Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ọjọ́ 3 nínú 5

h1>Báwo ní mo ṣe lè fí Ẹ̀mí jagun láti ségun Èṣù?

Lododo ni Èṣù wà, ṣùgbọ́n a tí ségun rẹ

Jésù wá sí ayé láti pá iṣẹ́ Èṣù rùn (Jòhánù kini3:8). Nígbàtí Olúwa wa kú lórí igi àgbélébùú, ẹsẹ kú pẹ̀lú. Nígbàtí Ó jíǹde kúrò ní ipò òkú, ipò òkú ṣègbé. Ní ọjọ́ kan a ó ju Èṣù sínú iná àìleru níbití yíò tí màá jìyà lọ́san àti lóru ní gbogbo ìgbà (Ìfihàn 20:10). Èṣù kò ní jọba ní ọ̀run àpáàdì, nibẹ ní a ó ti máà dá lóró títí láì.

Èṣù ń gbógun tí bàbá wá àti pé àwa gàn ní ó jẹ ojú ogun rẹ níbití rògbòdìyàn tí ń ṣẹlẹ̀. Kò lè mú ìpalára bá Ọlọ́run, torí bẹ ní ó ṣe dojú kọ àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ọ̀nà tí ó rí pé ó dára jù láti pá mi lára ni láti kọlu àwọn ọmọ mi

Nípa ogun Ẹ̀mí tí à ń bá ọ̀tá yí ja, báwo ni a ṣe lè ségun?

Àkọ́kọ́, kọjú ìjà sí Èṣù, òun yio sì sá fún ọ(Jákọ́bù 4:7). Ní àkókò tí ó bá dán ọ wò, jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún Ọlọ́run kì ó sì yàn láti kojú rẹ. Kí ó má ṣe fì àyè fún Èṣù (Éfésù 4:27). Kò rọrùn láti kọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ju ìgbà tí ó bá kọ́kọ́ sọ jáde ní àyà tàbí ọkàn rẹ

Èkejì, gbá ìṣẹ́gun rẹ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run

Bàbá rẹ̀ ṣe ìlérí pé Òun kò ní gbá ìdánwò kánkán láyè láì fún ọ ní agbára láti borí rẹ.(Kọ̀rinti kini 10:13)Ní àkókò tí ota bá farahàn ní ìgbé ayé rẹ dúró lórí ìlérí yẹn.

Ẹ̀keta, gbé ìhámọ́ra Ẹ̀mí-mímọ́ wọ́.

Éfésù orí kẹfà sọ fún wa pé "Jẹ̀ alágbára nínú Olúwa àti nínú agbára ipá Rẹ̀. Gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ó lè kọjú ìjà sí àrékérekè Èṣù. Ohun ìjà wá kì í ṣe tí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ ibi òkùnkùn aiyé yi, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run" (ẹsẹ 10-12)

"Ìhámọ́ra" Ẹ̀mí yí pẹ̀lú òtítọ́ Ọlọ́run, òdodo, ìhìnrere, ìgbàgbọ́, ìgbàlà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà (ẹsẹ 14-18).Dúró nínú ìwọ̀nyí, Ṣé ìmúlọ wọ́n. Kí ó sì gbẹ́kẹ̀lé wọ́n gẹ́gẹ́bí agbára Ọlọ́run nínú ayé rẹ. Nwọn yíò sì fún ọ ní ìṣẹ́gun.

Nítorí náà, mọ dájú pé ọ̀tá yíò lépa ikú sí ọ̀

Àwọn kìnnìún a máà bú ramúramù tí wọn bá fẹ́ kọlù ni. Dúró nínú agbára Ọlọ́run loni. Nígbà tí ó bá kùnà, sá tọ Ọlọ́run fún ìdáríjì, óòre-ọ̀fẹ́, àti ìsẹ́gun

Nígbà míràn tí Èṣù bá rán Ọ̀ létí ohun tí ó tí kọjá nínú ayé rẹ, ṣe ni kí ó rán létí nípa ọjọ iwájú rẹ.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Denison Forum fún ìpèsè ètò yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.denisonforum.org

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ