Ohun Tí Baba SọÀpẹrẹ

What The Father Says

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ìwọ Ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi

Bàbá wí pé, "Kí a tó rò nípa rẹ rárá, Mo mọ àlàyé ní kíkún nípa ẹ̀dá rẹ. Láti iye irun orí rẹ títí dé gbogbo iye ọjọ́ ayé rẹ, Mo dá ọ fún ìfẹ́ inú àti ìgbádùn mi. ju iyanrìn etí òkun lọ, ni èrò àti ìfẹ́ mi sí ọ. Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn láti pè ọ́ ní tèmi."

Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́! Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló dàgbà nínú àwọn ẹbí tí àwọn bàbá kò ti ṣe bíi baba, àwọn mìíràn sì dàgbà pẹ̀lú àwọn bàbá tó jẹ́ àràmọ̀dà, tàbí bóyá tí àwọn bàbá kò tilẹ̀ ti sí rárá. Ìtàn wa yìí sábà máa ń di awò èyí tí a ń ti ipa rẹ̀ rí Bàbá wa ọ̀run.

Irú ojú wo ni o fi ń wo Abba Bàbá rẹ?

Allison Fowler sọ pé, "Ọkàn ni awò tí a fi rí Ọlọ́run. Bí a bá kọ̀ láti dáríjì, ìkorò àti ìrunú wa á di ìdọ̀tí tí ó ṣú bo agbára tí a ní láti rí I kedere." Torí náà pe Olúwa kí Ó gbá ọkàn rẹ mọ́ kúrò nínú gbogbo ayédèrú ìgbàgbọ́ nípa ìwàa Rẹ̀ èyí tó wù jáde láti inú bí wọn ṣe tọ́ ẹ dàgbà tàbí ìdojúkọ tí o lè ti ní sẹ́yìn. Jẹ ki otitọ nípa iwa Rẹ fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú rẹ: ìwà Ọlọ́run ni òdiwọ̀n pípé, ìṣoore, ati ifẹ; Kò ní àbùkù, àìpé tàbí àbàwọ́n

Yan àsìkò diẹ, di ojú rẹ, kí o ronújinlẹ̀ lórí ẹ̀dá ìyanu tí Ọlọ́run jẹ́. Òróró ìwòsàn láti ọ̀run ń ṣàn wá sí ọkàn rẹ nísìnyí, ó ń mú ìṣókùnkùn kúrò, ó ń ṣí ọ ní ojú ẹ̀mí. Fetí sí ohùn Bàbá rẹ bí Ó ti ń fi ohùn kẹ́lẹ́ sọ òtítọ́ sí ọ lọ́kàn, kí o sì gba ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ tí ó kún ọkàn Rẹ̀ fún ọ. Bàbá wí pé, "Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi."

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

What The Father Says

Àwọn èrò ìfẹ́ tí Bàbá ní sí ọ pọ̀ ju iyanrìn etí òkun lọ. Ọmọ Rẹ̀ Olùfèẹ́ ni ọ́, inú Rẹ̀ sì dùn sí ọ! Ètò ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí jẹ́ ìpé fún ọ láti mọ àbúdà ẹni pípé àti ẹni àgbààyanu tí Bàbá rẹ ọ̀run jẹ́. Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sí ìlàkàkà tàbí ìbẹ̀rù, nítorí pé o wà ní àtẹ́lẹwọ́ Rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christ for the Nations fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://cfni.org/