Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò ÌsinmiÀpẹrẹ

Grief Bites: Hope for the Holidays

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ahh, àkókò ìsinmi! Àkókò tó jẹ́ pé ìtànná ewéko tó rẹ̀ ní ìgbà ìwọ́wé maá ń rán wa létí pé Ọdún Ìdúpẹ́ ti súnmọ́ etílé tí kùrùkẹrẹ Kérésìmesì ti dé tán. Àkókò tí gbogbo ènìyàn ma ń kún fún ọpẹ́, ìfẹ́, ìṣọ̀kan nínú ẹbí àti ayọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Àmọ́ ṣá, bẹ́ẹ̀ kọ́ l'ọmọ́ ṣ'orí lọ́dọ̀ gbogbo enìyàn-pàápàá àwọn tí wọ́n pàdánù àwọn ẹni wọn ọ̀wọ́n, àwọn tí wọ́n ń la àdánù kan gbògíì kọjá nínú ìbájọṣepọ̀ tàbí tí wọ́n ń ní ìtàpórógan nínú ẹbí, tàbí, àwọn tí wọ́n ní àdánù ńlá tàbí ọgbẹ́-ọkàn.

Nígbàtí mò ń dàgbà, mo fẹ́ràn àkókò ìsinmi mo sì ma ń f'ojú s'ọ́nà gidi fún un.
Nígbàtí arábìnrin mi ẹni ọdún méjìlélógún kú l'ọ́jọ́ Ọdún Ìdúpẹ́, kàkà kí àkókò ìsinmi jẹ́ èyí tí ó dára jù níní ọdún, àkókò ìsinmi wá di èyí tí ó kó 'ni láyà jẹ àti àkókò ìpèníjà tó ga jùlọ nínú ọdún.

Báwo ni o ṣe ń ní ìrètí l'ákòkò ìsinmi?

Báwo ni o ṣe lè bù ọlá fún àwọn ẹni rẹ ọ̀wọ́n tí wọ́n ń lo àkókò ìsinmi tiwọn l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run báyìí?

Ṣé ayọ́ lè jẹyọ́ l'ákokò ìsinmi...pàápà jùlọ láàrin ìṣèdárò tó pọ̀ rékọjá?

Báwo ni o ṣe lèe ṣ'èdá àkókò ìsinmi tó ní ìtumọ̀ tí o kún fún àlááfíà, láì fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ṣe?

Jọ̀wọ́ darapọ̀ mọ́ mi fún bí ọjọ́ mélòó kan bí n ó ṣe máa dáhùn àwọn ìbéérè yìí àti àwọn mìráàn.

"Baba Ọ̀run,
Mo gbàdúrà fún gbogbo àwọn tí ń k'ẹ́dùn l'ákòkò ìsinmi-pàápàá jùlọ ní àkókò Ìdúpẹ́ àti Kèrésìmesì yìí. Jọ̀wọ́ wo ọkàn wọn sàn kí O sì tù ọkàn ọgbẹ́ wọ́n nínú. Jọ̀wọ́ rọ̀'jò oore-ọ̀fẹ́ àti àánú Rẹ lé wọn lórí ní ojoojúmọ́ àt'ọjọọjọ́. Fi ọwọ́ ìfẹ́ Rẹ dì wọn mú kí O sì gbé wọn la àkókò ìdárò wọn kọjá. Ní Orúkọ Jèsù, àmín!"

Àyọkà yìí © 2015 làti ọwọ́ Kim Niles/Grief Bites. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà nípamọ́ lábẹ́ òfin. A lòó pẹ̀lú àṣẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Grief Bites: Hope for the Holidays

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Kim Niles, òǹkọ̀wé tó kọ Getting Your Breath Back After Life Knocks It Out of You, fún p'ípèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.griefbites.com