Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ
Njẹ́ È̩dá Kan Wà Nítòótọ́ Tí Orúkọ Rẹ̀ Ńjẹ́ Sátánì?
Láti le sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, ó pọn dandan kí á sọ̀rọ̀ lórí Sátánì. A kò lè f'ojú fo àwọn iṣẹ́ rẹ̀: ọgbẹ́ ọkàn, ilé dídàrú, àṣìlò nnkan àti ènìyàn, ààrùn àti àgbèrè. Àwọn àjálù t'ó ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá pọ̀ lọ jántìrẹrẹ.
Sátánì wà ní tòótọ́ṣùgbọ́n a tiṣẹ́gun rẹ̀. Kò fẹ́ kí o gbàgbọ́ pé òtítọ́ ni méjèèjì ṣùgbọ́n ó kù sí ọ lọ́wọ́. Àdúrà mi ni pé kí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run k'ó hàn sí ọ nípasẹ ìlànà ẹ̀kọ́ yìí.
Sátánì Wà Nítòótọ́
Sátánì tún ní àwọn orúkọ mìràn nínú Bíbélì. Méjì tí a mọ̀ jù ni "Sátánì" àti "èṣù". "Èṣù" túmọ̀ sí "olùfinisùn" àti "aṣinilọ́nà", ọ̀nà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni wọ̀n sì ti lò ó nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÈṣù wà ní ibi mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú Májẹ̀mú Tuntun, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ sì ni "apẹ̀gàn".
A tún mọ Sátánì sí "ògbólógbò ejò nì", "drágónì" àti "ẹni ibi nì". Bí Jésù ṣe ṣe àpèjúwe iṣẹ́ Sátánì ní Jòhánù 8: 42-47 ba ni lẹ́rù jọjọ.
Èkínní, Sátánì sọ pé òun ni òun ni gbogbo ọkàn tí kò ní ìgbàlà.
Ní Jòhánù 8, Olúwa sọ pé "bàbá" àwọn ọ̀tá Òun ni Sátánì (ẹsẹ́ 44). Sátánì ni "ọlọ́run ìran yìí" (2Kọ̀ríntì 4:4), "ọmọ aládè ayé yìí" (Jòhánù 12:31) tí ó ń ṣe ìdarí ìran t'ó ti ṣubú yìí (1Jòhánù 5:19). A yan àwọn Krìstẹ́nì láti máa gbé nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso. A jẹ́ ọmọ ogun lórí ilẹ̀ ọ̀tá - ilẹ̀ tí ọ̀tá ti gbà gẹ́gẹ́ bíi tiwọ̀n.
Èkejì, èṣù kìí jẹ́ kí ọkàn wa mọ òtítọ́.
Òpùrọ́ ni "òun sì ni bàbá gbogbo irọ́" (Jòhánù 8:44). Ìdí nìyí tí òye nnkan Ọlọ́run kò fi lè yé ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì gbà È̩mí Mímọ́ (1Kọ́ríntì 2:14). Sátánì fẹ́ já irúgbìn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà kúrò nínú ọkàn àwọn tó ṣe iyebíye fún jù. (Mátíu 13:1-9).
È̩kẹta, Sátánì máa ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà
Láti Jẹ́nẹ́sísì orí 3 títí di ọjọ́ òní, ó máa ń yí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà láti tàn wá ṣìnà. Ẹni t'ó ka ẹsẹ̀ Bíbélì láti dán Jésù wò (Mátíù 4: 1-11) kò ní ṣaláì fẹ́ lo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà òdì láti tan àwa náà jẹ. Kìí ṣe gbogbo nnkan tí wọ́n fi ń kọ́ wa gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀tá wa lè ka ẹsẹ̀ Bíbélì jù wá lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti tàn wá jẹ ni ní gbogbo ìgbà.
È̩kẹrin, "apànìyàn ni èṣù jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá" (Jòhánù 8:44).
Sátánì jẹ́ kìnnìún t'ó ń bú ramúramù, t'ó ń wá ẹni tí yó pa jẹ (1Pétérù 5:8). Àwọn ẹni tirẹ̀ máa n gbógun ti ara wọn àti àwa lọ́nà tí a f'ojú rí àti èyí tí a kò f'ojú rí àti nípa ìbálòpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀. Ohun t'o jẹ ọ̀gá wọn lógún ni k'ó pa ìran ọmọ ènìyàn run pátápátá, pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn ti Ọlọ́run..
È̩karùnún, Sátánì ló ń darí àwọn ẹ̀mí èṣù.
Àwọn ni ẹmẹsẹ̀ àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ rẹ̀ nínú ogun tí ó ń lọ lọ́wọ́ t'ó ń gbé ti Olúwa àti àwọn ọmọ Rẹ̀.
Kókó ọ̀rọ̀ ni pé, Sátánì ń tako Ọlọ́run.
Nínú ìwé Jòhánù 8, ó ti àwọn olùdarí ẹ̀sìn láti wọ́nà láti gba ẹ̀mí Jésù. Lẹ́hìn náà ó tì wọ́n láti kan Olúwa wa mọ́ àgbélébùú.
Ìdàkejì Ọlọ́run ni Sátánì jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà.
- Ìmọ́lẹ̀ ni Olúwa wa; òkùnkùn ni Sátánì.
- Ọlọ́run jẹ́ iná mímọ́ ajónirun; èṣù kún fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ààrùn ó sì ń rí ni lára.
- È̩mí ni Ọlọ́run; Sátánì jẹ́ ẹran ara aláìmọ́.
- Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ; Sátánì kórìíra rẹ.
- Ọlọ́run fún ọ ní ọmọ Rẹ̀; Sátánì fẹ́ gba ọkàn rẹ.
- Baba rẹ ni Ọlọ́run; ọ̀tá rẹ ni èṣù.
Sátánì wá nítòótọ́, ṣùgbọ́n máṣe gbàgbé pé; a ti ṣẹ̀gun rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.
More