. Mo ń ṣe ìpinnu búburú léraléra nítorí mo rí ara mi bí eni tí kò yẹ láti fẹ́. Kòsí ohun tó ní ìtumọ̀ sí mi tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi wá gàba lóríi pé mo réwà fún sáà kan nígbà tó jẹ́ pé ohun tí mo nílò gangan ni láti béèrè lówó Jésù kí Ó wò mí sàn kí Ó sì sọ mí dòtun.
Mo tèsíwájú láti máa tiraka láti gbàgbó pé mo yẹ lẹ́ni tí àá fẹ́ lẹ́yìngbà ti mo di atẹ̀lé Jésù. Gẹ́gẹ́ bi ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, mo ń ṣàníyàn pé mo jé ẹni tó sanra tí kò jámọ́ nǹkan kan tí kò sì ní ohunkóhun láti ṣe fún ẹnikẹ́ni nítorí nkò parí iléèwé gíga. Àwọn ìwàásù òpin ọ̀sẹ̀ maá ń fún mi níṣìírí, àmọ́ mo ní ìdààmú láti mú àwọn òtítọ́ Olórun wá sínú ìgbé ayé ojoojúmó mi. Tí mo bá wo ẹ̀yìn wò, mo ní inú dídùn pé Krístì kò jáwọ́ lọ́rọ̀ mi. O ń túbo fún mi ní ànfàní láti ṣe nǹkan fún Ìjọba Rè nígbà tí mo ti ẹ̀ rò pé mi ò dáńgájíá.
Gbogbo wa ló ní àtẹ̀mọ́, yálà a gbà àwọn ti àwọn mìíràn ti tẹ̀ mọ́ wa lára tàbí èyí tí a tẹ̀ sí ara wa lórí. Lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń gba àwọn àtẹ̀mọ́ yii láàyè láti dín wa kù, kí wọ́n sì sọ fún wa pé aláìtótán lásán la jẹ́. Lásán. A má ńlo ọ̀rọ̀ kékeré, ṣùgbọ́n tí ó ṣe pàtàkì yìí sàpèjúwe ara wa a sì máa jẹ́ kí àwọn àtẹ̀mọ́ yìí sọ wá di ẹnití kò kájú òṣùwọ̀n. Ó ṣeéṣe kí o ti gbó àìmọye ènìyàn tí wọ́n sọ ọ́, bóyá o ti sọ ọ́ fún ara rẹ pẹ̀lú. “Ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gígalásán ni mí” tàbí “Òkúndùn ògùn olórólàsàn ni mí.”
Òtítọ́ ibẹ̀ nipé, o kìí ṣe ọjọ́ orí rẹ, ipò ibi iṣẹ́ rẹ, o kìí ṣe àyẹ̀wò rẹ, ó kìí ṣe ipò ìgbéyàwó rẹ, ìtiraka tí o ń là kọjá, tàbí ìgbé ayé àtijọ́ rẹ. Àwọn àtẹ̀mọ́ yìí le jẹ́ àpèjúwe ipò tí o wà lówólówó, àsìkò rẹ, tàbí ìdánwò rẹ, àmọ́ ìjúwe rẹ gan-an mbè nínú ẹni tí Olórun pè ọ́ kò dẹ́ si ohun mìíràn lẹ́yìn èyí.
O rẹwà, o dáńgájíá, ó sì yẹ. A ti sọ ọ́ di ọ̀tun nínú Krístì. A kò fún o lèmí ìbèrù, bíkòṣe ti ìfẹ́, àgbàrá, àti ti ọkàn tó yèkooro. O ju aṣẹ́gun lọ nínú Krístì Tó ń fún ọ lókun. A mọ́ọ̀mọ̀ ṣèdá rẹ fún ìdí kan pàtó. Ọlọ́run féràn rẹ. A ti yàn ọ́. O sì kún ojú òṣùwọ̀n.
Ìgbésè:
Ronú lórí àwọn àtẹ̀mọ́ tí o gbéwọ̀ tí wọ́n lòdì sí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ nínú Bíbélì. Àwon agbègbè ìgbésí ayé rẹ wo ni ó ń mú ọ nímọ̀lára ìtìjú? Kíni àwọn àìdánilójú rẹ tó tóbi jù? Kíni ohun tó wà nínú ìgbé ayé rẹ àtitjó tí ò ń fipamó nítorí ẹrù pé ẹnìkan yóò mọ̀ọ́? Gbàdúrà sí Olórun láti fi àwọn àtẹ̀mọ́ tó n fà ọ sílè hàn ọ kí Ó sí ràn ọ́ lówó láti mú àwọn ajúwe rẹ bá àwọn òtítọ́ Bíbélì dọ́gba.
Nípa Ìpèsè yìí
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.
More