Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ọjọ́ 5 nínú 5

Kíni Ṣíṣe Tí Mo Bá Ti Bọ́ Sínú Ìdánwò?

Bí ẹ̀pa kò bá b'óró mọ́ ńkọ́?

O d'ojúkọ ìdánwò pẹ̀lú agbára rẹ—o sì jákulẹ̀

Ní báyìí o dúró ní ìdálẹ́bi níwájú Olúwa mímọ́ gbogbo àgbááyé.

Gbogbo wa lèyí ti ṣẹlẹ̀ sí: “Bí àwa bá wípé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwá tan ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa” (1 John 1:8).

Ohun tí a ó ṣe nìyìí: “Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtọ́ àti olódodo ni Òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo” (v. 9).

Kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tọ Bàbá rẹ lọ—nísinsìyí.

Mọ ẹ̀bi rẹ l'ẹ́bi, ronúpìwàdà àṣìṣe rẹ, kí o sì bèèrè fún ìdáríjì Rẹ̀.

Gba ìlérì Rẹ̀ láti dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì, láti wẹ̀ ọ́ mọ́, kí á má rántí àwọn ìjákulẹ̀ rẹ mọ́.

Ṣé ìdáríjì Ọlọ́run túmọ̀ sí pé a lè d'ẹ́ṣẹ̀ kí á jẹ́wọ́, kí a tún d'ẹ́ṣẹ̀ síi kí a sì jẹ́wọ́?

Kìí ṣe láàsí àtunbọ̀tán.

Mo lè kan ìṣó m'ọ́gi, kí ìwọ yọọ́ kúrò—ṣùgbọ́n àpá ìṣọ́ kò ní kúrò lára igi. Ìgbọràn tí a kọ̀ sílẹ̀ kò ṣeé rí gbà mọ́. Èrè jíjẹ́ olóòtọ́ sọnù títí láí.

Ọlọ́run ńdáríjì, ṣùgbọ́n ìrora ẹ̀ṣẹ̀ ń dun ni síbẹ̀—ó ń dun àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.

Láì ṣe àníàní, Ẹni tí Ọmọ Rẹ̀ kú d'ípò wa láti san gbèsè wa lè dáríjì wá: “Ọlọ́run fi ìfẹ́ Òun pàápàá sí wa hàn ní èyí pé: nígbàtí àwá jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Krístí kú fún wa.” (Róòmù 5:8).

Ẹ̀bí kìí ṣe látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Bàbá wa fẹ́ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ẹbí Rẹ̀. A sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀ síbẹ̀, bí a kò tilẹ̀ wùwà bẹ́ẹ̀.

Oore-ọ̀fẹ́ ni kí a gba ohun tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí; àánú ni kí á má gba èrè ohun tí a ṣe.

Bàbá wa ọ̀run ń fún ni ní méjéèjì.

Ṣe o níílò láti ṣí ẹ̀bùn ìdáríjì Rẹ̀ lónìí?

Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ má t'ẹsẹ̀ dúró. Bá Bàbá rẹ tí ń bẹ ní ọ̀run sọ̀rọ̀. Ó ńfẹ́ láti gbọ́ ọ, ọmọ Rẹ̀ olùfẹ́.

---

Láti kà síi nípa b'íborí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdánwò, download orí kìńní ìwé Dr. Denison, 7 Deadly Sins, for free.

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Denison Forum fún ìpèsè ètò yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.denisonforum.org

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ