Líla Ìgbà Ìṣòro KọjáÀpẹrẹ

Going Through Hard Times

Ọjọ́ 4 nínú 4

Yàrá Ìdúró

Gbogbo wa la ti gbọ́ tí àwọn èèyàn ń lo gbólóhùn náà “ní báyìí ná” nígbà tí wọ́n ń dúró de nǹkan. Nígbà tí a wà ní yàrá ìdúró, Ọ̀rọ̀ náà “ní báyìí ná,”tí a ń dúró de ìwòsàn wa tàbí iṣẹ́ ìyanu wa, sábà máa ń burú gan-an, ṣé bẹ́ẹ̀ kọ́? 

Nítorí náà, kí la máa ṣe ní báyìí? Báwo la ṣe lè pa ìgbàgbọ́ wa mọ́ àti kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ nígbà tí a kò bá rí i? Àwọn àbá díẹ̀ rèé fún wa bi á ṣe ń dúró nínú ìjà wa:

Máa Yìn Í Nínú Ìrora Rẹ
Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí á lè ṣe nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò ni pé ká máa sìn Ọlọ́run. Ó yẹ fún un lójoojúmọ́. Nígbà tí a bá ronú nípa gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún wa àti ayérayé tí a ó lò pẹ̀lú Re, báwo la ò ṣe ní sìn? Ṣe àkíyèsí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run—Kò ní ópin, Kò yí pa dà, Òun ni òun gbogbo, Ẹni pípé ni, aláàánú ni, olóore ọ̀fẹ́ ni, Ó sì wà níbi gbogbo ní gbogbo ìgbà. A ń fi ògo àti ìyìn fún Ọlọ́run kí a tó kúrò nínú àdánwò tàbí kí a rí àbájáde tí a fẹ́.

Máa Gbé E Lárugẹ
Láàárín ìrora yìí, ó lè jẹ́ pé àìlera rẹ nìkan lo rí, O ò rí àwọn iṣan ẹ̀mí tí ó ń dàgbà tàbí bó o ṣe ń lágbára sí i. Àmọ́ nígbàkigbà tí ó bá ń gbàdúrà, tí ó ń jọ́sìn, tí ó ń kà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Rẹ̀, ẹ̀mí rẹ ń lágbára sí i. Nínú àìlera wa ni agbára rẹ̀ ti di pípé. Ọ̀pọ̀ ló sọ pé àdánwò máa ń jẹ́ ká mọyì àwọn ànímọ́ wa. Gbàgbọ́ pé àwọn àdánwò tó ń dé bá ẹ á jẹ́ kó o lè fara dà á.

Tú Ọkàn-Àyà Rẹ Sílẹ̀
Gbogbo ìrora ọkàn rẹ ò ba Ọlọ́run lẹ́rù. Ó lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ, ó mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, ó sì mọ ohun tí n bí ọ nínú. Máa wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Àdánwò lè mú ká rọ̀ mọ́ Kristi tàbí kí o sá kúrò lọ́dọ̀ Kristi. Rọ̀ mọ́ Kristi. O lè má mọ ìdí tí ìṣòro yìí ṣi fi wa nínú ìgbésí ayé rẹ. Ibi yìí ni wàá ti fi òtítọ́ tí ó ti kọ́ sílò nígbà tí nǹkan kò le. Ojoojúmọ́ ni ó máa fi ara rẹ sílẹ̀ fún un, tí ó sì máa fọkàn tán an.

Máa Ronú Nípa Ìyè Àìnípẹ̀kun
A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyè àìnípẹ̀kun wà lọ́kàn wa. Tí á bá ń dojú kọ àwọn ohun tí á ń rí, a ń dojú kọ àwọn nǹkan tó jẹ́ fúngbà díẹ̀. Àwọn ohun tí á rí, bí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìbòjú, èyí ní o wa títí láé. Ọlọ́run ń ṣe nǹkan kan nínú wa, nípase wa, fún wa, kódà pẹ̀lú wa. Ẹ jẹ́ ká yan láti ní sùúrù bí a ti ń rí bí àkókò tí ó péye tí ó wà fún un ṣe ń ṣẹ.  

Bí ó ṣe ń fara dà á nínú yàrá ìdúró rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti wo ẹ̀yìn kí o sì wo ìtẹ̀síwájú rẹ. Nítorí pé o ti ṣe díẹ̀. Lẹ́yìn náà, máa gbé ìgbésẹ̀ tó kàn. O ò lè mọ ìgbà tí ó máa jí kí o sì rí ìyókù nínú àwọn àwọsánmà ẹ̀mí rẹ tó wà ní ìsàlẹ̀. Ọjọ́ tí o rò pé o kò lè rìn mọ́ ó lè jẹ́ ọjọ́ àṣeyọrí rẹ. 

Ṣe àṣàrò

  • Bí o bá wà ní yàrá ìdúró nínú ayé rẹ, bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí o fi ohun kan tí ó ń ṣe hàn nínú àti nípasẹ̀ rẹ lójoojúmọ́. 
  • Nínú Bíbélì tí à kà lónìí, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló ló wọ̀ ẹ́ lọ́kàn gan-an? Kọ èrò rẹ sílẹ̀. 
Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Going Through Hard Times

A kò lè fẹ́ àwọn ìdojúkọ kù nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n nínú Ètò kúkúrú ọlọ́jọ́-4 yìí, a ó máa gbà wá ní ìyànjú láti mọ̀ pé a kò dá nìkan wà, pé Ọlọ́run ní ète fún ìrora wa, àti pé yíó lò ó fún ètò gíga Rẹ̀.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.