Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ
Ṣé Lóòtọ́ Ni Mò Lè Borí Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ìdánwò?
Ní 1 Sámúẹ̀lì 13:14, wòlíì Sámúẹ̀lì sọ fún Sọ́ọ́lù, ọba Ísráẹ́lì pé, a ti pààrọ̀ rẹ̀ nítorípé "Olúwa ti wá fún ara rẹ̀ ọkùnrin tí ó wù Ú ní ọkàn Rẹ̀, Olúwa sì ti pàṣẹ fún u kí ó ṣe olórí fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.”
Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, "ẹni bí ọkàn Rẹ̀" ní ìbáṣepọ̀ kòtọ́ pẹ̀lú adélébọ̀, èyí tí ó yọrí sí oyún, and ó s'àṣeyorí nínú ète rẹ̀ láti pa ọkọ adélébọ̀ yìí kí ó baà lè mú obìnrin náà fi ṣe aya tirẹ̀.
Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan péré, Dáfídì rú mẹ́sàán nínú Òfin Mẹ́wàá:
10: Ó ṣe ojúkòkòrò aya ẹnìkejì rẹ̀.
9: Ó f'irọ́ bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
8: Ó jí arábìnrin náà fún ara rẹ̀.
7: Ó ṣe àgbèrè.
6: Ó pa ọkọ arábìnrin náà.
5: Ó ṣe àìbọ̀wọ̀ fún òbí rẹ̀.
2: Ó sọ Bááṣébà di ère.
1 and 3: Ó d'ójúti Ọlọ́run àti orúkọ Rẹ̀.
Dáfídì kò ṣáà bá ọjọ́ ìsinmi jẹ́—n'íbi t'ójú wa ríi mọ.
Kílódé tí ẹni bí ọkàn Ọlọ́run ṣe èyí?
Kílódé tí à ń dá ẹ̀ṣẹ̀? Báwo ni a ṣe lè b'orí ìdánwò? Kíni kí a ṣe nígbàtí a kò bá lè b'orí?
Ñkan tí a ó máa gbéyẹ̀wò rèé láàrin bíi ọjọ́ mẹ̀rin.
Retí Kí A Rán Ọ́ wò
Nígbàtí Jésù b'orí ìgbógun Sàtáánì, ọ̀tá "fií s'ílẹ̀ fún sáà kan” (Lúùkù 4:13). Bí Olúwa wa bá d'ojúkọ ìdánwò, bẹ́ẹ̀ ni yió rí fún àwa náà.
Èṣù wá o, ósì kórìra rẹ. Ìwọ ni ọ̀tá rẹ̀. Jésù kìlọ̀ fún wa pé èṣù jẹ́ "apànìyàn láti àtètèkọ́ṣe," àti "èké baba èké” (Jòhánù 8:44). Ó jẹ́ “kìnìún tí ńbú ramúramù tí ó ńwá ẹni tí yíó pajẹ kiri" (1 Pétérù 5:8). Ó ńdán olúkúlùkù wa wò ó sì ńtàn wá.
Ìdí nìyìí: "Nígbàtí ìfẹ́kùfẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbàtí ó bá d'àgbà tán, á bí ikú” (Jákọ́bù 1:15).
Kọọ́ sílẹ̀: éṣẹ̀ yíó gbé ọ kọjá ibi tí o ní l'érò láti dé, yíó dá ọ dúró ju bí ọ ṣe fẹ́ lọ, yíó sì ná ọ ju ohun tí o lè san lọ.
Nígbà gbogbo.
Ìwọ ṣáà bi Ọba Dáfídì. Ka 2 Sámúẹ̀lì 12 fún àwọn àbáyọrí kàyééfì.
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.
More