Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́Àpẹrẹ
< p > Nígbà tí i a ba gba àwọn àkọlé tí a fi dá wá mọ̀ tabi gbàgbọ́ pe a kò kún ojú òṣùwọ̀n, a pàdánù lori igbe ayé tí ó lẹ́wà ti Ọlọrun fẹ fun wa. Ó ṣẹda ẹnìkọ̀kan wa pẹlu àkójọpọ̀ pataki ti agbara, ati awọn ẹ̀bùn, ati pe Ó nírètí pe a ò yàn lati lò wọn fun ijọba Rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà ti a ba ni ìdojúkọ pupọ fún ààbò lórí wa, awọn èrò òdì ati awọn ẹdun wọnyẹn le yà wa kuro ninu eredí Rẹ fun wa. < / p >
Ní ìwọ̀n ọdun díẹ̀ sẹyin, mo gbọ nipa ẹ̀kọ́ Bíbélì tí awọn obinrin gbé kalẹ̀ ti mo gbèrò lati máà lọ. Mo fẹ́rẹ̀ má lọ ní ìmọ̀lára bí mo ṣe mọ̀ ara mí tó. Mo sọ fun ara mi pe wọn ko fẹ iya ti o sanra tó bayi ti ko le sọ ohunkóhun tí ó wulo lásìkò ìjíròrò nàá nitori kò ní ìmọ̀ to nipa Bibeli. Bákan sá, mo kò ibẹru kúrò mo si lọ lọ́nàkọ́nà. Bí Ó tí máà ń ṣé nígbà gbogbo, Ọlọrun ló igbesẹ kekere ti ìjọwọ́sílẹ̀ lati bẹrẹ iyipada kan ninu mi. Ó ṣe iranlọwọ fun mi lati mọ̀ bí mo ṣé jẹ́ ati mú aworan ara mi dára sí.
< p > Ohun ti èmi kò mọ ni àkókò yẹn ni pé Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ mi ní lati gbẹ́kẹ̀le Òun ki n le ṣe iranlọwọ fun awọn obinrin míràn ní ọjọ iwájú kí wọ́n lè ṣé bákan náà. Nígbà ti mo jọ̀wọ́ àìláàbò mi silẹ fún nìkan ní mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lè gbé ìgbésẹ̀ sínú ìpè mi. Ni otitọ, ohun ti mo kọ ninu ẹ̀kọ́ Bibeli yẹn ni àkóónú ti mo lo pupọ nigbati mo bẹrẹ ìkọ́ni. Ti mo ba tí gba ibẹru mi láàyè lati jẹ ki ń mà lọ ni ọjọ yẹn, igbesi aye mi ati iṣẹ-ìránṣẹ́ mi yíò ní iyatọ pupọ.
Boya ayérayé mi pàápàá yíò ní ìyàtọ̀ pẹ̀lú. < / p >
< p > Ọlọrun fún wa ní ìgboyà nítorí pé a mọ ẹni tí a jẹ nínú Kristi. Kìí ṣé nitori àìpé wa ní ó mú àìláàbò wa kuro, ṣugbọn nitori a mọ pé a sọ awọn àìlera wa di pípé nípa agbára Rẹ̀. Ni otitọ, Ọlọrun ko nilo ki a jẹ pípé. O ṣe amọja nípa lilo awọn aláìyẹ ènìyàn, àwọn aláìtọ́, ati awọn aláìlágbára. Jákèjádò Bibeli, Ó ṣiṣẹ nipasẹ awọn aláìpé ènìyàn àti oriṣiriṣi ẹ̀yà, takọtabo, àgbà àti ọmọdé lati ṣe àṣeyọrí ifẹ Rẹ̀. Ko si ohun ti o sọ wa di aláìyẹ ní oju Rẹ̀. Àwa nìkan ní a lè yọ ara wa kúrò nínú eré-ije náà. Àwa ni ó ní lati yàn ti a ba máà gbà Ọlọrun láyè pé kí Ó ṣalaye bí a bá fẹ́ láti jẹ apákan nínú ero Rẹ, tabi kí a gbà awọn míràn láàyè lati ṣàlàyé nípa wa ati padanu àǹfààní lati ni ipa lórí ayérayé.
< / p >
< p> strong < Ìgbésẹ̀ tó yẹ: < / strong> < /p>
< p > Rorí fun ìgbà díẹ̀, báwo ní awọn irọ́ ti ó gbàgbọ́ nipa ara rẹ le jẹ ìdíwọ́ itọsọna Ọlọrun fun igbesi aye rẹ. Ṣe ó tẹti jù sì awọn èrò ati ìrètí awọn ti o wa ni àyíká rẹ, tàbí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun ti Ọlọrun ń bá ọkàn rẹ̀ sọ? < strong > Máṣe pàdánù idi tí ó fí wá láyé fún Ọlọrun àti igbesi aye rẹ nitori idanimọ rẹ ti wa ni ibi tí kò tọ́. < / strong > Béèrè lọ́wọ́ Ọlọrun lati hù awọn irọ ti a gbìn sínú ọkan rẹ jáde tí gbòǹgbò tí gbòǹgbò. Jẹ ki Ó ṣe àtúntò ohun ti a tí tú palẹ̀. Lẹhin náà béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ lati fi han ọ bi o ṣe le ṣe iranlọwọ lati mú ijọba Rẹ̀ dàgbà sókè sí. Ó ni àyè pàtàkì nínú ọkàn Rẹ̀ ati ipa pàtàkì nínú èrò Rẹ̀. < / p >
Idagbasoke
Bọtini: ọjọ_4
Nípa Ìpèsè yìí
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.
More