Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò ÌsinmiÀpẹrẹ

Grief Bites: Hope for the Holidays

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí a l'áyọ̀ l'ákojò ìsinmi...pàápàá jùlọ nínú ọ̀fọ̀ ńlá?

Ó ṣeéṣe kí a l'áyọ̀ tòótọ́l'ákokò ọ̀fọ̀!

Ìyàtọ̀ wà láàrin ìdùnnú àti ayọ̀ tó kún fún ìrètí.

Ìdùnnú lè dá lóríi ohun t'ára ńfẹ́, èrò, ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìgbàgbọ́. Àyọ̀ tó kún fún ìrètí a máa wá nípa níní òye bí Ọlọ́run Baba wa ṣe ní ìfẹ́ wa tó, fí fẹ'lá nínú oore Rẹ, àti wíwọ inú àlááfíà pípé Rẹ, ìfìfẹ́ gba'ni níyànjú Rẹ, àti ìsinmi Rẹ.
Ó wà nínú níní òye pé Ọlọ́run ní ètò fún ọgbẹ́-ọkàn rẹ, àti ayé rẹ pàápàá, àti mímọ̀ pé Òun kìí fi ẹ̀dùn ọkàn s'òfò.
Paríparí gbogbo rẹ̀, ó wà nínú níní òye pé a lè rí ayọ̀ àkókò ìsinmi nínú Rẹ̀ nìkan soso!

Sáájú ọ̀fọ̀ mi, mo l'érò pé àkókò ìsinmi kún fún ayọ̀ látàrí ṣíṣe ètò rẹ̀ sílẹ̀ àti kí a ní àkókò ìsinmi tó "gún règé" pẹ̀lú ará àti ọ̀rẹ́. Éhìn ìgbà ọ̀fọ̀ mi ní mo tóó ríi pé inù Ọlọ́run nìkan ni ayọ̀ tí kò l'ábùkù wà.
Ọlọ́run nìkan ni ìtumọ̀ tòótọ́ fún ati ti àkókò ìsinmi.
Ọjọ́ Ìdúpẹ́ kìí ṣe èyí tí à ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan fún àwọn ẹni wa ọ̀wọ́n àti ìbùkún ti ara...Ọjọ́ Ìdúpẹ́ jẹ́ ọjọ́ ọpẹ́ ńlá nítorí pé ọpẹ́ yẹ wá 'torí a ní Ọlọ́run t'Ó fẹ́ràn tí Ó sì ń ṣ'ìkẹ́ wa! À ń dúpẹ́ fún ohun gbogbo tí Ó ń ṣe l'ọ́kàn wa àti ní ayé wa, a ń dúpẹ́ fún ìsúra ayérayé tí Ó ń kọ́ sí ọkàn wa, à ń dúpẹ́ pé a ní ìbádọ́ọ̀rẹ́ tó tọ́ tó sì dára jù pẹ̀lú Rẹ̀!
Níní òye pé Ọlọ́run ń pèsè ààyè sílẹ̀ fún wa ní ayérayé, àti pé Ọ̀run ní àwọn àyànfẹ́ wa lọ́dọ̀ àti àwọn àlùmọ́ọ́nì tó ga tó sì ní'tumọ̀ fún wa náà jẹ́ ohun tí ó yẹ ká ṣ'ọpẹ́ fún.

Kérésìmesì kò dá lórìi ká lo àsìkò wa pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ wa, ká ṣe igi àti ilé wa l'ọ́ṣọ̀ọ́, ká kọ orin Kérésì, ká dá'ná, tàbí wo eré Kérésì l'órí ẹ̀rọ́ Tẹlifísàn...Kérésìmesì ní sàn-án sàn-án dá l'órí Olùgbàlà tó fi ògo Ọ̀run sílẹ̀ (àbí oò r'óye?) kí Ó baà lè di ènìyàn làti gbà ọkàn àwa tìkalára wa là...kí O kàn lè ní ìbájọṣepọ̀ tó tímọ́tímọ́́ pẹ̀lú wa!

Láti fi gbogbo ògo àti ọlá Ọ̀run sílẹ̀—ìpéníye, ayọ̀, àti tító tàn pẹ̀lú ìgbósùbàfún àwọn áńgẹ́lì ojoojúmọ́—kí Ó wá ṣètò ìsinmi pàtàkì tí à ń pè ní Kérésìmesì, kí a baà lè wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ láì sí ìdíwọ́ àti kí á baà lè ní àǹfààní sí ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀, yà mí lẹ́nu gidi! Èyí maá ń jẹ́ kí n fẹ́ láti f'ọkàn sí ìtàn òtítọ́ ti Kérésìmesì, ìtàn dídára ti Kérésì tí ń fún ni ní ìrètí! Èyí sì jẹ́ kí n fìfẹ́ hàn sí àti kí n sì ṣe kóríyá fun àwọn ẹlòmíràn l'ọ́nà tí Òun náà ṣe fẹ́ràn tí Ó sì ṣe kóríyá fún mi.
Bí Ó ṣe fi tìfẹ́tìfẹ́ fi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, èmi náà maá ń rántí láti fi tìfẹ́tìfẹ́ fi fún àwọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n tó wà láyìká l'ákokò ìsinmi nípa pínpín ẹ̀bùn ìfẹ́, ṣíṣe kóríyá, níní àwọn ìrírí àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú wọn, àti ṣíṣe àwọn ìṣe tí ó ń fihàn pé mo mọ rírì wọn.
Ronú nípa bí o ṣe lèè dókoowò sínú àwọn ẹbí ará àti ọ̀rẹ́ l'ákokò ìsinmi yì.
Èyí yíó gbé ọkàn wúwo rẹ fúyẹ́, yíó sì gbà ọ́ láàyè láti bùkún ọkàn ẹlòmíràn nípasè bẹ́ẹ̀.

Nígbàtí mo bá ronú nípa ìtumọ̀ Kérésìmesì gan an, ó ma ń pè mí láti lo àkókò Kérésì láti wá ọkàn Ọlọ́run, kí n máa s'àjọyọ̀ ayọ̀ tó wà nípasẹ̀ Rẹ̀, kí n sì mọ dunjú irú ẹni tí o yé kí n pín ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú.

Èyí lè má mú ọgbẹ́-ọkàn tí a ní lọ pàtápátá, ṣùgbọ́n ó ní agbára láti kún onígbàgbọ́ tòótọ́ pẹ̀lú ayọ̀ tó jinlẹ̀ bí a ṣe ń mọ rírì ìfarajì ńlá tí Ọlọ́run ṣe fún aráyé...kí Ó baà lè bá wa dọ́rẹ̀ẹ́ láì ṣẹ̀tàn, tìfẹ́tìfẹ́ àti l'ótìtọ́!

Mímọ̀ pé a lè ní ayọ̀ tó jẹ́ ojúlówó láàrin bí ohun gbogbo ṣe le koko tó jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run nìkan lè fi fún ọkàn wa.

Lónìí, mo bèèrè pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ẹ̀bùn ìbùkún ti ayọ̀, kí Ó sì jẹ́ kí èyí hàn gbangba sí ọ ní gbogbo àkókò ìsinmi yìí.
Gbéeyẹ̀wò láti bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí o lè bùkùn fún àkókò ìsinmi yìí, pẹ̀lú ìfẹ́ àti ṣíṣe kóríyà fún ni rẹ.

Àdúrà:
"Baba Ọ̀run, O ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo ohun tí O ti ṣe fún èmi àti ìdílé mi—l'átẹ̀yìnwá, ní lọ́ọ́lọ́ yìí, àti l'ọ́jọ́ iwájú—O sì seun fún ohun tí O ó tún máá ṣe fún wa síi!
Jọ̀wọ́ fi ayọ̀ ọ̀run Rẹ kún ọkàn wa! Ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìrírí ayọ̀ Rẹ tí ó ń ràn kálẹ̀ nínú ọkàn wa l'ákokò ìsinmi yìí. Jẹ́ kí ìwàláàyè Rẹ di mímọ̀, pẹ̀lú ìfẹ́, ìrètí, ìmóríyá àti ìtùnú Rẹ! Mo yìn Ọ́ nítorípé a lè ní ayọ̀ ọlọ́run bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn kan wà nínú ọgbẹ́-ọkàn àti ìrora ńlá. Ìgbàkúgbà tí a bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí ó rẹ ọkàn wa l'ákokò ìsinmi yìí, kún ọkàn wa pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ àti ìwàláàyè Rẹ! Kún wa pẹ̀lú ÌRÈTÍ ọ̀tun!
Ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ làti jẹ́ ohun èlò kóríyá, ìrètí, ayọ̀, àti àlááfíà fún gbogbo àwọn tí O fi s'ọ́nà àjò wa.
A fẹ́ràn Rẹ, Olúwa! Ní Orúkọ Jésù, Àmín."

Àyọkà yìí © 2015 làti ọwọ́ Kim Niles/Grief Bites. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà nípamọ́ lábẹ́ òfin. A lòó pẹ̀lú àṣẹ.
Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

Grief Bites: Hope for the Holidays

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Kim Niles, òǹkọ̀wé tó kọ Getting Your Breath Back After Life Knocks It Out of You, fún p'ípèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.griefbites.com