Ohun Tí Baba SọÀpẹrẹ
O Wà Nínú Àtẹ́lẹwọ́ Mi
Bàbá sọ wí pé, “Ìfẹ́ mi tí o je pípé ń sáré wọ inú ọkàn rẹ, tí ó sì ń lé gbogbo ìbẹ̀rù. Fi gbogbo ohun tí o ní sílẹ̀, Kí o sì rọ̀ mọ́ mi. Èmi ni Jèhófà Jireh, Olùpèsè rẹ. Èmi ni Jèhófà Rapha, Olùwòsàn rẹ. Èmi ni Alpha àti Omega, èmi yóò sì fi oore-ọ̀fẹ́ mi kún àwọn ọjọ́ rẹ bí ìwọ ti wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú mi. Ìdílé rẹ, ìnáwó àti ọjọ́ ọ̀la; gbé wọn kalẹ̀ níwájú mi, Kí ẹ sì máa wo ohun tí n óo ṣe nígbà tí ẹ bá gbẹ́kẹ̀lé mi. Ọmọ mi olùfẹ́, O wà nínú àtẹ́lẹwọ́ mi.”
Ọlọ́run ti pè wá láti gbé nínú ìṣípayá yìí: A wà nínú àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀. Bí orin tí àwọn ọmọdé máa ń kọ, “Gbogbo ayé wà nínú ọwọ́ rẹ̀!” Tí á bá ní ìṣòro, ó ṣe pàtàkì láti gbára lé ohùn Bàbá, kí a sì sinmi ní àyíká rẹ̀. Kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa ẹ̀mí rẹ̀. Òun ni ibi ìpamọ́ wa, ibi ìsádi wa, àti ilé gogoro tó lágbára. Nínú ohun tí a mọ̀ àti ohun tí a kò mọ̀, ní ìsinsìnyí àti ní àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀, Òun ló yẹ ká máa sá sọ́dọ̀ nígbà gbogbo.
Nínú 2 Kíróníkà 20:17, Ọba Jèhóṣáfátì wà láàárín ogun kan. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì wá wí pé, “Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.” Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa!
Bí wọ́n ti ń kọrin, Olúwa dẹ́kùn mú àwọn ọ̀tá wọn, ó sì ṣẹ́gun wọn.
Ọ̀kan lára ipò ìgbàgbọ́ tó ga jù lọ ni láti sinmi nínú apá Baba kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Sinmi nínú oore Ọlọ́run. Sinmi Nínú Àwọn Ìlérí Rẹ̀. Sinmi nínú ìṣẹ́gun rẹ̀. Sinmi, Òun yóò sì bójú tó ìyókù. Bíi ti John olólùfẹ́, Like John the beloved gbé orí rẹ lé àyà Jésù. Ibi ìfararora àti ibi àjọpín yìí ni ọkàn Ọlọ́run ti máa ń kọjú sí gbogbo àníyàn wọn. Ọkàn-àyà rẹ̀ ń lù kìkì nítorí rẹ. Bàbá sọ wí pé, "O wà nínú àtẹ́lẹwọ́ mi."
Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ orin yìí fún ọ níṣìírí, Shalom, látọ̀dọ̀ Legacy Worship:
“Ó lè máà jẹ́ apá ètò rẹ
woÀmọ́ o wà nínú atele mi
Mo ti gbá ọ mú
Mo ti gbá ọ mú
Mo wà níbí yìí
Mi ò fi ọ sílẹ̀ rí
Mo ṣì wà níbí
Mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ”
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn èrò ìfẹ́ tí Bàbá ní sí ọ pọ̀ ju iyanrìn etí òkun lọ. Ọmọ Rẹ̀ Olùfèẹ́ ni ọ́, inú Rẹ̀ sì dùn sí ọ! Ètò ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí jẹ́ ìpé fún ọ láti mọ àbúdà ẹni pípé àti ẹni àgbààyanu tí Bàbá rẹ ọ̀run jẹ́. Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sí ìlàkàkà tàbí ìbẹ̀rù, nítorí pé o wà ní àtẹ́lẹwọ́ Rẹ̀.
More