Isa 66:9-14

Isa 66:9-14 YBCV

Emi o ha mu wá si irọbi, ki nmá si mu ki o bi? li Oluwa wi: emi o ha mu ni bi, ki nsi sé inu? li Ọlọrun rẹ wi. Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u. Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀. Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀. Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu ni Jerusalemu. Nigbati ẹnyin ba ri eyi, ọkàn nyin yio yọ̀, egungun nyin yio si tutu yọ̀yọ bi ewebẹ̀; a o si mọ̀ ọwọ́ Oluwa lara awọn iranṣẹ rẹ̀, ati ibinu rẹ̀ si awọn ọta rẹ̀.