Ohun Tí Baba SọÀpẹrẹ

What The Father Says

Ọjọ́ 2 nínú 3

Inu mi dun si Ọ   

Baba wi pe, “Ọmọkurin, ọmọbinrin; Iwo ni ayọ̀ Mi! Kii ṣe iṣe rẹ ni o mu inu mi dun si o, bí kòṣe Ìwà láàyè rẹ ni. Ko s‘ainiyan ninu ìfẹ́ mi. Saa ti wá ki o si wa pẹlu mi ati ninu mi.

Jọ̀wọ́ ara rẹ fun ìfẹ́ mi igba gbogbo. Fi ẹru rẹ sílẹ̀, ki o si sinmi ninu ifẹ́ mi, nitori inu mi dun si ọ.”

Olóògbé Billy Graham sọ nígbà kan pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ohun púpọ̀ láti dúpẹ́ fún bí mo ṣe ń wo irin-aajo ìgbésí ayé mi, mo tún máa ń kábàámọ̀ púpọ̀. Bayi n o máa sọ̀rọ̀ díẹ̀, n o si màá kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i, n o si màá sì lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú ìdílé mi. Emi yoo tun lo akoko diẹ sii ninu itọju ti ẹ̀mi, ni wiwa lati dagba sunmọ Ọlọrun ki n le di pupọ sii bi Kristi.”

Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Billy Graham fọwọ́ kan Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ okan, síbẹ̀ ní òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó fẹ́ láti lo àkókò díẹ̀ fun sísọ̀rọ̀, àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, àti àkókò púpọ̀ síi láti wá Olúwa.

Iwa eniyan ni lati ri ara re sinu isin, ṣiṣe, ṣiṣe. Asa wa maa n yara lati fa wa sinu iṣẹ ṣiṣe ati idamu. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdúró ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ọmọdé ní apá Bàbá wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti sinmi, sinmi, sinmi. Ìfihàn ìdùnnú Abba Bàbá nínú wa ń fòpin sí ìsapá-ara-ẹni ó sì tọ́ wa sọ́nà kúrò nínú gbígbìyànjú sínú ìrọ̀rùn.

Idunnu Olorun kii se lati fa wa sinu àirójú ráàyè, bikose ki o kuku maa pe wa si sisunmọ Òun. A. W. Tozer sọ nígbà kan pé, “Ọkùnrin tí ó dàgbà nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, yoo rí i pé ìgbésí ayé rẹ̀ túbọ̀ rọrùn.” Ifẹ kan wa lati inu ijinle Rẹ si tiwa, itọsi si irọrun ti igbadun, idapọ, ati ifẹ. Igbesi aye olufẹ Jesu ti a fi lelẹ kii ṣe igbiyanju lati gba idunnu Rẹ, ṣugbọn lati duro ninu idunnu Rẹ. Nítorí Baba sọ pé, “Inú mi dùn sí ọ.”

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

What The Father Says

Àwọn èrò ìfẹ́ tí Bàbá ní sí ọ pọ̀ ju iyanrìn etí òkun lọ. Ọmọ Rẹ̀ Olùfèẹ́ ni ọ́, inú Rẹ̀ sì dùn sí ọ! Ètò ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí jẹ́ ìpé fún ọ láti mọ àbúdà ẹni pípé àti ẹni àgbààyanu tí Bàbá rẹ ọ̀run jẹ́. Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sí ìlàkàkà tàbí ìbẹ̀rù, nítorí pé o wà ní àtẹ́lẹwọ́ Rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christ for the Nations fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://cfni.org/