AISAYA 66:9-14

AISAYA 66:9-14 YCE

Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí, kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí? Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ, ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?” Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀, ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu; kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú, ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀. Nítorí OLUWA ní: “N óo tú ibukun sórí rẹ̀, bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn. N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́, bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè. Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú, ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu. Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí, bí ìgbà tí koríko bá rúwé. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”