Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò ÌsinmiÀpẹrẹ

Grief Bites: Hope for the Holidays

Ọjọ́ 2 nínú 5

Báwo ni o ṣe lè sàwárí kí o sí ní ìrírí ìrètí nígbàtí o wà nínú ipò àìnírètí l'ákokò ìsinmi?

Léhìn ìgbà tí mo ti la ikú arábìnrin mi kọjá l'ọ́jọ́ ọdún Ìdúpẹ́, tí ikú ọ̀rẹ́kùnrin mi tún tẹ̀lée nínú ìsinmi Kérésì, tí ìyá àgbà mi kú l'ópin ọ̀sẹ̀ Àjájọ́ Olólùfẹ́, tí ìyá àgbà mi kejì kú ní Kérésì ku ọjọ́ méjì, àti lẹhin ọdún díẹ̀ tí àfẹ́sọ́nà arábìnrin mi kejì kú l'ọ́jọ́ ọdún Àjíǹde, mi ò kún fún ìrètí rárá. Àkókò ìsinmi tí ó tẹ̀lé ìgbà ikú wọn jẹ́ èyí tí o dun ni jọjọ. Mo tiraka láti ní ìrètí kankan látàrí ọgbẹ́-ọkàn tó pọ̀ lápọ̀jù.

Bóyá o wà ní ipò àìnírètí látàrí ikú ẹni tí o fẹràn, tàbí ò ń la ìpèníjà àyè kan kọjà (bíi ìkọ̀sílẹ̀, làásìgbò nínú ẹbí, àìsàn, ìnira nínú ìṣúná, ìpàdánù iṣẹ́, tàbí àwọn òfò abanilọ́kànjẹ́ mìráàn), jọ̀wọ́ mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ nítòtòtọ́ Ó sì l'ákàsí rẹ gidi.
Ohun tí ò ńlà kọjá yé E yékéyéké Ó sì fẹ́ láti na ọwọ́ ìwòsàn Rẹ sí ọ.

Ọlọrun ń fẹ́ ju ohunkóhun lọ láti rọ̀'jò ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ àti ÌRÈTÍ tókọjá sísọ Rẹ lé ọ lórí!

Ṣùgọ́n báwo ni o ṣe lè ṣàwárí ìrètí Rẹ̀ kí o sì ní ìrírí rẹ lẹ́kùnrẹ́rẹ́?

Bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ fún Ọlọ́run kí Ó wo ọkàn rẹ sàn...bèèrè pé kí Ó kún ọ fún ìrètí Rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Òun nìkan wá...bèèrè pé kí Ó rì ọ́ sínú ibú ìfẹ́ àgbààyanu Rẹ̀!

Bèèrè ní pàtó pé kí Ọlọ́run gbé ọ la àkókò ìsinmi yìí já àti kí Ó sì bá ọkàn rẹ pàdé!
Ka ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kí o sì bèèrè pé kí Ó bá ọkàn rẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára bí Ó ti ń rọra tu ọkàn àti ẹ̀mí rẹ tó gb'ọgbẹ́ nínú.

Kò níí ṣe ohun náà tí oò báà máa là kọjá, Ó l'ákàsí ọkàn ìgbọgbẹ́ rẹ, nítorí náà wá Ọlọ́run l'ákokò ìsinmi yìí, àti nígbà gbogbo, pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ!

WÀÁ rí Ọlọ́run—àti ÌRÈTÍ Rẹ̀ titun—nígbàtí o bá fi gbogbo ọkàn rẹ wá A! Ọ̀tun ni àánú Ọlọ́run ní ojoojúmọ́ nítorí náà bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ fún wọn!
Ó wà níbí fún ọ yí Ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò ìsinmi yìí!

Àdúrà:
"Jèsù Olùfẹ́, mo dúpẹ́ fún ìrètì! Mo bèèrè ní pàtó pé kí O fún mi ní ẹ̀bùn rere tí ìrètí àti pé kí O jẹ́ kí n sàwàrí kí n sì ní ìrírí ìrètí àti àlááfíà Rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Mo bèèrè pé kí O bùkún ọkàn mi pẹ̀lú ìwòsàn Rẹ kí O sì rọ̀'jò ìfẹ̀ Rẹ lé mi lórí. Baba, dákun jọ̀wọ́ wo ọkàn mi sàn kí O sì gbé mi la àkókò ìsinmi yìí kọjá? Mo gbàdúrà pé kí O sọ̀rọ̀ agbára sínú ẹ̀mí mi bí mo ṣe ń wá ọkàn Rẹ (àti ìtọ́sọ́nà) bí mo ṣe ń ka ọ̀rọ̀ Rẹ. Fún mi ní àánú Rẹ iyebíye l'óòròwúrọ̀ kí O sì jọ̀wọ́ tú ọkàn mi nínú lójoojúmọ́. O ṣeun nítorí pé O jẹ́ Ọ̀rẹ́ mi tòòtọ́! Mo mọ rírì mo sì b'ọlá fún ìbádọ́ọ̀rẹ́ Rẹ! Mo ní'fẹ̀ Rẹ, Olúwa!
Ní Orúkọ Rẹ Iyebíye ni mo gbàdúrà, àmín."

Àyọkà yìí © 2015 làti ọwọ́ Kim Niles/Grief Bites. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà nípamọ́ lábẹ́ òfin. A lòó pẹ̀lú àṣẹ.
Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Grief Bites: Hope for the Holidays

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Kim Niles, òǹkọ̀wé tó kọ Getting Your Breath Back After Life Knocks It Out of You, fún p'ípèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.griefbites.com