Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Nígbàtí A Bá Dán Mi Wò?
Gbé e tọ Ọlọ́run lọ—nísinsìnyí
Nígbà tí a bá dán ẹ wò, rántí ìlérí yìí: “Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.” (Kọ́ríńtì kíní 10:13 BM).
Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ìdánwò tó kọjá agbára wa dé bá wa. Bákan náà, Sátánì ò ní fi àkókò rẹ̀ ṣòfò láti dán wa wò pẹ̀lú ǹkan tí a lè borí pẹ̀lú ipá tiwa.
Fún ìdí èyí, gbogbo ìgbà tí a bá dán ẹ wò, mọ̀ dájú wípé o kò lè borí ìjàkadì náà nípa agbára tìrẹ.
Wà ní ìgbáradì láti jọ̀wọ́ gbogbo ìdánwò rẹ fún Baba lójú ẹsẹ̀.
Tọrọ fún agbára Rẹ̀.
Jọ̀wọ́ ohun gbogbo sí ìkápá Rẹ̀.
Mú u tọ Ọlọ́run lọ—nísinsìnyí.
Ṣe àgbéyẹ̀wò àbájáde náà
Tí o kò bá tẹ̀lé àmọ̀ràn yí?
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa ni Ọlọ́run ma dá'jọ́ lé lórí: “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu. (Oníwàásù 12:14 BM).
Jésù kì wá nílọ̀: “Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.” (Lúùkù 12:2-3 BM).
A ma dá wa lẹ́jọ́ nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wa: “Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ. Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.” (Mátíù 12:36-37 BM).
Lẹ́yìn tí ó ka onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ tí a kọ̀ láti jẹ́wọ́, Pétérù wá sọ wípé gbogbo àwọn tó bá ńṣe ǹkan wọ̀nyí “yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú.” (Pétérù kíní 4:5 BM).
Kí ni ó ma ṣẹlẹ̀ sí wọn?
“Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti ìṣe. . . . Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja.” (Kọ́ríńtì kíní 3:13, 15 BM).
Àìwà-bí-Ọlọ́run, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò jẹ́wọ́, àwọn èrò, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ wa ni a ó fi lé'de lọ́jọ́ ìdájọ́ tí gbogbo rẹ̀ yóò sì jó dànù. Nítorí ibi pípé ni ọ̀run jẹ́, àwọn ǹkan wọ̀nyí kò lè wọnú rẹ̀—a gbọ́dọ̀ jó wọn run kí wọn ó sì ṣègbé.
A wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù èrè sì ti bọ́ sọnù.
Nígbàtí a bá dán ẹ wò tí ó sì ṣe ọ́ bíi kí o bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, má ṣe sá kúrò ní iwájú Rẹ̀.
Ní àkókò àìní rẹ yìí, sá tọ Ọlọ́run lọ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.
More